Surah 'Abasa in Yorùbá
سورة عبس · Verses: 42 · Meccan
Translation: Yorùbá translation (الترجمة اليورباوية)
-
1
عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ
(Ànábì s.a.w.) fajú ro, ó sì pẹ̀yìn dà -
2
أَن جَآءَهُ ٱلۡأَعۡمَىٰ
nítorí pé afọ́jú wá bá a. -
3
وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ
Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́) -
4
أَوۡ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكۡرَىٰٓ
tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní? -
5
أَمَّا مَنِ ٱسۡتَغۡنَىٰ
Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀, -
6
فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ
òun ni ìwọ tẹ́tí sí. -
7
وَمَا عَلَيۡكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́). -
8
وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسۡعَىٰ
Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, t’ó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú), -
9
وَهُوَ يَخۡشَىٰ
tí ó sì ń páyà (Allāhu), -
10
فَأَنتَ عَنۡهُ تَلَهَّىٰ
ìwọ kò sì kọbi ara sí i. -
11
كَلَّآ إِنَّهَا تَذۡكِرَةࣱ
Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí. -
12
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀. -
13
فِي صُحُفࣲ مُّكَرَّمَةࣲ
(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé, -
14
مَّرۡفُوعَةࣲ مُّطَهَّرَةِۭ
A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́ -
15
بِأَيۡدِي سَفَرَةࣲ
ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika), -
16
كِرَامِۭ بَرَرَةࣲ
àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere. -
17
قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ
Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ! -
18
مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ
Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀? -
19
مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ
Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀. -
20
ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un. -
21
ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ
Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè. -
22
ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde. -
23
كَلَّا لَمَّا يَقۡضِ مَآ أَمَرَهُۥ
Ẹ gbọ́, ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un. -
24
فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ
Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀. -
25
أَنَّا صَبَبۡنَا ٱلۡمَآءَ صَبࣰّا
Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀. -
26
ثُمَّ شَقَقۡنَا ٱلۡأَرۡضَ شَقࣰّا
Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn. -
27
فَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا حَبࣰّا
A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀; -
28
وَعِنَبࣰا وَقَضۡبࣰا
àti èso àjàrà àti kànnáfùrù, -
29
وَزَيۡتُونࣰا وَنَخۡلࣰا
àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù, -
30
وَحَدَآئِقَ غُلۡبࣰا
àti àwọn ọgbà t’ó kún fún igi, -
31
وَفَٰكِهَةࣰ وَأَبࣰّا
àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde). -
32
مَّتَٰعࣰا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ
(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. -
33
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ
Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀, -
34
يَوۡمَ يَفِرُّ ٱلۡمَرۡءُ مِنۡ أَخِيهِ
ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀, -
35
وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ
àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀, -
36
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ
àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. -
37
لِكُلِّ ٱمۡرِيࣲٕ مِّنۡهُمۡ يَوۡمَئِذࣲ شَأۡنࣱ يُغۡنِيهِ
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn t’ó máa tó o ó rán. -
38
وُجُوهࣱ يَوۡمَئِذࣲ مُّسۡفِرَةࣱ
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀. -
39
ضَاحِكَةࣱ مُّسۡتَبۡشِرَةࣱ
Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú. -
40
وَوُجُوهࣱ يَوۡمَئِذٍ عَلَيۡهَا غَبَرَةࣱ
Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀. -
41
تَرۡهَقُهَا قَتَرَةٌ
Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. -
42
أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡكَفَرَةُ ٱلۡفَجَرَةُ
Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.