Surah Al-Lail in Yorùbá
سورة الليل · Verses: 21 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰ
(Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú. -
2
وَٱلنَّهَارِ إِذَا تَجَلَّىٰ
Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n. -
3
وَمَا خَلَقَ ٱلذَّكَرَ وَٱلۡأُنثَىٰٓ
Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo.
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Ẹni tí Ó dá akọ àti abo. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra. -
4
إِنَّ سَعۡيَكُمۡ لَشَتَّىٰ
Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. -
5
فَأَمَّا مَنۡ أَعۡطَىٰ وَٱتَّقَىٰ
Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu), -
6
وَصَدَّقَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo, -
7
فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡيُسۡرَىٰ
A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un. -
8
وَأَمَّا مَنۢ بَخِلَ وَٱسۡتَغۡنَىٰ
Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run, -
9
وَكَذَّبَ بِٱلۡحُسۡنَىٰ
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́, -
10
فَسَنُيَسِّرُهُۥ لِلۡعُسۡرَىٰ
A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un. -
11
وَمَا يُغۡنِي عَنۡهُ مَالُهُۥٓ إِذَا تَرَدَّىٰٓ
Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná). -
12
إِنَّ عَلَيۡنَا لَلۡهُدَىٰ
Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà. -
13
وَإِنَّ لَنَا لَلۡأٓخِرَةَ وَٱلۡأُولَىٰ
Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé. -
14
فَأَنذَرۡتُكُمۡ نَارࣰا تَلَظَّىٰ
Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín. -
15
لَا يَصۡلَىٰهَآ إِلَّا ٱلۡأَشۡقَى
Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú, -
16
ٱلَّذِي كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ
ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i. -
17
وَسَيُجَنَّبُهَا ٱلۡأَتۡقَى
Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu), -
18
ٱلَّذِي يُؤۡتِي مَالَهُۥ يَتَزَكَّىٰ
ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀). -
19
وَمَا لِأَحَدٍ عِندَهُۥ مِن نِّعۡمَةࣲ تُجۡزَىٰٓ
Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni, -
20
إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ رَبِّهِ ٱلۡأَعۡلَىٰ
bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ. -
21
وَلَسَوۡفَ يَرۡضَىٰ
Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀).