ترجمة معاني سورة عبس باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

(Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà
nítorí pé afọ́jú wá bá a.
Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
tí ó sì ń páyà (Allāhu),
ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi,
àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀,
àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán.
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.