ترجمة معاني سورة المزّمّل باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ìwọ olùdaṣọbora.
Dìde (kírun) ní òru àyàfi fún ìgbà díẹ̀.
Lo ìlàjì rẹ̀ tàbí dín díẹ̀ kù nínú rẹ̀.
Tàbí fi kún un. Kí o sì ké al-Ƙur’ān ní pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
____________________
Ní ìbámu sí āyah yìí, kí ẹnì kan ké odidi al-Ƙur’ān parí láààrin àsìkò díẹ̀ nípasẹ̀ ìkánjú kò lè mú kí onítọ̀ún gbádùn adùn al-Ƙur’ān. Kò sì lè mú ẹ̀san rẹ̀ kún kẹ́kẹ́. Lára oore tí ó rọ̀ mọ́ kíké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ni pé, ó máa fún wa ní àǹfààní láti rí àwọn lẹ́tà (ìró) rẹ̀ pè dáradára. Ó máa ṣe àlékún àgbọ́yé àti àfọkànsí fún wa. Ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu sì fẹ̀ẹ̀kan ni kíké al-Ƙur’ān pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
Dájúdájú Àwa máa gbé ọ̀rọ̀ t’ó lágbára fún ọ.
Dájúdájú ìdìde kírun lóru, ó wọnú ọkàn jùlọ, ó sì dára jùlọ fún kíké (al-Ƙur’ān).
Dájúdájú iṣẹ́ púpọ̀ wà fún ọ ní ọ̀sán.
Rántí orúkọ Olúwa rẹ. Kí o sì da ọkàn kọ Ọ́ pátápátá.
Olúwa ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, mú Un ní Aláfẹ̀yìntì.
Kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí. Pa wọ́n tì ní ìpatì t’ó rẹwà.
Fi Mí dá àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn ọlọ́rọ̀. Kí o sì lọ́ra fún wọn fún ìgbà díẹ̀.
Dájúdájú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ àti Iná Jẹhīm ń bẹ lọ́dọ̀ Wa.
Oúnjẹ háfunháfun àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro (tún wà fún wọn).
Ní ọjọ́ tí ilẹ̀ àti àwọn àpáta yóò máa mì tìtì pẹ̀lú ohùn igbe líle. Àwọn àpáta sì máa di yanrìn tí wọ́n kójọ tí wọ́n túká.
Dájúdájú Àwa rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ si yín (tí ó jẹ́) olùjẹ́rìí lórí yín gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ sí Fir‘aon.
Ṣùgbọ́n Fir‘aon yapa Òjíṣẹ́ náà. A sì gbá a mú ní ìgbámú líle.
Tí ẹ̀yin bá ṣàì gbàgbọ́, báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe bẹ̀rù ọjọ́ kan t’ó máa mú àwọn ọmọdé hewú?
Sánmọ̀ sì máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú rẹ̀. Àdéhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa ṣẹ.
Dájúdájú èyí ni ìrántí. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ojú ọ̀nà kan tọ̀ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.
Dájúdájú Olúwa rẹ mọ̀ pé dájúdájú ìwọ ń dìde kírun fún ohun t’ó kéré sí ìlàta méjì òru tàbí ìlàjì rẹ̀ tàbí ìlàta rẹ̀. Igun kan nínú àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀). Allāhu l’Ó ń ṣòdíwọ̀n òru àti ọ̀sán. Ó sì mọ̀ pé ẹ kò lè ṣọ́ ọ. Nítorí náà, Ó ti dá a padà sí fífúyẹ́ fun yín. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fun yín) nínú al-Ƙur’ān. Ó mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò wà nínú yín. Àwọn mìíràn sì ń rìrìn àjò lórí-ilẹ̀, tí wọ́n ń wá nínú oore Allāhu. Àwọn mìíràn sì ń jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹ ké ohun tí ó bá rọrùn (fun yín) nínú rẹ̀. Ẹ kírun (ọ̀ran-an-yàn). Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì yá Allāhu ní dúkìá t’ó dára. Ohunkóhun tí ẹ bá tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín nínú ohun rere, ẹ̀yin yóò bá a lọ́dọ̀ Allāhu ní ohun rere àti ní ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀san. Ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ìṣọ́-òru jẹ́ iṣẹ́ tí ẹ̀dá kò lágbára láti ṣe. Ìṣọ́-òru ni kí ẹ̀dá lérò pé òun kò níí fojú kan oorun láti alẹ́ mọ́júmọ́ lójojúmọ́.