ﰆ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
ﭤ
ﰀ
Allāhu búra pẹ̀lú àfẹ̀mọ́júmọ́.
ﭦﭧ
ﰁ
Ó tún búra pẹ̀lú àwọn òru mẹ́wàá kan.
ﭩﭪ
ﰂ
Ó tún búra pẹ̀lú méjì àti ẹyọ.
Ó tún búra pẹ̀lú òru nígbà tí ó bá lọ (tí ó bá dé).
Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
Ṣé o ò rí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
àwọn tí A ò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonífojì,
àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn t’ó tayọ ẹnu-àlà nínú ìlú.
Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti pọ́n mi lé."
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: "Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi."
Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (t’ó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
Ó máa wí pé: "Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi."
Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
ﭺﭻ
ﰝ
Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.