ﮗ
ترجمة معاني سورة هود
باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
’Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fun yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìn dà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fun yín.
Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bo ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan t’ó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú.
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) – nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín l’ó dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà t’ó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Kí l’ó ń dá a dúró ná?” Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà t’ó máa yí wọn po.
Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore.
Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira t’ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi.” Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí.
Àyàfi àwọn t’ó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san t’ó tóbi.
Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: "Kí ni kò jẹ́ kí àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí?
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ǹjẹ́ ẹni t’ó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì s.a.w.), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni t’ó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasara, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: "Àwọn wọ̀nyí ni àwọn t’ó parọ́ mọ́ Olúwa wọn." Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí,
àwọn t’ó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A ó sì ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo).
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àfiwé ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àfiwé bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fun yín.
(Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fun yín.
Àwọn aṣíwájú t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: "Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan tayọ abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn t’ó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan tayọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni t’ó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́."
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọn kò sí jẹ́ kí ẹ ríran rí (òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ̀mí yín kọ̀ ọ́?
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn t’ó gbàgbọ́ dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan.
Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Èmi kò sì sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí."
Wọ́n wí pé: "Ìwọ Nūh, O mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo."
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Allāhu l’Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.
Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí."
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Ó hun ún ni." Sọ pé: "Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀."
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni t’ó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí. Dájúdájú A máa tẹ̀ wọ́n rì ni.
Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: "Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọmọr; 54:9.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Ƙọmọr; 54:9.
Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí."
(Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: "Kó gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni t’ó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.
(Ànábì Nūh) sọ pé: "Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ó máa rìn, ó sì máa gúnlẹ̀ ní orúkọ Allāhu. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run."
Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi t’ó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: "Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́."
Ó wí pé: “Èmi yóò forí pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa là mí níbi omi.” (Ànábì Nūh) sọ pé: "Kò sí aláàbò kan ní òní níbi àṣẹ Allāhu àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú." Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi.
A sọ pé: "Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró." Wọ́n sì dín omi kù. Ọ̀rọ̀ ìparun wọn sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. A sì sọ pé: “Ìjìnnà réré sí ìkẹ́ Allāhu ni ti ìjọ alábòsí.”
(Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l’O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́.
Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.”
____________________
Nínú èdè Lárúbáwá, wọ́n lè pe ọmọ ẹni ní iṣẹ́ ọwọ́ ẹni. Ní èdè Lárúbáwá èyí lè jẹ́ ‘amal tàbí kasb. Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “Dájúdájú n̄ǹkan t’ó dára jùlọ ni n̄ǹkan tí ẹ bá jẹ nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín. Dájúdájú nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín ni àwọn ọmọ yín wà. (Sunan at-Tirmithiy; 1358. Abu ‘Īsā at-Tirmithiy sọ pé: “Èyí ni hadīth t’ó dára, t’ó fẹsẹ̀ rìnlẹ̀.)

Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò."
A sọ pé: "Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa."
Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́.
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fun yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́)."
Wọ́n wí pé: "Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan t’ó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ.
ǹkan tí à ń sọ fún ọ ni pé àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (l’ó fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn)." Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ
dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára.
Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà.
Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fun yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan t’ó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ ò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan."
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà t’ó nípọn.
Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo.
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd.
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fun yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).”
Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.”
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun.
Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fun yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà t’ó súnmọ́ má báa jẹ yín."
Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́.”
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá).
Ohùn igbe líle gbá àwọn t’ó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí. Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, ìjìnnà réré sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìjọ Thamūd.
Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Ó sọ pé: “Àlàáfíà (fun yín).” Kò sì pẹ́ rárá t’ó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá.
Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ, ó f’ojú òdì wo (àìjẹun) wọn. Ìbẹ̀rù wọn sí wà nínú ọkàn rẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”
Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) ’Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn ’Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ).
____________________
Àsìkò tí àwọn mọlāika fẹ́ pa ìjọ Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) rẹ́ ni àsìkò tí ìró ìdùnnú àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) bọ́ sí. Èyí túmọ̀ sí pé, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti fẹ́ fi àkọ́bí rẹ̀, Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jọ́sìn fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣẹlẹ̀. Ìdí ni pé, ọlá àdúà tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe láti tọrọ ọmọ l’ó jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àmọ́ ọlá ìtẹ̀lé àṣẹ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pa pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) fi “ọmọ àdúà náà”, Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jọ́sìn fún Òun l’ó jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ishāƙ ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Kíyè sí i, àdúà “ìrawọ́rasẹ̀” sí Allāhu tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ṣe láti fi tọrọ Ànábì ’Ismọ̄‘īl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò la ìjẹ́jẹ̀ẹ́ kan kan lọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe lérò. Ẹ ka sūrah ‘Ibrọ̄hīm; 14:39 àti sūrah as-Sọ̄ffāt; 37: 100-113.

Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ? Arúgbóbìnrin ni mi, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”
Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fun yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́, Ẹlẹ́yìn.”
Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a, ó sì ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt.
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà.
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá.
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Èyí ni ọjọ́ t’ó le púpọ̀.”
Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bíi ìbálòpọ̀ láààrin ọkùnrin àti ọkùnrin). Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyẹn ni ọmọbìnrin mi, wọ́n mọ́ jùlọ fun yín (láti fi ṣaya). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin olùmọ̀nà kan nínú yín ni?"
Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò lẹ́tọ̀ọ́ kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”
Ó sọ pé: "Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan t’ó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín)."
(Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru. Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú àdánwò rẹ̀ ni ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni?
____________________
Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.
____________________
Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
(Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí.
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ẹ̀ ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fun yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po.
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gbadọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe balẹ̀ jẹ́ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.
Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fun yín (nínú halāl) lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín."
Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ l’ó ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni aláfaradà, olùmọ̀nà (lójú ara rẹ nìyẹn)."
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí t’ó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí t’ó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fun yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fun yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà).
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín.
Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá).”
Wọ́n wí pé: "Ṣu‘aeb, a ò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, a ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì níí lágbára kan lórí wa."
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn kọ̀pàkọ́ sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín).”
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbé inú ìlú náà rí. Gbọ́, ìjìnnà sí ìkẹ́ ń bẹ fún ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́.
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā
sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà.
Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú.
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn ègún tí A fún wọn sì burú.
Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí ó ti parẹ́.
A ò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.
Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le.
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni t’ó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí.
A ò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe di àkókò t’ó lọ́jọ́.
Ní ọjọ́ t’ó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà).
Ní ti àwọn t’ó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.
____________________
Ẹ wo àlàyé lórí àgbọ́yé "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’An‘ām; 6:128.
____________________
Ẹ wo àlàyé lórí àgbọ́yé "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’An‘ām; 6:128.
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ,1 àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.2 (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.
____________________
1 Bíbẹ nínú Iná àti bíbẹ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ kò túmọ̀ sí pé òpin yóò dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra gẹ́gẹ́ bí òpin yóò ṣe dé bá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìbátan níbi àfiwé tí ń bẹ láààrin àwọn méjéèjì ni pé, ó jẹ́ ara ẹwà èdè láti ṣe àfihàn ìgbà pípẹ́ fún n̄ǹkan. Lára irúfẹ èyí náà ni, bí àpẹẹrẹ, kí ọkùnrin kan sọ pé, "Èmi yóò máa jẹ́ ọkúnrin ní òdiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú, tí ilẹ̀ bá ń mọ́." Ṣíwájú sí i, ìgbàgbọ́ àwa mùsùlùmí ahlu-sunnah wal-janmọ̄n‘ah ni pé, kò sí òpin ìgbà fún Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ já sí pé, àwọn kan lè kọ́kọ́ wọ inú Iná, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) yó sì padà mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú àánú Rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣìpẹ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lẹ́yìn náà, ó máa ṣẹ́ ku kìkìdá àwọn ọmọ Iná Gbére, wọn yó sì ṣe gbére nínú Iná. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ni. Kò sì níí sí ẹnì kan tí ó máa ti inú Ọgbà Ìdẹ̀ra bọ́ sínú Iná Gbére. Ẹ̀rí nínú sunnah Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí á tún lè fi ní àgbọ́yé àwọn āyah wọ̀nyí dáradára ni hadīth Abu-Sa‘īd al-Kudri (rọdiyallāhu 'anhu). Ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ pé: "Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò mú Ikú wá ní ìrísí àgbò funfun, tí ó ní dúdú lára. Olùpèpè kan yó sì pèpè báyìí pé, 'Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra'. Àwọn ará Ọgbà Ìdẹ̀ra yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: 'Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?' Wọn yóò sọ pé: 'Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.' Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Lẹ́yìn náà, olùpèpè máa pèpè báyìí pé, 'Ẹ̀yin ará Iná'. Àwọn ará Iná yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: 'Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?' Wọn yóò wí pé: 'Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.' Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Nígbà náà, A óò pa Ikú. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan yóò sọ pé: 'Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra, gbére (ni tiyín báyìí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), kò sì sí Ikú mọ́. Olùpèpè yóò tún sọ pé: 'Ẹ̀yin ará Iná, gbére (ni tiyín báyìí nínú Iná), kò sì sí Ikú mọ́." Al-Bukāriy; Kitāb at-Tafsīr. 2 Awẹ́ gbólóhùn yìí "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́", àgbọ́yé rẹ̀ ni pípẹ́ tí àwọn kan yóò pẹ́ kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó kúkú ti hàn kedere pé àwọn kan yóò ṣíwájú àwọn mìíràn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra látára bí ìrìn-àjò ẹ̀dá bá ṣe rí lórí afárá Iná. Bákàn náà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan yóò kọ́kọ́ wọ inú Iná, ṣíwájú kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àti pé àwọn kan wulẹ̀ ti wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde ẹ̀dá. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú sí ipò ṣẹhīd, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mú hadīth wá lórí èyí nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:154. Nítorí náà, nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra, "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" túmọ̀ sí "àfi pípẹ́ tí Olúwa rẹ bá fẹ́ fún àwọn kan láti pẹ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra." Nígbà tí gbogbo wọn bá sì péjú pésẹ̀ tán sínú rẹ̀, wọn yó sì máa wà nínú rẹ̀ títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá pa Ikú. Kí Allāhu jẹ́ kí á tètè wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ní ìsọníṣókí, ìyàtọ̀ wà nínú àgbọ́yé "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nípa ti èrò Iná àti "àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́" nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àmọ́ àgbọ́yé àwọn méjèèjì kò jẹmọ́ pé òpin máa dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ọgbà gbére ni méjèèjì.

Nítorí náà, má ṣe wà nínú ròyíròyí nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí kù síbì kan.
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ kan tí ó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì t’ó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn t’ó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fun yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.
Kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀sán (ìyẹn, ìrun Subh, Ṭḥuhr àti ‘Asr) àti ní ìbẹ̀rẹ̀ òru (ìyẹn, ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’). Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).
Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran t’ó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ – àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn t’ó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.
Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa ẹnu (sí ’Islām)
àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): “Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ.”
____________________
Gbólóhùn yìí “Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn.”, ìyẹn ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dá àwọn ènìyàn àti àlùjànnú kan fún dídúró ṣinṣin lórí ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó sì dá àwọn mìíràn fún yíyapa ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Iná.

Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: "Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ.
Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí."
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.