surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,
àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù t’ó wúwo nínú rẹ̀ jáde,
ènìyàn yó sì wí pé: "Kí l’ó mú un?"
Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).
Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.
Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.