ﮨ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
ﮝ
ﰀ
Tọ̄ sīn mīm.
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
À ń ké nínú ìró (Ànábì) Mūsā àti Fir‘aon fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo.
Dájúdájú Fir‘aon ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Ó ṣe àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìjọ-ìjọ. Ó ń dá igun kan nínú wọn lágara; ó ń pa àwọn ọmọkùnrin wọn, ó sì ń dá àwọn obìnrin wọn sí. Dájúdájú ó wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́.
A sì fẹ́ ṣèdẹ̀ra fún àwọn tí wọ́n fojú tínrín lórí ilẹ̀, A (fẹ́) ṣe wọ́n ní aṣíwájú. A sì (fẹ́) kí wọ́n jogún (ilẹ̀).
A (fẹ́) gbà wọ́n láàyè lórí ilẹ̀. Láti ara wọn, A sì (fẹ́) fi han Fir‘aon àti Hāmọ̄n pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì ohun tí wọ́n ń ṣọ́ra fún lára wọn.
A sì ránṣẹ́ sí ìyá (Ànábì) Mūsā pé: “Fún un ní ọmú mu. Tí o bá sì ń páyà lórí rẹ̀, jù ú sínú agbami odò. Má ṣe bẹ̀rù. Má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú Àwa máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. A ó sì ṣe é ní ara àwọn Òjíṣẹ́.
Nígbà náà, àwọn ènìyàn Fir‘aon rí i he nítorí kí ó lè jẹ́ ọ̀tá àti ìbànújẹ́ fún wọn. Dájúdájú Fir‘aon, Hāmọ̄n àti àwọn ọmọ ogun àwọn méjèèjì, wọ́n jẹ́ aláṣìṣe.
Ìyàwó Fir‘aon wí pé: “Ìtutù-ojú ni (ọmọ yìí) fún èmi àti ìwọ. Ẹ má ṣe pa á. Ó lè jẹ́ pé ó máa ṣe wá ní àǹfààní tàbí kí a fi ṣe ọmọ.” Wọn kò sì fura.
Ọkàn ìyá (Ànábì) Mūsā pami (lórí ọ̀rọ̀ Mūsā, kò sì rí n̄ǹkan mìíràn rò mọ́ tayọ rẹ̀) ó kúkú fẹ́ẹ̀ ṣàfi hàn rẹ̀ (pé ọmọ òun ni nígbà tí wọ́n pè é dé ọ̀dọ̀ Fir‘aon) tí kò bá jẹ́ pé A kì í lọ́kàn nítorí kí ó lè wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ó sì sọ fún arábìnrin rẹ̀ pé: “Tọpa rẹ̀ lọ.” Ó sì ń wò ó láti ibi t’ó jìnnà. Wọn kò sì fura (sí i).
A kò sì jẹ́ kí ó mu ọyàn (mìíràn) ṣíwájú (tìyá rẹ̀.) Arábìnrin rẹ̀ sì wí pé: “Ṣé kí n̄g fi ará ilé kan hàn yín, tí ó máa gbà á tọ́ fun yín? Wọn yó sì jẹ́ olùtọ́jú rẹ̀.”
A sì dá a padà sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀ nítorí kí ojú rẹ̀ lè tutù (fún ìdùnnú) àti nítorí kí ó má baà banújẹ́. Àti pé nítorí kí ó lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu, òdodo ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Nígbà t’ó dàgbà, t’ó di géńdé, A fún un ní ọgbọ́n àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san
Ó wọ inú ìlú nígbà tí àwọn ará ìlú ti gbàgbé (nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀). Ó rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n ń jà. Èyí wá láti inú ìran rẹ̀. Èyí sì wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Èyí tí ó wá láti inú ìran rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí èyí tí ó wá láti (inú ìran) ọ̀tá rẹ̀. Mūsā kàn án ní ẹ̀ṣẹ́. Ó sì pa á. Ó sọ pé: “Èyí wà nínú iṣẹ́ Èṣù. Dájúdájú (èṣù) ni ọ̀tá aṣini-lọ́nà pọ́nńbélé.”
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara mi. Nítorí náà, foríjìn mí.” Ó sì foríjìn ín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ó sọ pé: “Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe ìkẹ́ fún mi, èmi kò níí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Nítorí náà, ó di ẹni t’ó ń bẹ̀rù nínú ìlú, ó sì ń retí (ẹ̀hónú ìran Fir‘aon). Nígbà náà ni ẹni tí ó wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní àná tún ń lọgun rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Mūsā sọ fún un pé: “Dájúdájú ìwọ ni olùṣìnà pọ́nńbélé.”
Àmọ́ nígbà tí ó fẹ́ gbá ẹni tí ó jẹ́ ọ̀tá fún àwọn méjèèjì mú, ẹni náà wí pé: “Mūsā, ṣé o fẹ́ pa mí bí ó ṣe pa ẹnì kan ní àná? O ò gbèrò kan tayọ kí o jẹ́ aláìlójú-àánú lórí ilẹ̀; o ò sì gbèrò láti wà nínú àwọn alátùn-únṣe.”
Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Mūsā, dájúdájú àwọn ìjòyè ń dá ìmọ̀ràn lórí rẹ láti pa ọ́. Nítorí náà, jáde (kúrò nínú ìlú), dájúdájú èmi wà nínú àwọn onímọ̀ràn rere fún ọ.”
Ó sì jáde kúrò nínú (ìlú) pẹ̀lú ìpáyà, tí ó ń retí (ẹ̀hónú wọn), ó sì sọ pé: “Olúwa mi, là mí lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
Nígbà tí ó sì dojú kọ ọ̀kánkán ìlú Mọdyan, ó sọ pé: “Ó súnmọ́ kí Olúwa mi fọ̀nà tààrà (sí ìlú Mọdyan) mọ̀ mí.”
Nígbà tí ó dé ibi (kànǹga) omi (ìlú) Mọdyan, ó bá ìjọ ènìyàn kan níbẹ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn ní omi mu. Lẹ́yìn wọn, ó tún rí àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n ń fà sẹ́yìn (pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn wọn). Ó sọ pé: “Kí l’ó ṣe ẹ̀yin méjèèjì?” Wọ́n sọ pé: “A ò lè fún àwọn ẹran-ọ̀sìn wa ní omi mu títí àwọn adaran bá tó kó àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn lọ. Àgbàlagbà arúgbó sì ni bàbá wa.”
Ó sì bá wọn fún (ẹran-ọ̀sìn) wọn ní omi mu. Lẹ́yìn náà, ó padà síbi ibòji, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi bùkátà sí ohun tí O bá sọ̀kalẹ̀ fún mi nínú oore.”
Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì wá bá a, ó sì ń rìn pẹ̀lú ìtìjú, ó sọ pé: “Dájúdájú bàbá mi ń pè ọ́ nítorí kí ó lè san ọ́ ní ẹ̀san omi tí o fún (àwọn ẹran-ọ̀sìn) wa mu.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ ìtàn (ara rẹ̀) fún un. (Bàbá náà) sọ pé: “Má bẹ̀rù. O ti là lọ́wọ́ ìjọ alábòsí.”
Ọ̀kan nínú (àwọn ọmọbìnrin) méjèèjì sọ pé: “Bàbá mi o, gbà á síṣẹ́. Dájúdájú ẹni t’ó dára jùlọ tí o lè gbà síṣẹ́ ni alágbára, olùfọkàntán.”
Ó sọ pé: “Dájúdájú mo fẹ́ fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì wọ̀nyí fún ọ ní aya lórí (àdéhùn) pé o máa bá mi ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́jọ. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣe é pé ọdún mẹ́wàá, láti ọ̀dọ̀ rẹ nìyẹn. Èmi kò sì fẹ́ kó ìnira bá ọ. Tí Allāhu bá fẹ́, o máa rí i pé mo wà nínú àwọn ẹni rere.”
(Mūsā) sọ pé: “(Àdéhùn) yìí wà láààrin èmi àti ìwọ. Èyíkéyìí tí mo bá mú ṣẹ nínú àdéhùn méjèèjì náà, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣàbòsí sí mi. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
Nígbà tí Mūsā parí àkókò náà, ó mú ará ilé rẹ̀ rin (ìrìn-àjò). Ó sì rí iná kan ní ẹ̀bá àpáta. Ó sọ fún ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró (síbí ná). Èmi rí iná kan. Ó ṣe é ṣe kí n̄g mú ìró kan wá ba yín láti ibẹ̀ tàbí (kí n̄g mú) ògúnná kan wá nítorí kí ẹ lè rí ohun yẹ́ná.”
Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é láti ẹ̀gbẹ́ àfonífojì ní ọwọ́ ọ̀tún (rẹ̀) ní àyè ìbùkún láti ibi igi náà. (A sọ pé): “Mūsā, dájúdájú Èmi ni Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” (Ó sì jù ú sílẹ̀). Nígbà tí ó rí i t’ó ń mira bí ẹni pé ejò ni, Mūsā pẹ̀yìn dà, ó ń sá lọ́, kò sì padà. (Allāhu sọ pé): “Mūsā, máa bọ̀ padà, má sì ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn olùfàyàbalẹ̀.
Ti ọwọ́ rẹ bọ (abíyá láti ibi) ọrùn ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra sí (abíyá rẹ) níbi ẹ̀rù. Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
____________________
Ìyẹn ni pé, tí ọpá rẹ bá yí padà, t’ó di ejò níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ẹ̀rù sì ń ba ìwọ náà, pa ọwọ́ rẹ mọ́ra láti fi yọ ẹ̀rù náà kúrò nínú ọkàn rẹ.
____________________
Ìyẹn ni pé, tí ọpá rẹ bá yí padà, t’ó di ejò níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ẹ̀rù sì ń ba ìwọ náà, pa ọwọ́ rẹ mọ́ra láti fi yọ ẹ̀rù náà kúrò nínú ọkàn rẹ.
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pa ẹnì kan nínú wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí.
Àti pé arákùnrin mi, Hārūn, ó dá láhọ́n jù mí lọ. Nítorí náà, rán an níṣẹ́ pẹ̀lú mi, kí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí yóò máa jẹ́rìí sí òdodo ọ̀rọ̀ mi. Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.”
(Allāhu) sọ pé: “A máa fi arákùnrin rẹ kún ọ lọ́wọ́. A ó sì fún ẹ̀yin méjèèjì ní agbára, wọn kò sì níí lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀yin méjèèjì. Pẹ̀lú àwọn àmì Wa, ẹ̀yin méjèèjì àti àwọn t’ó bá tẹ̀lé ẹ̀yin méjèèjì l’ó máa borí.”
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé bá wọn pẹ̀lú àwọn àmì Wa, wọ́n wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àdáhun. A kò sì gbọ́ èyí (rí) láààrin àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
(Ànábì) Mūsā sì sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ẹni tí àtubọ̀tán ilé (ìkẹ́) máa jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
Fir‘aon wí pé: “Ẹ̀yin ìjòyè, èmi kò mọ̀ pé ọlọ́hun kan tún wà lẹ́yìn mi! Nítorí náà, Hāmọ̄n, dá iná fún mi, kí o fi mọ amọ̀, kí o sì kọ́ ilé gíga kan fún mi nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā. (Nítorí pé) dájúdájú mò ń rò ó sí ara àwọn òpùrọ́.”
Òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì rò pé dájúdájú A ò níí dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Wa.
Nítorí náà, A gbá òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú; A jù wọ́n sínú agbami odò. Wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ti rí.
A ṣe wọ́n ní aṣíwájú t’ó ń pèpè sínú Iná. Tí ó bá sì di Ọjọ́ Àjíǹde, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àti pé A fi ègún tọpa wọn ní ilé ayé yìí. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yó sì wà nínú àwọn ẹni ìparun.
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà lẹ́yìn ìgbà tí A ti pa àwọn ìjọ àkọ́kọ́ rẹ́. (Tírà náà jẹ́) àríwòye fún àwọn ènìyàn, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Ìwọ kò sí ní ẹ̀bá ìwọ̀-òòrùn nígbà tí A fi ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā. Àti pé ìwọ kò sí nínú àwọn t’ó wà níbẹ̀.
Ṣùgbọ́n A ṣẹ̀dá àwọn ìran kan tí ẹ̀mí wọn gùn. O ò kúkú gbé láààrin ará ìlú Mọdyan, tí ò ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, ṣùgbọ́n Àwa l’à ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́.
Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
____________________
Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti àkọ́bí rẹ̀, Ànábì ’Ismā‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) dé ìlú Mọkkah ṣíwájú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), àmọ́ kì í ṣe pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí ará ìlú Mọkkah. Bẹ́ẹ̀ náà ni èyíkéyìí Ànábì Ọlọ́hun tí ìtàn bá sọ nípa rẹ̀ pé ó dé ìlú Mọkkah tàbí ìlú mìíràn nínú àwọn ìlú Lárúbáwá. Ó lè dé ibẹ̀ rí, àmọ́ tí Allāhu kò sì níí rán an níṣẹ́ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ànábì ‘Ismā‘īl gan-an ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) tí wọ́n gbé wá wò láti òpóǹló nínú ìlú Mọkkah, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò kúkú rán an níṣẹ́ sí ìran Lárúbáwá ní àpapọ̀ tàbí sí ìlú kan nínú ìlú àwọn Lárúbáwá. Àmọ́ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán an níṣẹ́ sí ọ̀wọ́ ẹbí rẹ̀ nínú ìdílé ìyàwó rẹ̀ t’ó jẹ́ Lárúbáwá. Ìyẹn sì ni àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 19:54-55.
Bákan náà, tòhun ti bí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n fún ní tírà Taorāt, iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ kò kúkú kan àwọn ènìyàn Kidr (rọdiyallāhu 'anhu). Kódà Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ìbá tí mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan tún wà ní àyè mìíràn lábẹ́ Kidr tí kò bá jẹ́ pé Allāhu pa á láṣẹ láti ṣàbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wàyí bí a ṣe rí àwọn āyah kan t’ó ń fi rinlẹ̀ pé kò sí ìjọ tí Allāhu kò rán Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:7, sūrah an-Nahl; 16:36 àti sūrah Fātir; 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:46, sūrah Saba’; 34:44, sūrah as-Sajdah; 32:3 àti sūrah Yāsīn; 36:6.)
Ẹ rántí àlàyé tí mo mú wá lórí iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ’Isma‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Lẹ́yìn náà, àgbọ́yé t’ó wà nínú àwọn āyah t’ó wá lórí àìsí Òjíṣẹ́ fún àwọn Lárúbáwá ni pé, kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀, Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan, àti pé àwọn méjèèjì ni wọ́n mọ Ilé Kaaba ga sókè, àwọn ìran Lárúbáwá tún ní àǹfààní láti rìn kan àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Nípasẹ̀ èyí, wọ́n tún gbúròó gbọ́ nípa òǹkà púpọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ ọmọ ’Isrọ̄’īl, ní pàtàkì jùlọ nípa Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) àti Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), àmọ́ kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ Ànábì Lárúbáwá. Paríparí rẹ̀ ni pé, ìgbà pípẹ́ gbọọrọ tún wà láààrin ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gun sánmọ̀ lọ láàyè àti ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ìkẹ́yìn dìde, ìyẹn Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:19. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn fi sọ pé, irúfẹ́ àwọn ènìyàn t’o ṣẹ̀mí láààrin ìgbà náà ni wọ́n ń pè ní “’ahlu-l-fatrah”. Ọjọ́ Àjíǹde sì ni Allāhu máa tó yanjú ọ̀rọ̀ wọn. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kúkú nímọ̀ nípa ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ àti ẹni tí kò níí tẹ̀lé e nínú wọn bí Ó bá jẹ́ pé Allāhu tètè rán Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí wọn. Àpẹẹrẹ wọn tún ni àwọn ọmọdé t’ó kú ṣíwájú bíbàlágà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti nímọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá dágbà. Èyí ni òdodo ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ àwọn “’ahlu-l-fatrah”, ìyẹn àwọn t’ó ti kú ṣíwájú iṣẹ́ jíjẹ́ Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn ènìyàn mìíràn t’ó ti kú ṣíwájú tiwọn àti ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì dìde fún wọn.
Kíyè sí i, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fi àdámọ́ òye àtinúwá sára gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ láti jìnnà sí jíjọ̀sìn fún òrìṣà nítorí gbogbo ẹ̀dá l’ó ní òye pé kì í ṣe òrìṣà ni ẹlẹ́dàá àwọn, àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu, Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé, dípò kí ó jẹ́ Ànábì fún ìran Lárúbáwá nìkan gẹ́gẹ́ bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì t’ó ṣíwájú rẹ̀ ṣe jẹ́, ńṣe ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú ọlá Rẹ̀ ṣe é ni Ànábì gbogbo ayé pátápátá. Allāhu tí Ó ṣe ìṣẹ̀dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ àìlo àtọ̀ ọkùnrin kan kan fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ìyàtọ̀ sí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ̀, Òun náà (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó kúkú ṣe Ànábì Muhammad ní Òjíṣẹ́ gbogbo ayé, tí kò sì sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ rí fún ṣíwájú rẹ̀. Nítorí náà, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni Ànábì àti Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ fún ẹbí rẹ̀ àti ìran rẹ̀, ìran Lárúbáwá, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ìkẹ́yìn fún àpapọ̀ Lárúbáwá àti àwọn elédè mìíràn pátápátá.

Tí ó bá jẹ́ pé àdánwò kan kàn wọ́n nítorí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn tì síwájú, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa, ti Ó bá jẹ́ pé O rán Òjíṣẹ́ kan sí wa ni, a à bá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ, a à bá sì wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Ṣùgbọ́n nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní irú ohun tí Wọ́n fún (Ànábì) Mūsā?" Ṣé wọn kò sì ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí A fún (Ànábì) Mūsā ṣíwájú bí? Wọ́n wí pé: “Òpìdán méjì t’ó ń ranra wọn lọ́wọ́ (ni wọ́n).” Wọ́n sì tún wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìkọ̀ọ̀kan (wọn).”
Sọ pé: “Nítorí náà, ẹ mú tírà kan wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, t’ó ń tọ́ ni sí ọ̀nà ju ti àwọn méjèèjì lọ, mo sì máa tẹ̀lé e, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Tí wọn kò bá jẹ́pè rẹ, mọ̀ pé wọ́n kàn ń tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni. Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni t’ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, láì sí ìmọ̀nà (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu! Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Àti pé dájúdájú A ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Àwọn tí A fún ní Tírà ṣíwájú rẹ̀, wọ́n gba al-Ƙur’ān gbọ́.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọ́n á sọ pé: “A gbà á gbọ́. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa. Dájúdájú àwa ti jẹ́ mùsùlùmí ṣíwájú rẹ̀.”
____________________
Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n tì wà ní ipò mùsùlùmí lórí sunnah Ànábì ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām), tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tún dé bá wọn láyé, tí wọ́n sì gbà fún sunnah tirẹ̀ náà. Wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún wọn ní ẹ̀san wọn ní ẹ̀ẹ̀ mejì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù, wọ́n sì ń fi dáadáa ti àìdaa dànù. Àti pé wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ burúkú, wọ́n á ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì sọ pé: “Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kí àlàáfíà máa ba yín. A kò wá àwọn aláìmọ̀kan (ní alábàáṣepọ̀).”
Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
____________________
"Hidāyah" túmọ̀ sí ìwọ̀nyí: (1) Ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú àdúà nínú sūrah al-Fātihah; 1:6. (2) Ṣíṣí ọkàn ẹ̀dá payá fún gbígba ẹ̀sìn ’Islām. Kò sí èyí lọ́wọ́ ẹnì kan àfi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nítorí pé, ọwọ́ Rẹ̀ ni ọkàn ẹ̀dá wà. Hidayah t’ó ń túmọ̀ sí ìṣípayá ọkàn fún gbígbà ẹ̀sìn ’Islām l’ó jẹyọ ní àyè yìí, ìyẹn sūrah al-Ƙọs̱ọs̱; 28:56 àti nínú sūrah al-Hajj; 22:24 pẹ̀lú sūrah az-Zukruf; 43:40. (3) Fífi al-Ƙur’ān àti sunnah ṣàlàyé ìmọ̀nà sí ọ̀nà tààrà ’Islām, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52. (4) Títọ́ka ènìyàn sí ibì kan tàbí fífi ojú-ọ̀nà kan mọ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹyọ nínú sūrah as-Sọffāt; 37:23. Nítorí náà, kókó ọ̀rọ́ ni pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú al-Ƙur’ān àti sunnah rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá, ṣùgbọ́n Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Olùtọ́ni-sọ́nà pẹ̀lú ìṣípayá-ọkàn fún ẹni tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá fẹ́ nítorí pé, àdéhùn Rẹ̀ ni pé, igun kan fún Ọgbà Ìdẹ̀ra, igun kan fún Ọgbà Iná.

Wọ́n wí pé: “Tí a bá (fi lè) tẹ̀lé ìmọ̀nà pẹ̀lú rẹ, àwọn ọ̀ṣẹbọ yóò kó wa kúrò lórí ilẹ̀ wa.” Ṣé A ò fún wọn ní ibùgbé (tí ó jẹ́) àyè ọ̀wọ̀ ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì ń kó àwọn èso gbogbo ìlú wá síbẹ̀, tí ó jẹ́ èsè láti ọ̀dọ̀ Wa? Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Mélòó mélòó nínú ìlú tí A parẹ́, tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ ayé-jíjẹ nínú ìlú. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ibùgbé wọn, tí A kò jẹ́ kí ẹnì kan kan gbé ibẹ̀ lẹ́yìn wọn bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. Àwa sì jẹ́ Olùjogún.
Olúwa rẹ kò sì níí pa àwọn ìlú run (ní àsìkò tìrẹ yìí) títí Ó fi máa gbé Òjíṣẹ́ kan dìde nínú Olú-ìlú-ayé (ìyẹn, ìlú Mọkkah, ẹni tí) yóò máa ké àwọn āyah Wa fún wọn. (Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.) A ò sì níí pa àwọn ìlú (yìí) run sẹ́ àfi kí àwọn ara ibẹ̀ jẹ́ alábòsí.
Kò sí ohun tí A fun yín bí kò ṣe nítorí ìgbádùn ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Ohun t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Ǹjẹ́ ẹni tí A bá ṣàdéhùn ní àdéhùn t’ó dára, tí ó sì máa pàdé rẹ̀, dà bí ẹni tí A fún ní ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé bí, lẹ́yìn náà ní Ọjọ́ Àjíǹde tí ó máa wà nínú àwọn tí wọn yóò mú wá (fún ìyà Iná)?
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí wí pé: “Olúwa wa, àwọn wọ̀nyí tí a kó ṣìnà, a kó wọn ṣìnà gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe ṣìnà. A yọwọ́ yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀ wọn) níwájú Rẹ (báyìí); kì í ṣe àwa ni wọ́n ń jọ́sìn fún.”
A sọ (fún wọn) pé: “Ẹ pe àwọn òrìṣà yín.” Wọ́n sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kò dá wọn lóhùn. Wọ́n ti rí Iná. Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n jẹ́ olùmọ̀nà ni (ìyà ìbá tí jẹ wọ́n.)
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Kí ni ẹ fọ̀ ní èsì fún àwọn Òjíṣẹ́?”
Èsì ọ̀rọ̀ yó sì fọ́jú pọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ yẹn; wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ó súnmọ́ pé ó máa wà nínú àwọn olùjèrè.
Olúwa rẹ l’Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń ṣa (ohun tí Ó bá fẹ́) ní ẹ̀ṣà. Ṣíṣa ẹ̀ṣà kò tọ́ sí wọn. Mímọ́ ni fún Allāhu. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Olúwa rẹ sì mọ ohun tí igbá-àyà wọn ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀.
Òun sì ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. TiRẹ̀ ni ọpẹ́ ní ilé ayé yìí àti ní ọ̀run. TiRẹ̀ sì ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ òru di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní ìmọ́lẹ̀? Ṣé ẹ ò gbọ́rọ̀ ni?”
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá sọ ọ̀sán di ohun tí ó máa wà títí láéláé fun yín di Ọjọ́ Àjíǹde, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu l’ó máa fun yín ní alẹ́ tí ẹ óò máa sinmi nínú rẹ̀? Ṣé ẹ ò ríran ni?”
Nínú ìkẹ́ Rẹ̀ (ni pé) Ó ṣe òru àti ọ̀sán fun yín; nítorí kí ẹ lè sinmi nínú (òru) àti nítorí kí ẹ lè wá nínú oore Rẹ̀ (ní ọ̀sán) àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò pè wọ́n, Ó sì máa sọ pé: “Níbo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ wà?”
A sì máa mú ẹlẹ́rìí kan jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. A máa sọ pé: “Ẹ mú ìdí ọ̀rọ̀ yín wá.” Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ń jẹ́ ti Allāhu. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ yó sì dòfo mọ́ wọn lọ́wọ́.
Dájúdájú Ƙọ̄rūn wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ṣùgbọ́n ó ṣègbéraga sí wọn. A sì fún un ní àwọn àpótí-ọrọ̀ èyí tí àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ wúwo láti gbé fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn alágbára. (Rántí) nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ fún un pé: "Má ṣe yọ ayọ̀ àyọ̀jù. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn aláyọ̀jù.
Fi n̄ǹkan tí Allāhu fún ọ wá ilé Ìkẹ́yìn. Má ṣe gbàgbé ìpín rẹ ní ilé ayé. Ṣe dáadáa gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe dáadáa fún ọ. Má sì ṣe wá ìbàjẹ́ ṣe lórí ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn àwọn òbìlẹ̀jẹ́."
Ó wí pé: "Dájúdájú wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ t’ó ń bẹ lọ́dọ̀ mi ni." Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ti parun nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú rẹ̀, ẹni tí ó lágbára jù ú lọ, tí ó sì ní àkójọ ọrọ̀ jù ú lọ? A ò sì níí bi àwọn arúfin léèrè (ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó kúkú ti wà ní àkọsílẹ̀.)
Ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ rẹ̀. Àwọn t’ó ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí sì wí pé: “Háà! Kí á sì ní irú ohun tí wọ́n fún Ƙọ̄rūn. Dájúdájú ó ní ìpín ńlá nínú oore.”
Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ sọ pé: “Ègbé ni fun yín! Ẹ̀san Allāhu lóore jùlọ fún ẹni t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì sí ẹni tí ó máa rí (ẹ̀san náà) gbà àfi àwọn onísùúrù.”
Nítorí náà, A jẹ́ kí ilẹ̀ gbé òun àti ilé rẹ̀ mì. Kò ní ìjọ kan tí ó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì sí nínú àwọn t’ó lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
Àwọn t’ó ń rankàn ipò rẹ̀ ní àná sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ṣé ẹ rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu kẹ́ wa ni, ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ gbé àwa náà mì ni. Ṣé ẹ rí i pé àwọn aláìmoore kò níí jèrè.”
Ilé Ìkẹ́yìn yẹn, A máa fi fún àwọn tí kò fẹ́ máa ṣe ìgbéraga àti ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú iṣẹ́ rere wá, tirẹ̀ ni rere t’ó lóore jùlọ sí èyí t’ó mú wá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú iṣẹ́ aburú wá, A ò sì níí san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san kan àfi ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Dájúdájú Ẹni tí Ó ṣe al-Ƙur’ān ní ọ̀ran-anyàn fún ọ, Ó sì máa dá ọ padà sí èbúté kan. Sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mú ìmọ̀nà wá àti ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
Ìwọ kò sì retí pé A óò sọ tírà al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ (tẹ́lẹ̀), àmọ́ ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ jẹ́ alátìlẹ́yìn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́ ọ lórí kúrò níbi àwọn āyah Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí A ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ. Pèpè sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Gbogbo n̄ǹkan l’ó máa parun àfi Ojú Rẹ̀ (àfi Òun). TiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni wọn yóò da yín padà sí.