Surah Al-'Alaq in Yorùbá
سورة العلق · Verses: 19 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
ٱقۡرَأۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلَّذِي خَلَقَ
Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. -
2
خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِنۡ عَلَقٍ
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì. -
3
ٱقۡرَأۡ وَرَبُّكَ ٱلۡأَكۡرَمُ
Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ. -
4
ٱلَّذِي عَلَّمَ بِٱلۡقَلَمِ
Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn. -
5
عَلَّمَ ٱلۡإِنسَٰنَ مَا لَمۡ يَعۡلَمۡ
Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n. -
6
كَلَّآ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَيَطۡغَىٰٓ
Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà -
7
أَن رَّءَاهُ ٱسۡتَغۡنَىٰٓ
nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀. -
8
إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجۡعَىٰٓ
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá. -
9
أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يَنۡهَىٰ
Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀ -
10
عَبۡدًا إِذَا صَلَّىٰٓ
fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun! -
11
أَرَءَيۡتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلۡهُدَىٰٓ
Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām) -
12
أَوۡ أَمَرَ بِٱلتَّقۡوَىٰٓ
tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)! -
13
أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ
Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i? -
14
أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ
Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?) -
15
كَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ
Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná); -
16
نَاصِيَةࣲ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةࣲ
àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀. -
17
فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ
Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀. -
18
سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ
Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná. -
19
كَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب۩
Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu).