سورة الرحمن

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني سورة الرحمن باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

الترجمة اليورباوية

أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني

آية رقم 1
Àjọkẹ́-ayé,
آية رقم 2
Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
آية رقم 3
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.
آية رقم 4
Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
آية رقم 5
Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
آية رقم 6
Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
آية رقم 7
Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)
آية رقم 8
pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà níbi òṣùwọ̀n.
آية رقم 9
Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.
آية رقم 10
Ilẹ̀, (Allāhu) tẹ́ ẹ sílẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá.
آية رقم 12
Àti èso kóró onípòpórò àti eléwé dúdú (wà lórí ilẹ̀).
آية رقم 13
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 14
(Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ t’ó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.
آية رقم 15
Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.
آية رقم 16
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 17
Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mọ‘ārij; 70:40.
آية رقم 18
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 19
(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.
آية رقم 20
Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-àlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).
آية رقم 21
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 22
Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.
آية رقم 23
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 24
Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro t’ó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.
آية رقم 25
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 26
Gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ máa tán.
آية رقم 27
Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.
آية رقم 28
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
Àwọn t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.
آية رقم 30
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 31
A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.
آية رقم 32
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ ò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.
آية رقم 34
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 35
Wọ́n máa ju ẹ̀ta-pàrà iná àti ẹ̀ta-pàrà idẹ lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì lè ran’ra yín lọ́wọ́.
آية رقم 36
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 37
Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa.
آية رقم 38
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 39
Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn ò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).
آية رقم 40
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 41
Wọ́n máa mọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.
آية رقم 42
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 43
Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè nírọ́.
آية رقم 44
Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi t’ó gbóná parí.
Ìyẹn ni pé, nínú Iná, yàtọ̀ sí pé oríṣiríṣi omi burúkú l’ó wà nínú rẹ̀ bíi omi t’ó gbóná parí, omi rẹ́funrẹ́fun, omi ètútú, omi àwọnúwẹ̀jẹ̀, àwọn omi wọ̀nyí máa wà nínú ọ̀gbun kan fún àwọn ọmọ Iná nínú Iná, bí Iná bá ti ń jó wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á lọ máa mu omi ìmukúmu wọ̀nyí sí i, wọ́n á tún padà síbi Iná, wọ́n á tún padà síbi omi, wọ́n á tún padà síbi Ina. Wọ́n á wà bẹ́ẹ̀ títí láéláé.
آية رقم 45
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 46
Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni t’ó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.
آية رقم 47
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 48
(Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi gígùn.
آية رقم 49
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 50
Odò méjì t’ó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
آية رقم 51
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 52
Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan t’ó wà nínú ọgbà méjèèjì.
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Yāsīn; 36:36.
آية رقم 53
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán t’ó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.
آية رقم 55
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
آية رقم 57
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 58
Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn.
آية رقم 59
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 60
Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.
آية رقم 61
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 62
Ọgbà méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).
آية رقم 63
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 64
Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).
آية رقم 65
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 66
Àwọn odò méjì t’ó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).
آية رقم 67
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 68
Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì.
آية رقم 69
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 70
Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
آية رقم 71
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 72
Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.
آية رقم 73
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 74
Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
آية رقم 75
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 76
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ t’ó dára.
آية رقم 77
Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè nírọ́?
آية رقم 78
Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.
تقدم القراءة