Surah Al-Qari'ah in Yorùbá
سورة القارعة · Verses: 11 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
ٱلۡقَارِعَةُ
Àkókò ìjáyà. -
2
مَا ٱلۡقَارِعَةُ
Kí ni Àkókò ìjáyà? -
3
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡقَارِعَةُ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà? -
4
يَوۡمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلۡفَرَاشِ ٱلۡمَبۡثُوثِ
(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta, -
5
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٱلۡمَنفُوشِ
àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù. -
6
فَأَمَّا مَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ
Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n, -
7
فَهُوَ فِي عِيشَةࣲ رَّاضِيَةࣲ
ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí. -
8
وَأَمَّا مَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ
Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́, -
9
فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةࣱ
Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀. -
10
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا هِيَهۡ
Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀? -
11
نَارٌ حَامِيَةُۢ
(Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an.