ترجمة معاني سورة الحجر باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
آية رقم 1
’Alif lām rọ̄. Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà àti (àwọn āyah) al-Ƙur’ān t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
آية رقم 2
Ó ṣeé ṣe kí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nífẹ̀ẹ́ sí pé àwọn ìbá sì ti jẹ́ mùsùlùmí (nílé ayé).
آية رقم 3
Fi wọ́n sílẹ̀, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n gbádùn, kí ìrètí (ẹ̀mí gígùn) kó àìrójú ráàyè bá wọn (láti ṣẹ̀sìn); láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
آية رقم 4
A kò pa ìlú kan run rí àfi kí ó ní àkọsílẹ̀ tí A ti mọ̀.
آية رقم 5
Kò sí ìjọ kan (tí ó parun) ṣíwájú àkókò rẹ̀ (nínú Laohul-Mahfuuṭḥ); wọn kò sì níí sún un ṣíwájú fún wọn.
آية رقم 6
Wọ́n wí pé: “Ìwọ tí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún, dájúdájú wèrè ni ẹ́.
آية رقم 7
Kí ni kò jẹ́ kí ìwọ mú àwọn mọlāika wá bá wa, tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo?”
آية رقم 8
A ò níí sọ mọlāika kalẹ̀ bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Wọn kò sì níí lọ́ wọn lára mọ́ nígbà náà (tí àwọn mọlāika bá sọ̀kalẹ̀).
آية رقم 9
Dájúdájú Àwa l’A sọ Tírà Ìrántí kalẹ̀ (ìyẹn al-Ƙur’ān). Dájúdájú Àwa sì ni Olùṣọ́ rẹ̀.
آية رقم 10
Dájúdájú ṣíwájú rẹ A ti rán (àwọn Òjíṣẹ́) níṣẹ́ sí àwọn ìjọ, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
آية رقم 11
Òjíṣẹ́ kan kò sì níí dé bá wọn àfi kí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́.
آية رقم 12
ﮰﮱﯓﯔﯕ
ﯖ
Báyẹn ni A ṣe ń fi (àìsàn) sínú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
آية رقم 13
Wọn kò níí gba Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbọ́; ìṣe (Allāhu lórí) àwọn ẹni àkọ́kọ́ kúkú ti ré kọjá.
Ìṣe Allāhu lórí ẹ̀dá lásìkò ìparun nílé ayé ni pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) máa ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là, Ó sì máa ń pa àwọn aláìgbàgbọ́ run gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Ànábì Nūh, ìjọ Ànábì Lūt àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
آية رقم 14
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣí ìlẹ̀kùn kan sílẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀, tí wọn kò sì yé gbabẹ̀ gùnkè lọ (sínú sánmọ̀),
آية رقم 15
dájúdájú wọ́n á wí pé: “Wọ́n kúkú lo ìṣíjú fún wa ni. Ńṣe ni wọ́n ń dan wá.”
آية رقم 16
A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ (ìràwọ̀) sínú sánmọ̀ (ayé). A sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.
آية رقم 17
ﭙﭚﭛﭜﭝ
ﭞ
A sì fi ààbò bo ìmísí sánmọ̀ lọ́dọ̀ gbogbo èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
آية رقم 18
Àfi (èṣù) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn.
آية رقم 19
Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀.
آية رقم 20
A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún.
آية رقم 21
Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀.
آية رقم 22
Àti pé A rán atẹ́gùn láti kó ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fun yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀).
آية رقم 23
ﮕﮖﮗﮘﮙﮚ
ﮛ
Dájúdájú Àwa, Àwa mà l’À ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá).
آية رقم 24
Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn.
آية رقم 25
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
آية رقم 26
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà.
آية رقم 27
Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín.
آية رقم 28
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà.
آية رقم 29
Nígbà tí Mo bá ṣe é t’ó gún régé tán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni."
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
آية رقم 30
ﯶﯷﯸﯹ
ﯺ
Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i.
آية رقم 31
Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ náà.
آية رقم 32
(Allāhu) sọ pé: "’Iblīs, kí l’ó dí ọ lọ́wọ́ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀?"
آية رقم 33
Ó wí pé: "Èmi kò níí forí kanlẹ̀ kí abara kan tí O ṣẹ̀dá rẹ̀ láti ara amọ̀ t’ó ń dún koko, t’ó ti pàwọ̀dà."
آية رقم 34
ﭦﭧﭨﭩﭪ
ﭫ
(Allāhu) sọ pé: "Nítorí náà, jáde kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú, ìwọ ni ẹni-ẹ̀kọ̀.
آية رقم 35
ﭬﭭﭮﭯﭰﭱ
ﭲ
Àti pé, dájúdájú ègún ń bẹ lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san."
آية رقم 36
ﭳﭴﭵﭶﭷﭸ
ﭹ
Ó wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde.”
آية رقم 37
ﭺﭻﭼﭽ
ﭾ
(Allāhu) sọ pé: "Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn tí A óò lọ́ lára
آية رقم 38
ﭿﮀﮁﮂ
ﮃ
títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ."
آية رقم 39
Ó wí pé: "Olúwa mi, fún wí pé O ti ṣe mí ní ẹni anù, dájúdájú emí yóò ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún wọn lórí ilẹ̀. Dájúdájú èmi yó sì kó gbogbo wọn sínú anù
آية رقم 40
ﮏﮐﮑﮒ
ﮓ
àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn ẹni ẹ̀ṣà nínú wọn."
آية رقم 41
ﮔﮕﮖﮗﮘ
ﮙ
(Allāhu) sọ pé: "(Ìdúróṣinṣin lójú) ọ̀nà tààrà, Ọwọ́ Mi ni èyí wà."
آية رقم 42
Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn, àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú àwọn ẹni anù.
آية رقم 43
ﮦﮧﮨﮩ
ﮪ
Àti pé dájúdájú iná Jahanamọ ni àdéhùn fún gbogbo wọn.
آية رقم 44
Àwọn ojú ọ̀nà méje ń bẹ fún (iná). Àtúnpín tún wà fún ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
آية رقم 45
ﯕﯖﯗﯘﯙ
ﯚ
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) máa wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn nísàlẹ̀ rẹ̀).
آية رقم 46
ﯛﯜﯝ
ﯞ
(A máa sọ pé): “Ẹ wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ní olùfàyàbalẹ̀.”
آية رقم 47
A sì máa yọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn t’ó jẹ́ inúnibíni kúrò; (wọn yóò di) ọmọ-ìyá (ara wọn. Wọn yóò wà) lórí ibùsùn, tí wọn yóò kọjú síra wọn.
آية رقم 48
Wàhálà kan kò níí bá wọn nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀.
آية رقم 49
Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
آية رقم 50
ﯻﯼﯽﯾﯿ
ﰀ
Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
آية رقم 51
ﰁﰂﰃﰄ
ﰅ
Fún wọn ní ìró nípa àlejò (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
آية رقم 52
(Rántí) nígbà tí wọ́n wọlé tọ̀ ọ́, wọ́n sì sọ pé: “Àlàáfíà”. Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀rù yín ń ba àwa.”
آية رقم 53
Wọ́n sọ pé: "Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwa yóò fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin onímímọ̀ kan."
آية رقم 54
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀ ń fún mi ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí ọmọ) nígbà tí ogbó ti dé sí mi? Ìró ìdùnnú wo ni ẹ̀ ń fún mi ná?"
آية رقم 55
Wọ́n sọ pé: “À ń fún ọ ní ìró ìdùnnú pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, má ṣe wà lára àwọn olùjákànmùná.”
آية رقم 56
Ó sọ pé: “Kò mà sí ẹni tí ó máa jákànmùná nínú ìkẹ́ Olúwa Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùṣìnà.”
آية رقم 57
ﭽﭾﭿﮀﮁ
ﮂ
Ó sọ pé: “Kí tún ni ọ̀rọ̀ tí ẹ bá wá, ẹ̀yin Òjíṣẹ́?”
آية رقم 58
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
ﮉ
Wọ́n sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n rán wa níṣẹ́ sí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.
آية رقم 59
ﮊﮋﮌﮍﮎﮏ
ﮐ
Àfi ará ilé (Ànábì) Lūt. Dájúdájú àwa yóò gba wọn là pátápátá.
آية رقم 60
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
ﮗ
Àfi ìyàwó rẹ̀; A ti kọ kádàrá rẹ̀ (pé) dájúdájú ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun."
آية رقم 61
ﮘﮙﮚﮛﮜ
ﮝ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ ará ilé (Ànábì) Lūt,
آية رقم 62
ﮞﮟﮠﮡ
ﮢ
(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ àjòjì ènìyàn.”
آية رقم 63
Wọ́n sọ pé: “Rárá, a wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ohun tí wọ́n ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀.
آية رقم 64
ﮫﮬﮭﮮ
ﮯ
A mú òdodo wá bá ọ ni. Àti pé dájúdájú olódodo ni àwa.
آية رقم 65
Nítorí náà, mú ará ilé rẹ jáde ní apá kan òru. Kí o sì tẹ̀lé wọn lẹ́yìn. Ẹnì kan nínú yín kò sì gbọdọ̀ ṣíjú wo ẹ̀yìn wò. Kí ẹ sì lọ sí àyè tí wọ́n ń pa láṣẹ fun yín."
آية رقم 66
A sì jẹ́ kí ìdájọ́ ọ̀rọ̀ yìí hàn sí i pé dájúdájú A máa pa àwọn (ẹlẹ́ṣẹ̀) wọ̀nyí run pátápátá nígbà tí wọ́n bá mọ́júmọ́.
آية رقم 67
ﯪﯫﯬﯭ
ﯮ
Àwọn ará ìlú náà dé, wọ́n sì ń yọ̀ sẹ̀sẹ̀.
آية رقم 68
ﯯﯰﯱﯲﯳﯴ
ﯵ
(Ànábì Lūt) sọ pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni àlejò mi. Nítorí náà, ẹ má ṣe dójú tì mí.
آية رقم 69
ﯶﯷﯸﯹ
ﯺ
Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe yẹpẹrẹ mi."
آية رقم 70
ﯻﯼﯽﯾﯿ
ﰀ
Wọ́n wí pé: “Ǹjẹ́ àwa kò ti kọ̀ fún ọ (nípa gbígba àlejò) àwọn ẹ̀dá?”
آية رقم 71
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”
آية رقم 72
ﭘﭙﭚﭛﭜ
ﭝ
(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra; dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìdààmú ọpọlọ, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.”
آية رقم 73
ﭞﭟﭠ
ﭡ
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn.
آية رقم 74
A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí.
آية رقم 75
ﭫﭬﭭﭮﭯ
ﭰ
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye.
آية رقم 76
ﭱﭲﭳ
ﭴ
Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
آية رقم 77
ﭵﭶﭷﭸﭹ
ﭺ
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
آية رقم 78
ﭻﭼﭽﭾﭿ
ﮀ
Àwọn ará ’Aekah náà jẹ́ alábòsí.
’Aekah tún túmọ̀ sí igbó. Ìyẹn ni pé, ìlú tí ó wà nínú igbó. Ará ’Aekah ni ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām).
آية رقم 79
ﮁﮂﮃﮄﮅ
ﮆ
A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì l’ó kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀).
آية رقم 80
ﮇﮈﮉﮊﮋ
ﮌ
Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
آية رقم 81
ﮍﮎﮏﮐﮑ
ﮒ
A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀.
آية رقم 82
ﮓﮔﮕﮖﮗﮘ
ﮙ
Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta.
آية رقم 83
ﮚﮛﮜ
ﮝ
Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́.
آية رقم 84
ﮞﮟﮠﮡﮢﮣ
ﮤ
Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
آية رقم 85
A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò t’ó rẹwà.
آية رقم 86
ﯗﯘﯙﯚﯛ
ﯜ
Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀.
آية رقم 87
Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān t’ó tóbi.
آية رقم 88
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé lóríṣiríṣi fún àwọn kan nínú wọn. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
آية رقم 89
ﯵﯶﯷﯸﯹ
ﯺ
Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
آية رقم 90
ﯻﯼﯽﯾ
ﯿ
Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn t’ó ń pín òdodo mọ́ irọ́;
Pípín òdodo mọ́ irọ́ ni pípín al-Ƙur’ān mọ́ orin, idán, ìdábigba, àlá lílá àti ààlọ́.
آية رقم 91
ﭑﭒﭓﭔ
ﭕ
àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,
آية رقم 92
ﭖﭗﭘ
ﭙ
Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè
آية رقم 93
ﭚﭛﭜ
ﭝ
nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
آية رقم 94
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
ﭤ
Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.
آية رقم 95
ﭥﭦﭧ
ﭨ
Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́,
آية رقم 96
àwọn t’ó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
آية رقم 97
Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ.
آية رقم 98
ﭻﭼﭽﭾﭿﮀ
ﮁ
Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ. Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un).
آية رقم 99
ﮂﮃﮄﮅﮆ
ﮇ
Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ.
تقدم القراءة