surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Hā mīm.
Ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí kan (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(Èyí ni) Tírà kan tí Wọ́n ṣàlàyé àwọn āyah inú rẹ̀; al-Ƙur’ān ní èdè Lárúbáwá ni fún ìjọ t’ó nímọ̀.
(Ó jẹ́) ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gbúnrí kúrò níbẹ̀. Wọn kò sì tẹ́tí sí i.
Wọ́n sì wí pé: "Ọkàn wa wà ní títì pa sí ohun tí ẹ̀ ń pè wá sí. Èdídí sì wà nínú etí wa. Àti pé gàgá wà láààrin àwa àti ìwọ. Nítorí náà, máa ṣe tìrẹ. Dájúdájú àwa náà ń ṣe tiwa."
Sọ pé: "Abara bí irú yín kúkú ni èmi náà. Wọ́n ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi ni, pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin tì Í, kí ẹ sì tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ègbé sì ni fún àwọn ọ̀ṣẹbọ,
àwọn tí kò yọ Zakāh. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pẹ̀dín ń bẹ fún wọn.
Sọ pé: "Ṣé dájúdájú ẹ̀yin máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ fún ọjọ́ méjì, ẹ sì ń sọ (ẹ̀dá Rẹ̀) di akẹgbẹ́ fún Un?" Ìyẹn sì ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Ó sì fi àwọn àpáta sínú ilẹ̀ láti òkè rẹ̀. Ó fi ìbùkún sínú rẹ̀. Ó sì pèbùbù àwọn arísìkí (àti ohun àmúsọrọ̀) sínú rẹ̀ láààrin ọjọ́ mẹ́rin. (Àwọn ọjọ́ náà) dọ́gba (síra wọn) fún àwọn olùbèèrè (nípa rẹ̀).
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah yìí tako àwọn āyah t’ó ń fi ọjọ́ mẹ́fà rinlẹ̀ fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Wọ́n ni āyah yìí pè é ní ọjọ́ mẹ́jọ, àwọn āyah yòókù pè é ní ọjọ́ mẹ́fà. Àwọn kristiẹni tún sọ pé, yálà ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ, ìkíní kejì tún tako àwọn āyah kunfayakūn t’ó wà nínú al-Ƙur’ān. Wọ́n ní, “Kò wulẹ̀ yẹ kí Allāhu lo ọjọ́ mẹ́fà tàbí ọjọ́ mẹ́jọ kan kan mọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé Ó ti sọ nínú al-Ƙur’ān pé nígbà tí Òun bá gbèrò láti ṣẹ̀dá n̄ǹkan, gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀” ni Òun máa ń sọ.”
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni èyí. Kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé ọ̀rọ̀ nìyí. Ní ti òǹkà ọjọ́ fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ àti ilẹ̀, àyè mẹ́jọ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ní àyè mẹ́rin nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:54, sūrah Yūnus; 10:3, sūrah Hūd; 11:7 àti sūrah al-Hadīd; 57:4. Ní àyè mẹ́ta nínú wọn, ó jẹyọ nínú wọn pé, “Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì fún ọjọ́ mẹ́fà.” Ó wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Furƙọ̄n; 25:59, sūrah as-Sajdah; 32:4 àti sūrah Ƙọ̄f; 50:38. Kíyè sí awẹ́ gbólóhùn “àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì”. Ìyẹn ti fi hàn pé, ọjọ́ méjì ni Allāhu lò fún ìṣẹ̀dá sánmọ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀dá ilẹ̀ méje, ọjọ́ méjì fún ìṣẹ̀da ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì sì ń túmọ̀ sí gbogbo ohun t’ó wà lórí ilẹ̀. Èyí tí já sí pé, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà lórí ilẹ̀ kó ọjọ́ mẹ́rin nínú ọjọ́ mẹ́fà. Àtúpalẹ̀ ìṣírò yìí ni Allāhu fún ara Rẹ̀ fi rinlẹ̀ nínú āyah tí à ń ṣe ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún yìí, sūrah Fussilat 41; 9-10. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ èdè Lárúbáwá àti àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām fi ṣàlàyé āyah 10 pé ọjọ́ mẹ́rin yẹn kó ọjọ́ méjì tí Allāhu dárúkọ nínú āyah 9 sínú. Wọ́n ní àpapọ̀ ọjọ́ ìṣẹ̀dá ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ ni òǹkà ọjọ́ mẹ́rin náà dúró fún, kì í ṣe fún ohunkóhun t’ó wà lórí ilẹ̀ nìkan, gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn àwọn aláìnímọ̀ nípa ìlò èdè Lárúbáwá. Irúfẹ́ ìṣírò yìí l’ó tún jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:3 àti Fātir; 35:1. Ní ti gbólóhùn “kunfayakūn” tí í ṣe “Jẹ́ bẹ́ẹ̀-ó-sì-máa-jẹ́-bẹ́ẹ̀”, kò rújú rárá pé, Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àmọ́ t’òhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Allāhu kì í ṣe n̄ǹkan pẹ̀lú ìkánjú. Àti pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí ṣe ìṣe kan tí ó máa mú kí ìtakora ṣẹlẹ̀ láààrin àwọn orúkọ Rẹ̀ t’ó dára jùlọ àti àwọn ìròyìn Rẹ̀ t’ó ga jùlọ. Ẹ̀dá l’ó lè jẹ́ alágbára-mámèrò, kì í ṣe Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó wà lábẹ́ lílo òǹkà ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run.
Ipò tí gbólóhùn “kunfayakūn” wà nínú ìṣẹ̀dá ni ipò ìparí ọ̀rọ̀ àti àṣẹ dídi bíbẹ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn ìkójọ èròjà ìṣẹ̀dá, n̄ǹkan náà kò níí dòhun àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”. Àwọn ẹ̀dá tí kò bá sì jẹmọ́ èròjà ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ẹ̀dá tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò sọ nípa èròjà ìṣẹ̀dá wọn fún wa, Allāhu l’Ó kúkú nímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, ìkíní kejì kò níí di ẹ̀dá àfi pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”.
Pẹ̀lú àlàyé yìí, ó ń túmọ̀ sí pé, àwọn ẹ̀dá kan di ẹ̀dá pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn” nìkan. Àwọn ẹ̀dá kan sì di ẹ̀dá nípasẹ̀ èròjà ìṣẹ̀dá àti gbólóhùn “kunfayakūn”. Allāhu ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀nà tí Ó bá fẹ́. Nítorí náà, gbólóhùn “kunfayakūn” t’ó jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoṣo kò lè sọ Allāhu di olùkánjú. Ìkánjú kì í ṣe ìròyìn rere fún Allāhu. Bí Allāhu ṣe gbàròyìn pẹ̀lú gbólóhùn “kunfayakūn”, bẹ́ẹ̀ náà l’Ó ṣe gbàròyìn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, èyí tí í ṣe ìdà kejì ìkánjú. Nítorí náà, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lágbára láti ṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run láààrin ohun tí ó kéré jùlọ sí ìṣẹ́jú kan. Bí Ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò kúkú sí ẹni tí Ó lè pè É lẹ́jọ́. Bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá sì lo ọjọ́ mẹ́fà fún ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àṣẹ “Jẹ́-bẹ́ẹ̀” kò jẹ́ tiRẹ̀. Òun l’Ó kúkú ni gbogbo ìjọba, gbogbo agbára àti gbogbo ògo.
Lẹ́yìn náà, Allāhu wà ní òkè sánmọ̀, nígbà tí sánmọ̀ wà ní èéfín. Ó sì sọ fún òhun àti ilẹ̀ pé: "Ẹ wá bí ẹ fẹ́ tàbí ẹ kọ̀." Àwọn méjèèjì sọ pé: "A wá pẹ̀lú ìfínnú-fíndọ̀."
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Anbiyā’; 21:30.
Ó sì parí (ìṣẹ̀dá) rẹ̀ sí sánmọ̀ méje fún ọjọ́ méjì. Ó sì fi iṣẹ́ sánmọ̀ kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sínú rẹ̀. A sì fi àwọn àtùpà (ìràwọ̀) ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ àti ààbò (fún un). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.
Tí wọ́n bá gbúnrí, sọ pé: "Èmi ń ṣèkìlọ̀ ìparun irú ìparun ìjọ ‘Ād àti Thamūd fun yín ni."
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn, (wọ́n sọ) pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu." Wọ́n wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
____________________
"níwájú wọn" túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ (ahm.s.s.) wá bá àwọn bàbá ńlá wọn, "lẹ́yìn wọn" sì túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ tún wá bá àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn lẹ́yìn ìparun àwọn bàbá ńlá wọn.
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Wọ́n sì wí pé: "Ta ni ó lágbára jù wá lọ ná?" Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Allāhu tí Ó ṣẹ̀dá wọn, Ó ní agbára jù wọ́n lọ ni. Wọ́n sì ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Wa!
Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:19, Allāhu dárúkọ ọjọ́ kan fún ìparun ìjọ ‘Ād. Àmọ́ nínú sūrah al-Hāƙƙọh; 69:7, Allāhu dárúkọ òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ fún ìparun wọn. Nínú sūrah Fussilat; 41:16, Allāhu dárúkọ àwọn ọjọ́? Wọ́n ní, “Nítorí náà, ìtakora ti jẹyọ lórí òǹkà ọjọ́ ti Allāhu fi pa ìjọ ‘Ād run!
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà. Àlàyé rẹ̀ nìyí, āyah ti sūrah al-Ƙọmọr t’ó pè é ní ọjọ́ kan sọ pé “ọjọ́ burúkú kan t’ó ń tẹ̀ síwájú.” Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé, àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú aláìmọ̀kan.
Ní ti ìjọ Thamūd, A ṣàlàyé ìmọ̀nà fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àìríran dípò ìmọ̀nà. Nítorí náà, igbe ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá gbá wọn mú nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Ìyẹn nípasẹ̀ pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) rán àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí wọn.
A sì gba àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu) là.
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa kó àwọn ọ̀tá Allāhu jọ síbi Iná, wọn yó sì kó àwọn ẹni àkọ́kọ́ wọn papọ̀ mọ́ àwọn ẹni ìkẹ́yìn wọn
títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀ tán, ìgbọ́rọ̀ wọn, ìríran wọn àti awọ ara wọn yó sì máa jẹ́rìí lé wọn lórí nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọn yóò wí fún awọ ara wọn pé: "Nítorí kí ni ẹ ṣe jẹ́rìí lé wa lórí ná?" Wọ́n yóò sọ pé: "Allāhu, Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ọ̀rọ̀ sọ, Òun l’Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ sọ. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."
Ẹ̀yin kò lè para yín mọ́ (kúrò níbi ẹ̀ṣẹ̀, nítorí) kí ìgbọ́rọ̀ yín, ìríran yín àti awọ ara yín má fi lè jẹ́rìí le yín lórí. Ṣùgbọ́n ẹ lérò pé dájúdájú Allāhu kò mọ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ìyẹn, èrò yín tí ẹ lérò sí Olúwa yín ló kó ìparun ba yín. Ẹ sì di ẹni òfò.
Tí wọ́n bá ṣe sùúrù (fún ìyà), Iná kúkú ni ibùgbé fún wọn. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣẹ́rí padà sí ṣíṣe ohun tí Allāhu yọ́nú sí (ní àsìkò yìí), A ò níí gbà wọ́n láyè láti ṣẹ́rí padà.
Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn, tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ t’ó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Ẹ má ṣe tẹ́tí sí al-Ƙur’ān yìí. Kí ẹ sì sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀ kí ẹ lè borí."
Nítorí náà, dájúdájú A óò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ níyà líle tọ́ wò. Àti pé dájúdájú A óò fi èyí t’ó burú ju èyí tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san.
Iná, ìyẹn ni ẹ̀san àwọn ọ̀tá Allāhu. Ilé gbére wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ó jẹ́ ẹ̀san nítorí pé wọ́n ń tako àwọn āyah Wa.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: "Olúwa wa, fi àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣì wá lọ́nà nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn hàn wá nítorí kí á lè fi àwọn méjèèjì sí abẹ́ gìgísẹ̀ wa, nítorí kí wọ́n lè wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá."
Dájúdájú àwọn t’ó sọ pé: "Allāhu ni Olúwa wa." lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin, àwọn mọlāika yóò máa sọ̀kalẹ̀ wá bá wọn (ní ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì máa sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà, ẹ má ṣe banújẹ́. Kí ẹ sì dunnú sí Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín.
Àwa ni ọ̀rẹ́ yín nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní ọ̀run. Ohun tí ẹ̀mí yín ń fẹ́ ti wà fun yín nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún sì ti wà nínú rẹ̀.
N̄ǹkan ìgbàlejò ni láti ọ̀dọ̀ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Ta ni ó dára jùlọ ní ọ̀rọ̀ sísọ t’ó tayọ ẹni tí ó pèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ṣe iṣẹ́ rere, tí ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn mùsùlùmí."
Rere àti aburú kò dọ́gba. Fi èyí tí ó dára jùlọ dènà (aburú). Nígbà náà ni ẹni tí ọ̀tá wà láààrin ìwọ àti òun máa dà bí ọ̀rẹ́ alásùn-únmọ́ pẹ́kípẹ́kí.
____________________
Fífi rere dènà aburú ni ṣíṣe sùúrù pẹ̀lú ẹni tí ó ń bínú sí wa, ṣíṣe rere sí ẹni tí ó ń ṣe aburú sí wa, kíkí ẹni tí ó ń yàn wá lódì, ṣíṣe àtẹ̀mọ́ra pẹ̀lú ẹni tí ó ń hùwà àìmọ̀kan sí wa, wíwo ẹni tí ó ń ṣépè fún wa níran, wíwo ẹni tí ó ń bú wa níran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwọ̀nyí ni kí mùsùlùmí fi ṣẹwà nítorí kí àwa náa má baà di ẹni aburú àti nítorí kí èṣù má baà rí wa lò.
A ò níí fún ẹnì kan ní (ìwà rere yìí) àfi àwọn t’ó ṣe sùúrù. A ò níí fún ẹnì kan sẹ́ àfi olórí-ire ńlá.
Àti pé tí èròkérò kan láti ọ̀dọ̀ Èṣù bá fẹ́ ṣẹ́ ọ lórí (kúrò níbi ìwà rere yìí), sá di Allāhu. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni òru, ọ̀sán, òòrùn àti òṣùpá. Ẹ ò gbọdọ̀ forí kanlẹ̀ fún òòrùn àti òṣùpá. Ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, Ẹni tí Ó dá wọn, tí ẹ̀yin bá jẹ́ ẹni t’ó ń jọ́sìn fún Òun nìkan ṣoṣo.
Tí wọ́n bá sì ṣègbéraga, àwọn t’ó wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, wọ́n ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un ní alẹ́ àti ní ọ̀sán; wọn kò sì kágara.
Nínú àwọn àmì Rẹ̀ tún ni pé dájúdájú ìwọ yóò rí ilẹ̀ ní asálẹ̀. Nígbà tí A bá sì sọ omi kalẹ̀ lé e lórí, ó máa rúra wá, ó sì máa ga (fún híhu irúgbìn jáde). Dájúdájú Ẹni tí Ó jí i, Òun mà ni Ẹni tí Ó máa sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú àwọn t’ó ń yẹ àwọn āyah Wa (síbi òmíràn), wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Nínú yíyẹ āyah al-Ƙur’ān síbi òmíràn ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ṣókí, ẹni t’ó ń yẹ āyah al-Ƙur’ān síbi òmíràn ni ẹni tí kò tẹ̀lé àwọn äyah al-Ƙur’ān ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ àti ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àpẹẹrẹ igun kìíní ni àwọn oníbídíà bíí àwọn sūfī, àwọn Ahmadi àti àwọn oníjálàbí. Àpẹẹrẹ igun kejì ni àwọn ọ̀ṣẹbọ, àwọn kristiẹni àti àwọn yẹhudi.
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú Tírà Ìrántí náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) nígbà tí ó dé bá wọn (ẹni ìparun ni wọ́n.) Dájúdájú òhun mà ni Tírà t’ó lágbára.
Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀. Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn.
____________________
Ìyẹn ni pé, kò sí tírà sánmọ̀ kan tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irọ́ wà nínú al-Ƙur’ān ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀. Kò sì níí sí tírà kan kan lẹ́yìn rẹ̀ tí ó máa pe al-Ƙur’ān nírọ́. Ní ṣókí, kò sí ẹni tí ó lè rí āyah kan pè ní irọ́ nínú al-Ƙur’ān. Èyí jẹ́ ààbò mímọ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi bo al-Ƙur’ān yàtọ̀ sí àwọn tírà yòókù. Àwọn tírà yòókù, bíi Bíbélì, ni ọwọ́kọ́wọ́ ti wọ inú wọn ní ìbámú sí sūrah al-Baƙọrah; 2:75 àti 79 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Ìdí nìyí tí àjọ aláṣẹ atẹbíbélìtà “The Bible Societies” fi tú bíbélì ní àṣírí nínú ọ̀rọ̀ ìṣaájú tí wọ́n kọ fún “Revised Standard Version” pé: “Àwọn ìwé bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì wáyé láti inú ojúlówó èdè Hébérù àti èdè Greek tààrà. Títúmọ̀ ìwé bíbélì t’ó sì jẹ́ àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ni iṣẹ́ ọwọ́ William Tyndale. Ó fojú winá àtakò t’ó lágbára. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó fínnú-fíndọ̀ dojú ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú bíbélì rú, wọ́n sì pa á láṣẹ pé kí wọ́n dáná sun àwọn májẹ̀mu titun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ “àwọn ìtúmọ̀ tí kì í ṣe òdodo”. Arákùnrin náà padà bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀, wọ́n pa á níta gban̄gba, wọ́n kangi ikú fún un, wọ́n sì dáná sun ún lórí rẹ̀ ní October 1536. Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí Tyndale ṣe ló padà di ìpìlẹ̀ ìtọ́kasí fún àwọn bíbélì tí wọ́n ń padà túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì… Àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì ti King James Version ṣe àkíyèsí sí àwọn èyí tí wọ́n ti ṣe ṣíwájú; … Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí King James Version ṣe tún ní àléébù t’ó burú gan-an nínú. Láààrin 19 sẹ́ńtúrì, ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ bíbélì àti ṣíṣe àwárí àwọn àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ bíbélì tí ó lọ́jọ́ lórí ju èyí tí king James Version gbé iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì tirẹ̀ lé lórí, ó fi hàn kedere pé àwọn àlèébù wọ̀nyí pọ̀ púpọ̀ gan-an, wọ́n sì lágbára gan-an dé ibi pé ó bèèrè fún àtúnṣe àwọn ìtúmọ̀ tí wọ́n túmọ̀ bíbélì sí…"
Wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan sí ọ bí kò ṣe ohun tí wọ́n ti sọ sí àwọn Òjíṣẹ́ t’ó ṣíwájú rẹ. Dájúdájú Olúwa rẹ mà ni Aláforíjìn, Ó sì ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro (lọ́dọ̀).
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe al-Ƙur’ān ní n̄ǹkan kíké ní èdè mìíràn yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá ni, wọn ìbá wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n ṣe àlàyé àwọn āyah rẹ̀?" Báwo ni al-Ƙur’ān ṣe lè jẹ́ èdè mìíràn (yàtọ̀ sí èdè Lárúbáwá), nígbà tí Ànábì (Muhammad s.a.w.) jẹ́ Lárúbáwá? Sọ pé: "Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìwòsàn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Àwọn tí kò sì gbàgbọ́, èdídí wà nínú etí wọn. Fọ́júǹfọ́jú sì wà nínú ojú wọn sí (òdodo al-Ƙur’ān). Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n sì ń pè (síbi òdodo al-Ƙur’ān) láti àyè t’ó jìnnà.
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọ nù jìnnà.
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu sí i. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ́ kan tí ó ti ṣíwájú ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, A ìbá ṣe ìdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n tún wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe aburú, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣe àbòsí sí àwọn ẹrúsìn.
Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: "Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?" Wọ́n á wí pé: "Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé O ní akẹgbẹ́.)"
Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì dòfò mọ́ wọn lọ́wọ́. Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé kò sí ibùsásí kan fún àwọn.
Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná.
Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: "Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀." Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà t’ó nípọn tọ́ wò.
Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ.
Sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)" Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa t’ó jìnnà (sí òdodo)!
A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan?
Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká.