ترجمة معاني سورة الجن باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
آية رقم 1
Sọ pé: "Wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé dájúdájú ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú tẹ́tí (sí al-Ƙur’ān)." Wọ́n sì sọ pé: "Dájúdájú àwa gbọ́ al-Ƙur’ān ìyanu.
آية رقم 2
Ó ń ṣètọ́sọ́nà síbi ìmọ̀nà. Nítorí náà, a gbà á gbọ́. Àwa kò sì níí fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa wa.
آية رقم 3
Àti pé dájúdájú títóbi Olúwa wa ga. Kò fi ẹnì kan kan ṣe aya àti ọmọ.
آية رقم 4
Dájúdájú òmùgọ̀ nínú wa máa ń sọ ìsọkúsọ nípa Allāhu.
آية رقم 5
Dájúdájú àwa sì ń rò pé ènìyàn àti àlùjànnú kò níí pa irọ́ mọ́ Allāhu ni.
آية رقم 6
Àti pé dájúdájú àwọn ọkùnrin kan nínú ènìyàn máa ń fi àwọn ọkùnrin kan nínú àwọn àlùjànnú wá ààbò. Àwọn àlùjànnú sì ṣe àlékún aburú fún wọn.
آية رقم 7
Dájúdájú àwọn àlùjànnú lérò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ènìyàn náà ṣe lérò pé Allāhu kò níí gbé ẹnì kan kan dìde (lẹ́yìn ikú).
آية رقم 8
Dájúdájú àwa wá (ọ̀rọ̀ àyọ́gbọ́) wá sí sánmọ̀, a sì bá a tí ó ti kún fún àwọn ẹ̀ṣọ́ t’ó lágbára àti àwọn ògúnná.
آية رقم 9
Dájúdájú àwa máa ń jókòó síbẹ̀ ní àwọn ibùdó kan fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni t’ó bá jọ́rọ̀ gbọ́ lásìkò yìí, ó máa rí ògúnná t’ó ti lúgọ dè é.
آية رقم 10
Dájúdájú àwa kò sì mọ̀ bóyá aburú ni wọ́n gbà lérò pẹ̀lú àwọn t’ó wà lórí ilẹ̀ tàbí Olúwa wọn gbèrò ìmọ̀nà fún wọn.
آية رقم 11
Dájúdájú àwọn ẹni rere wà nínú wa. Àwọn mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn tún wà nínú wa. A wà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
آية رقم 12
Dájúdájú àwa mọ àmọ̀dájú pé àwa kò lè mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Àwa kò sì lè sá mọ́ Ọn lọ́wọ́.
آية رقم 13
Dájúdájú nígbà tí a gbọ́ nípa ìmọ̀nà (láti inú al-Ƙur’ān), a gbà á gbọ́. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Olúwa rẹ̀ gbọ́, kí ó má bẹ̀rù àdínkù (ẹ̀san rere) àti (àlékún) aburú.
Ìyẹn ni pé, wọn kò níí dín ẹ̀san iṣẹ́ rere onígbàgbọ́ òdodo kù, wọn kò sì níí fi kún àṣìṣe rẹ̀. Àti pé, àforíjìn Allāhu súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí lórí àwọn àṣìṣe náà.
آية رقم 14
Dájúdájú àwọn mùsùlùmí wà nínú wa. Àwọn arúfin náà wà nínú wa. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ’Islām, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ṣe àwárí ìmọ̀nà."
آية رقم 15
ﭝﭞﭟﭠﭡ
ﭢ
Ní ti àwọn arúfin, àwọn ni wọ́n máa jẹ́ igi ìkoná fún iná Jahanamọ.”
آية رقم 16
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n dúró ṣinṣin lójú ọ̀nà (’Islām) ni, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní omi púpọ̀ mu.
آية رقم 17
Nítorí kí Á lè fi dán wọn wò ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Olúwa rẹ̀, Ó máa mú un wọ inú ìyà ìnira.
آية رقم 18
Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.
Nínú ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí kalmọh “mọsājid” dúró fún àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ni iwájú orí àti góńgórí imú, àtẹ́lẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì àti orí ọmọníkasẹ̀ méjéèjì. Èèwọ̀ ni fún ẹ̀dá lati fi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ wọ̀nyí jọ́sìn tàbí kí ẹnikẹ́ni. Sa‘īd ọmọ Jubaer sọ pé, “Wọ́n sọ āyah yìí kalẹ̀ nípa àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni pé, dájúdájú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ń jẹ́ ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ má lò wọ́n láti fi jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Allāhu.” (Tafsīr Ibn Kathīr) Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
آية رقم 19
Dájúdájú nígbà tí ẹrúsìn Allāhu dìde dúró t’ó ń pe Allāhu, àwọn àlùjànnú fẹ́ẹ̀ máa dìfún-ùn-ùnfún lọ́dọ̀ rẹ̀ (láti tẹ́tí sí al-Ƙur’ān).
آية رقم 20
Sọ pé: "Olúwa mi ni mò ń pè. Àti pé èmi kò níí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Un."
آية رقم 21
Sọ pé: "Dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ìnira àti ìmọ̀nà fun yín."
آية رقم 22
Sọ pé: "Dájúdájú èmi, kò sí ẹnì kan t’ó lè gbà mí là lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì rí ibùsásí kan lẹ́yìn Rẹ̀.
آية رقم 23
Àfi (kí n̄g ṣe) ìkédé (t’ó wá) láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ (t’Ó fi rán mi). Ẹnikẹ́ni t’ó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ń bẹ fún un. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé.
آية رقم 24
(Aláìgbàgbọ́ kò níí yé ṣàì gbàgbọ́) títí di ìgbà tí wọ́n yóò fi rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. Nígbà náà, wọn yóò mọ ta ni ó lẹ jùlọ ní alárànṣe, tí ó sì kéré jùlọ ní òǹkà.
آية رقم 25
Sọ pé: "Èmi kò mọ̀ bóyá ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín ti súnmọ́ tàbí Olúwa mi yóò fún un ní àkókò (t’ó jìnnà).
آية رقم 26
Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, kò sì fi (ìmọ̀) ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ han ẹnì kan
آية رقم 27
àyàfi ẹni tí Ó ṣàlẹ́ṣà t’ó jẹ́ Òjísẹ́. Dájúdájú Ó ń mú ẹ̀ṣọ́ kan rìn níwájú Òjíṣẹ́ náà àti lẹ́yìn rẹ̀
Kíyè sí i, nígbà tí a bá sọ fún àáfà t’ó ń woṣẹ́ pé, “kò lè rí ìkọ̀kọ̀ kan kan wò nínú ohun t’ó pamọ́ fún ẹ̀dá.” Ó máa sọ pé, “ṣebí òjíṣẹ́ ni òun. Òun lè rí ìkọ̀kọ̀ nígbà náà.” Ẹ má ṣe jẹ́ kí ó tàn yín jẹ. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì àti òpin àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sí àáfà kan kan tí Allāhu ń fi iṣẹ́ ìmísí rán mọ́. Èṣù àlùjànnú ni àwọn àáfà t’ó ń woṣẹ́ bá dòwò pọ̀. Òjíṣẹ́ àlùjànnú ni irú wọn, wọn kì í ṣe “òjíṣẹ́ Ọlọ́hun”.
آية رقم 28
nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn pé wọ́n ti jẹ́ àwọn iṣẹ́ Olúwa wọn. Àti pé Allāhu fi ìmọ̀ rọkiri ká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn. Ó sì ṣọ́ òǹkà gbogbo n̄ǹkan.
تقدم القراءة