ترجمة معاني سورة البروج باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
آية رقم 1
ﭛﭜﭝ
ﭞ
(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀.
آية رقم 2
ﭟﭠ
ﭡ
Ó tún búra pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn.
آية رقم 3
ﭢﭣ
ﭤ
Ó tún búra pẹ̀lú olùjẹ́rìí àti ohun t’ó jẹ́rìí sí.
آية رقم 4
ﭥﭦﭧ
ﭨ
A ṣẹ́bi lé àwọn t’ó gbẹ́ kòtò (iná),
آية رقم 5
ﭩﭪﭫ
ﭬ
. (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
آية رقم 6
ﭭﭮﭯﭰ
ﭱ
(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
آية رقم 7
ﭲﭳﭴﭵﭶﭷ
ﭸ
Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
آية رقم 8
Kò sì sí kiní kan tí wọ́n torí rẹ̀ jẹ wọ́n níyà bí kò ṣe pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ọlọ́pẹ́,
آية رقم 9
Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
آية رقم 10
Dájúdájú àwọn t’ó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná t’ó ń jò sì wà fún wọn.
آية رقم 11
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
آية رقم 12
ﮮﮯﮰﮱ
ﯓ
Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
آية رقم 13
ﯔﯕﯖﯗ
ﯘ
Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
آية رقم 14
ﯙﯚﯛ
ﯜ
Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
آية رقم 15
ﯝﯞﯟ
ﯠ
Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ,
آية رقم 16
ﯡﯢﯣ
ﯤ
Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
آية رقم 17
ﯥﯦﯧﯨ
ﯩ
Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
آية رقم 18
ﯪﯫ
ﯬ
(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
آية رقم 19
ﯭﯮﯯﯰﯱ
ﯲ
Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo nírọ́.
آية رقم 20
ﯳﯴﯵﯶ
ﯷ
Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
آية رقم 21
ﯸﯹﯺﯻ
ﯼ
Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
آية رقم 22
ﯽﯾﯿ
ﰀ
tí ó wà nínú wàláà tí À ń ṣọ́.
تقدم القراءة