Surah Al-Mutaffifin in Yorùbá
سورة المطففين · Verses: 36 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
وَيۡلࣱ لِّلۡمُطَفِّفِينَ
Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù, -
2
ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ
àwọn (òǹtajà) t’ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
“Àwọn ènìyàn” ní àyè yìí dúró fún bíi “ àwọn olóko”. -
3
وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ
nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù. -
4
أَلَا يَظُنُّ أُوْلَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ
Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde -
5
لِيَوۡمٍ عَظِيمࣲ
ní Ọjọ́ ńlá kan? -
6
يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde nàró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá. -
7
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينࣲ
Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni ibi kúkú wà nínú Sijjīn. -
8
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينࣱ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Sijjīn! -
9
كِتَٰبࣱ مَّرۡقُومࣱ
Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn). -
10
وَيۡلࣱ يَوۡمَئِذࣲ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́, -
11
ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
àwọn t’ó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́. -
12
وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ
Kò sì sí ẹni t’ó ń pè é nírọ́ àfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀. -
13
إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: "Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)." -
14
كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Rárá kò rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ibi l’ó jọba lórí ọkàn wọn. -
15
كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذࣲ لَّمَحۡجُوبُونَ
Ní ti òdodo, dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn. -
16
ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm. -
17
ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: "Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè nírọ́." -
18
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ
Bẹ́ẹ̀ ni. Dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn. -
19
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ ‘illiyyūn! -
20
كِتَٰبࣱ مَّرۡقُومࣱ
Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn). -
21
يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ
Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i. -
22
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ
Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn. -
23
عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn. -
24
تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ
Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn. -
25
يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقࣲ مَّخۡتُومٍ
Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí. -
26
خِتَٰمُهُۥ مِسۡكࣱۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ
Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn. -
27
وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ
Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà). -
28
عَيۡنࣰا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ
(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu. -
29
إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ
Dájúdájú àwọn t’ó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín. -
30
وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ
Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn adẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́. -
31
وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí. -
32
وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: "Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà." -
33
وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ
Àwa kò sì rán wọn níṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn. -
34
فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ
Nítorí náà, ní òní àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín. -
35
عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn. -
36
هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ
Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?