Surah At-Tin in Yorùbá
سورة التين · Verses: 8 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
وَٱلتِّينِ وَٱلزَّيۡتُونِ
Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn. -
2
وَطُورِ سِينِينَ
Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn. -
3
وَهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ٱلۡأَمِينِ
Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí. -
4
لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِيٓ أَحۡسَنِ تَقۡوِيمࣲ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ. -
5
ثُمَّ رَدَدۡنَٰهُ أَسۡفَلَ سَٰفِلِينَ
Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná). -
6
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فَلَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونࣲ
Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn. -
7
فَمَا يُكَذِّبُكَ بَعۡدُ بِٱلدِّينِ
Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)? -
8
أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَحۡكَمِ ٱلۡحَٰكِمِينَ
Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?