سورة الإنشقاق

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني سورة الإنشقاق باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

آية رقم 1
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
آية رقم 2
- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ –
آية رقم 3
àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
آية رقم 4
ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
آية رقم 5
– ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ – (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
آية رقم 6
Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
آية رقم 7
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
آية رقم 8
láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
آية رقم 9
Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
آية رقم 10
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hāƙƙọh; 69:25.
آية رقم 11
láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
آية رقم 12
Ó sì máa wọ inú Iná t’ó ń jò fòfò.
آية رقم 13
Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
آية رقم 14
Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
آية رقم 15
Rárá (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
آية رقم 16
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwòǹpapa.
آية رقم 17
Mo tún búra pẹ̀lú òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀.
آية رقم 18
Mo tún búra pẹ̀lú òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀).
آية رقم 19
Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
آية رقم 20
Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
آية رقم 21
Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
آية رقم 22
Rárá, ńṣe ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é nírọ́.
آية رقم 23
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
آية رقم 24
Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Àyàfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin ń bẹ fún wọn.
تقدم القراءة