ترجمة سورة التكاثر

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة التكاثر باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
títí ẹ fi wọ inú sàréè.
Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Lẹ́yìn náà, ní òdodo láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).
Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa rí i ní àrídájú.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).
Icon