ﰑ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
ﮱﯓ
ﰀ
Allāhu búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń sáré t’ó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun.
ﯕﯖ
ﰁ
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá).
ﯘﯙ
ﰂ
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn ẹṣin t’ó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
Wọ́n tún bẹ́ gìjà papọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ sáààrin àkójọ ọ̀tá.
Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun t’ó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
tí wọ́n sì tú ohun t’ó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?