Al-Isra 17:78

سورة الإسراء

Meccan Verse: 78/111 Page 290

أَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِدُلُوكِ ٱلشَّمۡسِ إِلَىٰ غَسَقِ ٱلَّيۡلِ وَقُرۡءَانَ ٱلۡفَجۡرِۖ إِنَّ قُرۡءَانَ ٱلۡفَجۡرِ كَانَ مَشۡهُودࣰا ٧٨

  1. Yorùbá translation

    الترجمة اليورباوية

    Gbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí.
    Ní ṣísẹ̀n̄tẹ̀lé, ìrun méjì tí a óò kí nígbà tí òòrùn bá yẹ̀tàrí ni ìrun Ṭḥuhur àti ìrun ‘Asr. Ìrun méjì tí a óò kí nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú ni ìrun Mọgrib àti ìrun ‘Iṣā’. Irun Subh sì ni āyah yìí dàpè ni Ƙur’ānul-fajr.

Read the whole surah Arabic tafsir