ﰏ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí t’ó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn.
Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́.
Àwọn ìwé òfin t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀.
Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí t’ó yanjú dé bá wọn.
Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu (kí wọ́n jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, olùdúró déédé. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t’ó burú jùlọ.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá t’ó dára jùlọ.
Ẹ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀.