ترجمة معاني سورة المؤمنون باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè.
Àwọn t’ó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn,
àti àwọn t’ó ń ṣẹ́rí kúrò níbi ìsọkúsọ,
àti àwọn t’ó ń yọ Zakāh,
àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
àfi ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó wọn àti ẹrúbìnrin wọn. Dájúdájú wọn kì í ṣe ẹni èébú (tí wọ́n bá súnmọ́ wọn),
nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá wá òmíràn (súnmọ́) lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ ẹnu-àlà,
____________________
Lára wíwá òmíràn súnmọ́ yàtọ̀ sí ìyàwó àti ẹrúbìnrin ni sísúnmọ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ’Islām ṣe ní èèwọ̀ fúnni láti fẹ́ (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ní sūrah an-Nisā’; 4: 22-24), sísúnmọ́ ẹranko, ìbásùn láààrin ọkùnrin méjì, ìbásùn láààrin obìnrin méjì, fífí ọwọ́ fa àtọ̀-ẹni jáde. Kíyè sí i, ọ̀tọ̀ ni ẹrú, ọ̀tọ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀. Ẹrúbìnrin ni olówó-ẹrú lè fi tura, kì í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀.
àti àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn,
àti àwọn t’ó ń ṣọ́ ìrun wọn;
àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùjogún,
àwọn t’ó máa jogún ọgbà ìdẹ̀ra Firdaos. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Dájúdájú A ti ṣe ẹ̀dá ènìyàn láti inú ohun tí A mọ jáde láti inú erùpẹ̀ amọ̀.
Lẹ́yìn náà, A ṣe é ní àtọ̀ sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ).
Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.1 Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà).2
____________________
1. Ìyẹn ni pé, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn tí ó ní ẹ̀mí, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà sókè bẹ̀rẹ̀ láti òpóǹló títí di ọjọ́ ikú. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìyẹn, dájúdájú ẹ̀yin yó sì di òkú.
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní Ọjọ́ Àjíǹde Wọ́n máa gbe yín dìde.
Dájúdájú A dá àwọn sánmọ̀ méje sí òkè yín. Àwa kò sì níí dágunlá sí àwọn ẹ̀dá.
À ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n níwọ̀n. Lẹ́yìn náà, À ń mú un dúró sínú ilẹ̀. Dájúdájú Àwa kúkú lágbára láti mú un lọ.
Lẹ́yìn náà, A dá àwọn ọgbà oko dàbínù àti àjàrà fun yín; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso wà nínú rẹ̀ fun yín, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
Àti igi kan t’ó ń hù jáde níbi àpáta Sīnā’; ó ń mú epo àti n̄ǹkan ìṣebẹ̀ jáde fún àwọn t’ó ń jẹ ẹ́.
Àti pé dájúdájú àríwòye wà fun yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn; À ń fun yín mu nínú ohun tí ó wà nínú ikùn wọn. Àwọn àǹfààní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (mìíràn) tún wà fun yín lára wọn, ẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.
Ẹ sì ń kó ẹrù sí orí àwọn ẹran ọ̀sìn àti ọkọ̀ ojú-omi.
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Àwọn olórí tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín, tí ó fẹ́ gbé àjùlọ fún ara rẹ̀ lórí yín. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ránṣẹ́ sí wa ni), ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ ni. A kò sì gbọ́ èyí rí lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí (ìkángun) rẹ̀ títí di ìgbà kan ná.”
(Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."
Nítorí náà, A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Ṣe ọkọ̀ ojú-omi ní ojú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Nígbà tí àṣẹ Wa bá dé, tí omi bá ṣẹ́ yọ ní ojú àrò, nígbà náà ni kí o kó sínú ọkọ̀ ojú-omi gbogbo n̄ǹkan ní oríṣi méjì takọ-tabo àti ará ilé rẹ, àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà kò lé lórí nínú wọn (fún ìparun). Má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn t’ó ṣàbòsí; dájúdájú A óò tẹ̀ wọ́n rì sínú omi ni.
Nígbà tí o bá jókòó sínú ọkọ̀ ojú-omi náà, ìwọ àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ, sọ pé: 'Ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ẹni tí Ó gbà wá là lọ́wọ́ ijọ alábòsí.'"
Sọ pé: “Olúwa mi, sọ̀ mí kalẹ̀ sí ibùsọ̀ ìbùkún. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn amúnigúnlẹ̀.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọffāt; 37:125.
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Àwa sì ni À ń dán ẹ̀dá wò.
Lẹ́yìn náà, A mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
A tún rán Òjíṣẹ́ kan sí wọn láààrin ara wọn (láti jíṣẹ́) pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ ò ní ọlọ́hun mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Àwọn olórí t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀, àwọn t’ó pe ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn nírọ́, àwọn tí A ṣe gbẹdẹmukẹ fún nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, wọ́n wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe abara kan bí irú yín; ó ń jẹ nínú ohun tí ẹ̀ ń jẹ, ó sì ń mu nínú ohun tí ẹ̀ ń mu.
Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé abara kan bí irú yín, dájúdájú ẹ mà ti di ẹni òfò nìyẹn.
Ṣé ó ń ṣe àdéhùn fun yín pé nígbà tí ẹ bá kú, tí ẹ sì di erùpẹ̀ àti egungun tán, dájúdájú Wọn yóò mu yín jáde (ní alààyè)?
Ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fun yín (yìí) jìnnà tefétefé (sí òdodo).
Kò sí ìṣẹ̀mí ayé kan mọ́ àyàfi èyí tí à ń lò yìí; àwa kan ń kú, àwa kan ń wáyé. Kò sì sí pé Wọn yóò gbé wa dìde mọ́.
(Òjíṣẹ́ náà) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Àwa kò sì níí gbà á gbọ́."
(Òjíṣẹ́ náà) sọ pé: "Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mi nítorí pé wọ́n pè mí ní òpùrọ́."
(Allāhu) sọ pé: “Láìpẹ́ ńṣe ni wọn yóò di alábàámọ̀.”
Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn lọ́nà ẹ̀tọ́. A sì sọ wọ́n di pàǹtí. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ alábòsí.
Lẹ́yìn náà, A tún mú àwọn ìran mìíràn wá lẹ́yìn wọn.
Ìjọ kan kò níí lọ ṣíwájú àkókò (ìparun) rẹ̀, wọn kò sì níí sún (ìparun wọn) síwájú.
Lẹ́yìn náà, A rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Ìgbàkígbà tí Òjíṣẹ́ ìjọ kan bá dé, wọ́n ń pè é ní òpùrọ́. A sì mú apá kan wọn tẹ̀lé apá kan nínú ìparun. A tún sọ wọ́n di ìtàn. Nítorí náà, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ wà fún ìjọ tí kò gbàgbọ́ lódodo.
Lẹ́yìn náà, A rán (Ànábì) Mūsā àti ọmọ-ìyá rẹ̀ (Ànábì) Hārūn níṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé.
(A rán wọn níṣẹ́) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣègbéraga, wọ́n sì jẹ́ ìjọ olùjẹgàba.
Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gba abara méjì bí irú wa gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹrú wa ni àwọn ènìyàn wọn?”
Nítorí náà, wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. Wọ́n sì wà nínú àwọn ẹni- ìparun.
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.
A ṣe ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀ ní àmì kan. A sì ṣe ibùgbé fún àwọn méjèèjì sí ibi gíga kan, t’ó ní ibùgbé, t’ó sì ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Anbiyā’ 21;91
Ẹ̀yin Òjíṣẹ́, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ rere. Dájúdájú Èmi ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àti pé dájúdájú (’Islām) yìí ni ẹ̀sìn yín. (Ó jẹ́) ẹ̀sìn kan ṣoṣo. Èmi sì ni Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Mi.
Ṣùgbọ́n wọ́n gé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn láààrin ara wọn sí kélekèle. Ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń yọ̀ sí ohun t’ó ń bẹ ní ọ̀dọ̀ wọn.
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìṣìnà wọn títí di ìgbà kan ná.
Ṣé wọ́n ń lérò pé (bí) A ṣe ń fi dúkìá àti ọmọ nìkan ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn,
ni A óò ṣe máa yára ti àwọn oore sí ọ̀dọ̀ wọn lọ (títí láéláé). Rárá, wọn kò fura ni!
____________________
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èsì fún ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n lérò pé ẹni ayé bá yẹ ni ọ̀run yóò yẹ. Àmọ́ kò yé wọn pé, oore ilé ayé yìí wà ní abẹ́ oore Àjọkẹ́-ayé (ar-rahmāniyyah) fún gbogbo ẹ̀dá láì fi tẹ̀sìn ṣe.Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, oore ọ̀run wà ní abẹ́ oore Àṣàkẹ́ ọ̀run (ar-rahīmiyyah) fún ọ̀wọ́ àwa onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, oore ẹ̀dẹ tí kò lè dé ọ̀run ni oore ọwọ́ aláìgbàgbọ́ àti ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí.
Dájúdájú àwọn t’ó ń páyà (ìṣírò-iṣẹ́) fún ìpáyà wọn nínú Olúwa wọn;
àti àwọn t’ó ń gba àwọn āyah Olúwa wọn gbọ́;
àti àwọn tí kì í ṣẹbọ sí Olúwa wọn,
àti àwọn t’ó ń ṣe ohun rere (nínú iṣẹ́) tí wọ́n ṣe, pẹ̀lú ìbẹ̀rù nínú ọkàn wọn pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn;
àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n ń yára ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn sì ni aṣíwájú nínú (àwọn ẹ̀san) iṣẹ́ náà.
Àti pé A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tírà kan t’ó ń sọ òdodo (nípa iṣẹ́ ẹ̀dá) ń bẹ lọ́dọ̀ Wa. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Àmọ́ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ wà nínú ìfọ́núfọ́ra nípa (al-Ƙur’ān) yìí. Àti pé wọ́n ní àwọn iṣẹ́ kan lọ́wọ́, tí ó yàtọ̀ sí iṣẹ́ rere yẹn. Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ náà
____________________
"Iṣẹ́ rere yẹn" ni àwọn iṣẹ́ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ròyìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo ṣíwájú nínú āyah 57 sí āyah 61.
títí di ìgbà tí A máa gbá àwọn onígbẹdẹmukẹ nínú wọn mú pẹ̀lú ìyà. Nígbà náà ni wọ́n máa ké gbàjarì.
Ẹ má kèé gbàjarì lónìí. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Wa.
Wọ́n kúkú ń ka àwọn āyah Mi fun yín. Àmọ́ ńṣe ni ẹ̀ ń fà sẹ́yìn (níbi òdodo).
Ẹ̀ sì ń fi Kaaba ṣègbéraga, ẹ tún ń fi òru yín sọ ìsọkúsọ (nípa al-Ƙur’ān)!
Ṣé wọn kò ronú sí ọ̀rọ̀ náà ni? Tàbí ohun t’ó dé bá wọn jẹ́ ohun tí kò dé bá àwọn bàbá wọn àkọ́kọ́ rí ni?
Tàbí wọn kò mọ Òjíṣẹ́ wọn mọ́ ni wọ́n fi di alátakò rẹ̀?
Tàbí wọn ń wí pé àlùjànnú kan ń bẹ lára rẹ̀ ni? Rárá o. Ó mú òdodo wá bá wọn ni. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì jẹ́ olùkórira òdodo.
Tí ó bá jẹ́ pé (Allāhu), Ọba Òdodo tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn ni, àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àwọn t’ó wà nínú wọn ìbá kúkú ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n A mú ìṣítí nípa ọ̀rọ̀ ara wọn wá fún wọn ni, wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbi ìṣítí (tí A mú wá fún) wọn.
Tàbí ò ń béèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ wọn ni? Owó-ọ̀yà Olúwa rẹ̀ lóore jùlọ. Àti pé Òun l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Àti pé dájúdájú ò ń pè wọ́n sójú ọ̀nà tààrà ni.
Àwọn tí kò sì gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ni wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò lójú ọ̀nà náà.
Tí ó bá jẹ́ pé A kẹ́ wọn (nílé ayé), tí A sì gbé gbogbo ìṣòro ara wọn kúrò fún wọn, wọn ìbá tún won̄koko mọ́ ìtayọ ẹnu-àlà wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà (nínú ìṣìnà).
Dájúdájú A fi ìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọn kò tẹríba fún Olúwa wọn, wọn kò sì rawọ́ rasẹ̀ sí I
títí di ìgbà tí A fi ṣílẹ̀kùn ìyà líle fún wọn; nígbà náà ni wọ́n sọ̀rètí nù.
(Allāhu), Òun ni Ẹni tí Ó ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fun yín, ìdúpẹ́ yín sì kéré.
Òun ni Ẹni tí Ó da yín sórí ilẹ̀, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n yóò ko yín jọ sí.
Òun ni Ẹni t’Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè, Ó ń sọ ẹ̀dá di òkú, tiRẹ̀ sì ni ìtẹ̀léǹtẹ̀lé àti ìyàtọ̀ òru àti ọ̀sán, ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
Rárá (wọn kò níí ṣe làákàyè, ṣebí) irú ohun tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wí ni àwọn náà wí.
Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti kú, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé wọn yóò gbé wa dìde ni?
Wọ́n kúkú ti ṣe àdéhùn yìí fún àwa àti àwọn bàbá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí Ó ni ilẹ̀ àti ẹni tí ó wà ní orí rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?”
Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ méjèèje àti Olúwa Ìtẹ́ ńlá?”
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”
Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?” Sọ pé: “Ta ni Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀, (Ẹni tí) Ó ń gba ẹ̀dá là nínú ìyà, (tí) kò sì sí ẹni tí ó lè gba ẹ̀dá là níbi ìyà Rẹ̀ tí ẹ bá mọ̀?”
Wọ́n á wí pé: “Ti Allāhu ni.” Sọ pé: “Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń dan yín?”
Àmọ́ sá, òdodo ni A mú wá ba wọn. Dájúdájú àwọn sì ni òpùrọ́.
Allāhu kò fi ẹnì kan kan ṣe ọmọ, kò sì sí ọlọ́hun kan pẹ̀lú Rẹ̀. (Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ọlọ́hun kọ̀ọ̀kan ìbá ti kó ẹ̀dá t’ó dá lọ, apá kan wọn ìbá sì borí apá kan. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀ nípa ọmọ bíbí).
(Allāhu) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nítorí náà, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
Sọ pé: “Olúwa mi, Ó ṣeé ṣe kí Ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn hàn mí,
Olúwa mi, má ṣe fi mí sínú ìjọ alábòsí.”
Dájúdájú Àwa lágbára láti fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́.
Fi èyí t’ó dára tí àìdára dànù. Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n fi ń ròyìn (Wa).
Sọ pé: "Olúwa mi, mò ń sádi Ọ́ níbi ròyíròyí t’àwọn èṣù.
Mò ń sádi Ọ́, Olúwa mi, níbi kí wọ́n wá bá mi."
(Wọ́n ń ṣẹ̀mí lọ) títí di ìgbà tí ikú fi máa dé bá ọ̀kan nínú wọn. Ó sì máa wí pé: “Olúwa mi, Ẹ dá mi padà (sílé ayé)
nítorí kí n̄g lè ṣe iṣẹ́ rere nínú èyí tí mo gbé jù sílẹ̀. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, dájúdájú ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó kàn ń wí ni, (àmọ́) gàgá ti wà ní ẹ̀yìn wọn títí di ọjọ́ tí A óò gbé wọn dìde.
____________________
Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (99 àti 100) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Irú āyah yìí tún wà nínú sūrah az-Zumọr; 39:58 àti 59.
Síwájú sí i, àkúdàáyà kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ète àlùpàyídà láti ọ̀dọ̀ àwọn èṣù àlùjànnú. Irú ètekéte yìí náà ni àwọn olówò àlùjànnú máa ń lo láti fi ṣe àwọn òògùn ẹbọ bíi àfẹ́ẹ̀rí, ayẹta, òkígbẹ́, ìṣíjú, ọ̀wọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, kì í ṣe òkú gan-an gan-an ní wọ́n tún lè rí mọ́ níbikíbi nílé ayé, àmọ́ àwọn èṣù àlùjànnú kan lè gbé àwọ̀ àti àwòrán òkú kan wọ̀ láti tan àwọn aláìgbàgbọ́ jẹ. Èyí sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òye t’ó wà nínú mọ̀mí-n̄g-mọ̀ọ́ t’ó gbọ́dọ̀ wáyé láààrin àwọn ẹbí t’ó fẹ́ di tọkọ taya nítorí kí ẹnì kan má baà fi èṣù àlùjànnú ṣe ẹnì kejì rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, kò níí sí ìbátan láààrin wọn ní ọjọ́ yẹn, wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27 nípa ọ̀rọ̀ ìbéèrè.” Èsì: Kò sí ìtakora nínú rẹ̀. Ẹ wò ó, gbólóhùn yìí “wọn kò sì níí bira wọn léèrè ìbéèrè” ìyẹn ní kété tí olúkùlùkù bá kọ́kọ́ jí dìde láti inú sàréè rẹ̀. Iyè yóò pamọ́ àwọn ẹ̀dá nínú lásìkò náà ni, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọsọ; 28:66 àti sūrah az-Zumọr 39:68. Àmọ́ nígbà tí àwọn mọlāika bá da àwọn ẹ̀dá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), àwọn ẹ̀dá máa bẹ̀rẹ̀ sí i bira wọn léèrè ìbéèrè ní ti àbámọ̀ àti ìtakora, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:27. Nítorí náà, kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà gẹ́gẹ́ bí àwọn kristiẹni ṣe lérò.
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n, àwọn wọ̀nyẹn ni olùjèrè.
Ẹnikẹ́ni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá fúyẹ́, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú iná Jahanamọ.
Iná yóò máa jó wọn lójú. Wọn yó sì wà nínú rẹ̀, tí Iná yóò ti bà wọ́n lójú jẹ́.
Ṣé wọ́n kì í ka àwọn āyah Mi fun yín ni, àmọ́ tí ẹ̀ ń pè é nírọ́?
Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, orí burúkú l’ó kọlù wá; àwa sì jẹ́ ìjọ olùṣìnà.
Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú Iná. Tí a bá fi lè padà (síbi iṣẹ́ ibi nílé ayé), dájúdájú nígbà náà alábòsí ni àwa."
(Allāhu) sọ pé: “Ẹ tẹ̀rì sínú rẹ̀. Ẹ má ṣe bá Mi sọ̀rọ̀.”
Dájúdájú igun kan wà nínú àwọn ẹrúsìn Mi, tí wọ́n ń sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Ṣùgbọ́n ẹ sọ wọ́n di oníyẹ̀yẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn yẹ̀yẹ́ (yín) fi mu yín gbàgbé ìrántí Mi. Ẹ̀yin sì ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín.
Dájúdájú Mo san wọ́n ní ẹ̀san ní òní nítorí sùúrù wọn; dájúdájú àwọn, àwọn ni olùjèrè.
(Allāhu) sọ pé: "Ọdún mélòó ni ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) lò lórí ilẹ̀ ayé?"
Wọ́n wí pé: “A lo ọjọ́ kan tàbí abala ọjọ́ kan, bi àwọn olùṣírò-ọjọ́ léèrè wò.”
(Allāhu) sọ pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”
Ṣé ẹ lérò pé A kàn ṣẹ̀dá yín fún ìranù ni, àti pé dájúdájú wọn ò níí da yín padà sọ́dọ̀ Wa?”
Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Olúwa Ìtẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé.
Ẹni tí ó bá pe ọlọ́hun mìíràn pẹ̀lú Allāhu, kò ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí rẹ̀. Dájúdájú ìṣírò-iṣẹ́ rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́ kò níí jèrè.
Sọ pé: “Olúwa mi, ṣàforíjìn, kí O sì kẹ́ (mi). Ìwọ sì l’óore jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.