ﯡ
ترجمة معاني سورة الطور
باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
ﮞ
ﰀ
(Allāhu búra pẹ̀lú) àpáta Tūr.
ﮠﮡ
ﰁ
(Ó tún búra pẹ̀lú) Tírà tí wọ́n kọ sílẹ̀
sínú tákàdá tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀.
ﮧﮨ
ﰃ
(Ó tún búra pẹ̀lú) Ilé Àbẹ̀wò náà.
ﮪﮫ
ﰄ
(Ó tún búra pẹ̀lú) àjà tí wọ́n gbé sókè (ìyẹn, sánmọ̀).
ﮭﮮ
ﰅ
(Ó tún búra pẹ̀lú) agbami odò iná.
Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ máa ṣẹlẹ̀.
Kò sí olùdènà kan fún un.
(Ó máa ṣẹlẹ̀) ní ọjọ́ tí sánmọ̀ máa mì tìtì tààrà.
Àwọn àpáta sì máa rìn lọ tààrà (bí eruku àfẹ́dànù).
Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́,
àwọn tí wọ́n wà nínú ìsọkúsọ, tí wọ́n ń ṣeré.
(Rántí) ọjọ́ tí wọn yóò tì wọ́n lọ́ sínú iná Jahanamọ ní ìtìkutì.
Èyí ni Iná náà tí ẹ̀ ń pè nírọ́.
Ṣé idán ni èyí ni tàbí ẹ ò ríran?
Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ. Ẹ fara dà á tàbí ẹ ò fara dà á, bákan náà ni fun yín. Ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ ni A óò fi san yín ní ẹ̀san.
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà àti ìdẹ̀ra.
Wọn yóò máa jẹ ìgbádùn pẹ̀lú ohun tí Olúwa wọn fún wọn. Àti pé (Allāhu) yóò ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
Ẹ máa jẹ, ẹ máa mu ní gbẹdẹmukẹ nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. A sì máa fún wọn ní àwọn ìyàwó ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́.
Àti pé àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn tún tẹ̀lé wọn nínú ìgbàgbọ́ òdodo, A máa da àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn pọ̀ mọ́ wọn. A ò sì níí dín kiní kan kù nínú iṣẹ́ wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
A máa fún wọn ní àlékún èso àti ẹran tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí.
Wọn yó sì máa gba ife ọtí mu láààrin ara wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kò sí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọn yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. (Wọ́n) dà bí àlúùúlù àfipamọ́.
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, wọn yó sì máa bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ara wọn.
Wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwa jẹ́ olùpáyà láààrin àwọn ènìyàn wa.
Ṣùgbọ́n Allāhu ṣàánú wa. Ó sì là wá níbi ìyà Iná.
Dájúdájú àwa máa ń pè É tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olóore, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kì í ṣe adábigba tàbí wèrè lórí ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Eléwì kan tí à ń retí ikú rẹ̀ ni."
Sọ pé: "Ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.
Tàbí ọpọlọ wọn ń pa wọ́n láṣẹ èyí ni? Tàbí ìjọ alákọyọ ni wọ́n ni?
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni." Rárá o, wọn kò gbàgbọ́ ni.
Kí àwọn náà mú ọ̀rọ̀ kan bí irú rẹ̀ wá tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
Tàbí wọ́n ṣẹ̀dá wọn láì sí Aṣẹ̀dá? Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá ara wọn ni?
Tàbí àwọn ni wọ́n ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Rárá o, wọn kò màmọ̀ dájú ni.
Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni àwọn àpótí ọrọ̀ Olúwa rẹ wà? Tàbí àwọn ni olùborí?
Tàbí wọ́n ní àkàbà tí wọ́n ń fi gbọ́rọ̀ (nínú sánmọ̀ ni)? Kí olùgbọ́rọ̀ wọn mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá?
Tàbí àwọn ọmọbìnrin ni tiRẹ̀, àwọn ọmọkùnrin sì ni tiyín?
Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
Tàbí ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kọ ọ́ sílẹ̀?
Tàbí wọ́n ń gbèrò ète kan ni? Nígbà náà, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àwọn l’ó máa f’orí kó ète.
Tàbí wọ́n ní ọlọ́hun kan lẹ́yìn Allāhu ni? Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Tí wọ́n bá sì rí apá kan nínú sánmọ̀ t’ó ya lúlẹ̀, wọ́n á wí pé: "Ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ ni (wọn kò níí gbàgbọ́)."
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ títí wọn yóò fi bá ọjọ́ wọn tí wọn máa pa wọ́n sínú rẹ̀ pàdé.
Ọjọ́ tí ète wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àti pé dájúdájú ìyà kan ń bẹ fún àwọn t’ó ṣàbòsí yàtọ̀ sí (ìyà ọ̀run) yẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ nígbà tí ó bá ń dìde nàró (fún ìrun kíkí).
Àti ní alẹ́ (nígbà tí) àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán, ṣàfọ̀mọ́ fún Un.