ترجمة معاني سورة الزخرف باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Hā mīm.
(Allāhu) fi Tírà t’ó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
Dájúdájú Àwa sọ ọ́ ní al-Ƙur’ān. (A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní) èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ t’ó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān ga, ó kún fún ọgbọ́n.
Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fun yín, kí Á máa wò yín níran nítorí pé ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ?
Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
Nítorí náà, A ti pa àwọn t’ó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú.
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?", dájúdájú wọ́n á wí pé: "Ẹni t’ó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀;
Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fun yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà;
Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde.
Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi. Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fun yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: "Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀.
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí."
Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé.
Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): "Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà."
Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé (pé onítọ̀ún bí ọmọbìnrin), ojú rẹ̀ máa ṣókùnkùn wá. Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́.
Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé)!?
Àwọn mọlāika, àwọn t’ó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀).
Wọ́n tún wí pé: "Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn." Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur’ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí?
Rárá. Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn."
____________________
Ẹ wo āyah 37 àti 38 níwájú.
Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: "Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn."
(Olùkìlọ̀) sì sọ pé: "Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fun yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?" Wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́."
Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn olùpe-òdodo-nírọ́ ti rí!
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l’Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí."
Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan t’ó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
____________________
Ọ̀rọ̀ náà ni āyah 26 àti 27.
Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn.
Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: "Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́."
Wọ́n tún wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin pàtàkì kan nínú àwọn ìlú méjèèjì?"
Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l’A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ.
Àti pé tí kì í bá ṣe pé àwọn ènìyàn máa jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (lórí àìgbàgbọ́ ni), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni t’ó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé.
(A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)
àti góòlù. Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀.
Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: "Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni.
(Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni akẹ́gbẹ́ nínú ìyà.
Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé?
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Rūm; 30:53.
Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn.
Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn.
Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ Wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀).
Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): "Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?"
____________________
“Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa”. Àgbọ́yé méjì ni àwọn tafsīr mú wá lórí rẹ̀. Àgbọ́yé kìíní ni pé, ìbéèrè náà wáyé nínú ìrìn-àjò òru àti ìgun-sánmọ̀ tí Allāhu mú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rìn. Àgbọ́yé kejì ni pé, ìbéèrè náà wáyé láààrin Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn t’ó nímọ̀ nípa Taorāt àti ’Injīl. Ìyẹn ni pé, kí ni àwọn tírà méjèèjì sọ nípa “ta ni ìjọ́sìn tọ́ sí, ṣé Allāhu ni tàbí àwọn ọlọ́hun mìíràn?” Dídárúkọ àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ní àyè yìí dípò àwọn tírà wọn jọ bí Allāhu ṣe pàṣẹ pé “Tí ẹ bá yapa ẹnu nípa kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam),…” (ìyẹn nínú sūrah an-Nisā’; 4:59), tí èyí sì túmọ̀ sí al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: "Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá."
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà.
A ò sì níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (t’ó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Wọ́n sì wí pé: "Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀."
Ṣùgbọ́n nígbà tí A mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.
Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ ò ríran ni?
Tàbí ṣé èmi kò lóore jùlọ sí èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú?
Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀)?"
Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ dòpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò).
A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín.
Wọ́n sì wí pé: "Ṣé àwọn òrìṣà wa l’ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n.
Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
____________________
Nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi iná wíwọ̀ rínlẹ̀ fún àwọn òrìṣà àti àwọn abọ̀rìṣà wọn, ìyẹn nínú sūrah al-’Ambiyā’; 21:98-100, àwọn abọ̀rìṣà náà bá mú ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wá gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ òrìṣà àkúnlẹ̀bọ t’ó máa wọná. Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ṣàfọ̀mọ́ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fúnra Rẹ̀ pé kò sọra rẹ̀ d’òòṣà, àmọ́ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ d’òòṣà ló máa wọná. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò jọ ọ̀rọ̀ àwọn t’ó sọra wọn d’òòṣà lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Irú āyah yìí tún ni āyah tí Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ti pé àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní òkú, ìyẹn nínú sūrah an-Nahl; 16:21. Èyí tún ni ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ asòòkùn sẹ́sìn mìíràn tún sọ pé òkú ni ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá nítorí pé bí ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bá ti kú ni Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò níí sọ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń padà bọ̀ lópin aye, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú àwọn hadith rẹ̀ t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Àmọ́ sá, ìdí tí ìjọ Ahmadiyyah fi gbà pé ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú ni pé, olùdásílẹ́ ìjọ wọn, mirza ghulam Ahmad ti sọ’ra rẹ di ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìdí sì nìyí tí ìjọ Ahmadiyyah fi ń pè é ní “Mọsīh táàńretí”. Òpùrọ̀ pọ́nńbelé sì ni ọ̀gbẹni náà.
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀.
Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ ṣeyèméjì nípa rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.
____________________
Àgbọ́yé mẹ́ta ni àwọn tafsīr mú wá lórí àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ t’ó jẹyọ nínú “ wa’innahu”. Àgbọ́yé kìíní ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún “Ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ àmì láti mọ̀ pé dájúdájú Àkókò náà ti súnmọ́ pẹ́kípẹ́kí. Àgbọ́yé kejì ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ìsọ̀kalẹ̀ al-Ƙur̂ān, tí ó ń fi ìmọ̀ mọ̀ wá, tí ó sì ń fi àmì hàn wá nípa ìsúnmọ́ Àkókò náà. Àgbọ́yé kẹta ni pé, àrọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ náà dúró fún ìwásáyé Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Gbogbo rẹ̀ túmọ̀ sí pé, ìkọ̀ọ̀kan wọn ń jẹ́ àmì ńlá láti mọ̀ pé Àkókò náà ti fẹ́ ṣẹlẹ̀. Àgbọ́yé mẹ́tààta wọ̀nyí kúkú ni òdodo ọ̀rọ̀ nítorí pé, kò sí èyí tí kò ní ẹ̀rí aṣèrànwọ́ láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Kò sì sí ọ̀kan nínú àwọn àgbọ́yé mẹ́tààta wọ̀nyí tí ẹ̀rí àtakò wà fún láti inú hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ nígbà tí pọ́nna bá jẹyọ nínú āyah al-Ƙur’ān bí irú èyí, ọ̀nà kan pàtàkì nínú ìyọní-pọ́nna ni lílo hadīth Ànábì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú kí á tó lè lo hadīth kan kan fún ìyọní-pọ́nna, al-Ƙur’ān fúnra rẹ̀ ni ohun àkọ́kọ́ tí a máa lò. Èyí máa ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ wíwo sàkánì tí ọ̀rọ̀ onípọ́nna náà ti jẹyọ. A máa wòye sí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá á bọ̀ níwájú àti ọ̀rọ̀ tí ó tún mú wá lẹ́yìn rẹ̀. Kódà ìwòye yìí lè ṣẹlẹ̀ nígbà mìíràn nínú āyah kan náà tàbí nínú sūrah mìíràn pẹ̀lú. Nítorí náà, àgbọ́yé t’ó ń fi rinlẹ̀ pé ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ ni āyah náà ń sọ nípa rẹ̀ l’ó padà gbéwọ̀n jùlọ nítorí pé, ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) l’ó ń sọ bọ̀ láti inú āyah 57 títí dé āyah 65. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa al-Ƙur’ān tàbí ọ̀rọ̀ nípa Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àmọ́ sá, tí ẹnì kan bá bá àgbọ́yé mìíràn lọ nínú àwọn àgbọ́yé méjèèjì yòókù, kò la àtakò lọ níwọ̀n ìgbà tí onítọ̀un kò bá ti tako ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ lópin ayé nítorí pé, níwọ̀n ìgbà tí hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ti fi rinlẹ̀, aláìgbàgbọ́ tí ó máa jẹ̀bi ikú lábẹ́ òfin ’Islām ni ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí t’ó bá takò ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti ojú sánmọ̀ lópin ayé.
Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí; dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fun yín.
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ó sọ pé: "Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ fun yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà."
Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn ’Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura?
Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fun yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.
(Àwọn ni) àwọn t’ó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu).
Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí ẹ máa dunnú.
Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀.
Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fun yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Èso púpọ̀ wà fun yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀.
Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ.
A ò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná.
A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí.
Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: "Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú." (Mọ̄lik) yóò sọ pé: "Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni."
Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo.
Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀.
Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Rárá (À ń gbọ́); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn).
Sọ pé: "Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi).
Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn).
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
(Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun Ẹni tí ìjọ́sìn tọ́ sí lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí.
Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò kápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni." Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì ń sọ fún Allāhu ni pé): "Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́.”
Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: "Àlàáfíà!" Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.