Surah Al-Ghashiyah in Yorùbá
سورة الغاشية · Verses: 26 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡغَٰشِيَةِ
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun t’ó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ? -
2
وُجُوهࣱ يَوۡمَئِذٍ خَٰشِعَةٌ
Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn. -
3
عَامِلَةࣱ نَّاصِبَةࣱ
Oníṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni wọ́n nílé ayé). -
4
تَصۡلَىٰ نَارًا حَامِيَةࣰ
Wọ́n máa wọ inú Iná t’ó gbóná janjan (ní ọ̀run). -
5
تُسۡقَىٰ مِنۡ عَيۡنٍ ءَانِيَةࣲ
Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi gbígbóná mu. -
6
لَّيۡسَ لَهُمۡ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعࣲ
Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ. -
7
لَّا يُسۡمِنُ وَلَا يُغۡنِي مِن جُوعࣲ
Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi. -
8
وُجُوهࣱ يَوۡمَئِذࣲ نَّاعِمَةࣱ
Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn -
9
لِّسَعۡيِهَا رَاضِيَةࣱ
nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀. -
10
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةࣲ
(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga. -
11
لَّا تَسۡمَعُ فِيهَا لَٰغِيَةࣰ
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀. -
12
فِيهَا عَيۡنࣱ جَارِيَةࣱ
Omi ìṣẹ́lẹ̀rú t’ó ń ṣàn wà nínú rẹ̀. -
13
فِيهَا سُرُرࣱ مَّرۡفُوعَةࣱ
Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀, -
14
وَأَكۡوَابࣱ مَّوۡضُوعَةࣱ
àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn), -
15
وَنَمَارِقُ مَصۡفُوفَةࣱ
àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, -
16
وَزَرَابِيُّ مَبۡثُوثَةٌ
àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká. -
17
أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى ٱلۡإِبِلِ كَيۡفَ خُلِقَتۡ
Nítorí náà, ṣé wọn kò wo ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni; -
18
وَإِلَى ٱلسَّمَآءِ كَيۡفَ رُفِعَتۡ
àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè; -
19
وَإِلَى ٱلۡجِبَالِ كَيۡفَ نُصِبَتۡ
àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀); -
20
وَإِلَى ٱلۡأَرۡضِ كَيۡفَ سُطِحَتۡ
àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ ní gban̄sasa? -
21
فَذَكِّرۡ إِنَّمَآ أَنتَ مُذَكِّرࣱ
Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí. -
22
لَّسۡتَ عَلَيۡهِم بِمُصَيۡطِرٍ
Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn -
23
إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ
àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́. -
24
فَيُعَذِّبُهُ ٱللَّهُ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَكۡبَرَ
Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó tóbi jùlọ. -
25
إِنَّ إِلَيۡنَآ إِيَابَهُمۡ
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà. -
26
ثُمَّ إِنَّ عَلَيۡنَا حِسَابَهُم
Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.