ترجمة معاني سورة التين باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
آية رقم 1
ﭫﭬ
ﭭ
Allāhu búra pẹ̀lú èso tīn àti èso zaetūn.
آية رقم 2
ﭮﭯ
ﭰ
Ó tún búra pẹ̀lú àpáta Sīnīn.
آية رقم 3
ﭱﭲﭳ
ﭴ
Ó tún búra pẹ̀lú ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí.
آية رقم 4
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
ﭻ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí t’ó dára jùlọ.
آية رقم 5
ﭼﭽﭾﭿ
ﮀ
Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
آية رقم 6
Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
آية رقم 7
ﮋﮌﮍﮎ
ﮏ
Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
آية رقم 8
ﮐﮑﮒﮓ
ﮔ
Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?
تقدم القراءة