ترجمة معاني سورة القمر باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
آية رقم 1
ﮬﮭﮮﮯ
ﮰ
Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).
آية رقم 2
Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: "Idán kan (t’ó lágbára) t’ó máa lọ ni."
آية رقم 3
Wọ́n pè é nírọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn.
آية رقم 4
Dájúdájú èyí tí wọ́n fi ohùn líle kọ̀ wà nínú àwọn ìró t’ó dé bá wọn.
آية رقم 5
ﯪﯫﯬﯭﯮﯯ
ﯰ
Ìjìnlẹ̀ òye t’ó péye ni; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
آية رقم 6
Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
آية رقم 7
Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
آية رقم 8
Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Èyí ni ọjọ́ ìṣòro."
آية رقم 9
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: "Wèrè ni." Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Gbólóhùn ìparí āyah yìí ń sọ pé, ‘ìjọ Nūh lé Nūh jáde kúrò nínú ìlú’. Àmọ́ sūrah Hūd; 11:38 ń sọ pé, ‘Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.” Wọ́n ní, “Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ Nūh tí wọ́n ti lé jáde kúrò nínú ìlú ni ẹni tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́!”
Èsì: Kò sí ìtakora kan nínú rẹ̀. Al-Ƙur’ān kò fi rinlẹ̀ níbì kan kan pé, ìjọ Nūh lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) jáde kúrò nínú ìlú. Ìpìlẹ̀ “wa-zdujir” ni “zajara” láti ara “zajr” – kíkọ n̄ǹkan àti híhánnà n̄ǹkan pẹ̀lú ohùn líle. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran. Ìtúmọ̀ “wa-zdujir” yìí ni Allāhu ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:116 pé wọ́n ń fi lílẹ̀ lókò halẹ̀ mọ́ ọn. Ìtúmọ̀ kíkọ̀ náà ni ìtúmọ̀ t’ó jẹyọ nínú “muzdajar” t’ó parí āyah 4 ṣíwájú. Ìtúmọ̀ àkànlò fún “zajr” sì jẹyọ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:2. Kókó ọ̀rọ̀ ni pé, ìjọ Nūh fi ohùn líle kọ ọ̀rọ̀ sí Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lẹ́nu ni, kì í ṣe pé wọ́n lé e jáde kúrò nínú ìlú. Wọ́n kọ ìtẹ̀lé Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) sílẹ̀ pẹ̀lú sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i. Àmọ́ Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nínú ìlú pẹ̀lú wọn títí ó fi kan ọkọ̀ ojú omi. W-Allāhu ’a‘lam.

آية رقم 10
ﭯﭰﭱﭲﭳ
ﭴ
Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: "Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Ràn mí lọ́wọ́."
آية رقم 11
ﭵﭶﭷﭸﭹ
ﭺ
Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi t’ó lágbára.
آية رقم 12
A tún mú àwọn odò ṣẹyọ lórí ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
آية رقم 13
ﮅﮆﮇﮈﮉ
ﮊ
A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
آية رقم 14
ﮋﮌﮍﮎﮏﮐ
ﮑ
t’ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san fún ẹni tí wọ́n takò.
آية رقم 15
ﮒﮓﮔﮕﮖﮗ
ﮘ
Dájúdájú A fi sílẹ̀ ní àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 16
ﮙﮚﮛﮜ
ﮝ
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
آية رقم 17
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 18
ﮦﮧﮨﮩﮪﮫ
ﮬ
Ìran ‘Ād pé òdodo nírọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
آية رقم 19
Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan t’ó ń tẹ̀ síwájú.
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Fussilat; 41:16.
آية رقم 20
ﯘﯙﯚﯛﯜﯝ
ﯞ
Ó ń fa àwọn ènìyàn jáde bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
آية رقم 21
ﯟﯠﯡﯢ
ﯣ
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
آية رقم 22
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 23
ﯬﯭﯮ
ﯯ
Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́.
آية رقم 24
Wọ́n wí pé: "Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti ìyà.
آية رقم 25
Ṣé òun ni wọ́n sọ ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni."
آية رقم 26
ﰅﰆﰇﰈﰉ
ﰊ
Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
آية رقم 27
Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.
آية رقم 28
Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
آية رقم 29
ﭛﭜﭝﭞ
ﭟ
Nígbà náà ni wọ́n pe ẹni wọn. Ó wá ọ̀nà láti mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
آية رقم 30
ﭠﭡﭢﭣ
ﭤ
Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
آية رقم 31
Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí igi koríko gbígbẹ.
آية رقم 32
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 33
ﭶﭷﭸﭹ
ﭺ
Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ nírọ́.
آية رقم 34
Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
آية رقم 35
(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni t’ó bá dúpẹ́ (fún Wa).
آية رقم 36
ﮏﮐﮑﮒﮓ
ﮔ
Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
آية رقم 37
Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
آية رقم 38
ﮟﮠﮡﮢﮣ
ﮤ
Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
آية رقم 39
ﮥﮦﮧ
ﮨ
Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
آية رقم 40
Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 41
ﮱﯓﯔﯕﯖ
ﯗ
Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
آية رقم 42
Wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́, gbogbo rẹ̀ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (ń gbá ẹ̀dá mú).
آية رقم 43
Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore jùlọ sí àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
آية رقم 44
ﯫﯬﯭﯮﯯ
ﯰ
Tàbí wọ́n ń wí pé: "Gbogbo wa ni a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)"
آية رقم 45
ﯱﯲﯳﯴ
ﯵ
A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
آية رقم 46
ﯶﯷﯸﯹﯺﯻ
ﯼ
Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
آية رقم 47
ﯽﯾﯿﰀﰁ
ﰂ
Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà (nílé ayé, wọn yó sì wà nínú) Iná jíjò (ní ọ̀run).
آية رقم 48
Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn délẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
آية رقم 49
ﰍﰎﰏﰐﰑ
ﰒ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
آية رقم 50
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.
Ìyẹn ni pé, a máa lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún nínú sàréè, àmọ́ láààrin ká ṣẹ́jú ká lajú, gbogbo ẹ̀dá máa jí dìde láti inú sàréè wọn.
آية رقم 51
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
ﭞ
Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
آية رقم 52
ﭟﭠﭡﭢﭣ
ﭤ
Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
آية رقم 53
ﭥﭦﭧﭨ
ﭩ
Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
آية رقم 54
ﭪﭫﭬﭭﭮ
ﭯ
Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (t’ó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
آية رقم 55
ﭰﭱﭲﭳﭴﭵ
ﭶ
Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá.
تقدم القراءة