surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Nūn. (Allāhu búra pẹ̀lú) gègé ìkọ̀wé àti ohun tí àwọn mọlāika ń kọ sílẹ̀.
Ìwọ kì í ṣe wèrè nípa ìdẹ̀ra Olúwa rẹ.
Àti pé dájúdájú ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró ti wà fún ọ.
Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé.
Láìpẹ́ ìwọ yóò rí i, àwọn náà yó sì rí i;
èwo nínú yín ni wèrè?
Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.
Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
Àti pé wọ́n fẹ́ kí o dẹwọ́, kí àwọn náà sì dẹwọ́.
Má ṣe tẹ̀lé gbogbo ẹni tí ìbúra rẹ̀ pọ̀, ẹni yẹpẹrẹ,
abúni, alárìnká t’ó ń sòfófó kiri,
olùdènà iṣẹ́ rere, alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀,
ọ̀dájú. Lẹ́yìn ìyẹn, àsáwọ̀ ni.
____________________
Ìyẹn ni pé, kì í ṣe ojúlówó ọmọ ìran Ƙuraeṣ; àsọdọmọ ni. Ẹni náà ni Walīd ọmọ Mugīrah, ẹni tí ó wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún nígbà tí Mugīrah sọ ọ́ di ọmọ rẹ̀.
Nítorí pé ó ní dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin,
nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí)”.
A máa fi àmì sí i ní góńgórí imú.
Dájúdájú Àwa dán wọn wò gẹ́gẹ́ bí A ṣe dán àwọn ọlọ́gbà wò nígbà tí wọ́n búra pé dájúdájú àwọn yóò ká gbogbo èso ọgbà náà ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
Wọn kò sì ṣe àyàfi pé "tí Allāhu bá fẹ́".
Àdánwò t’ó ń yí n̄ǹkan po láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì yí ọgbà náà po, nígbà tí wọ́n sùn lọ.
Ó sì dà bí oko àgédànù (tí wọ́n ti résun).
Wọ́n ń pera wọn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù
pé ẹ jí lọ sí oko yín tí ẹ bá fẹ́ ká èso.
Wọ́n lọ, wọ́n sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀
pé ní òní mẹ̀kúnnù kan kò gbọdọ̀ wọnú rẹ̀ wá ba yín.
Wọ́n jí lọ lórí èrò-ọkàn kan (pé) àwọn lágbára.
Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí pé: "Dájúdájú àwa ti ṣìnà.
Rárá o, wọ́n ṣe ìkórè oko léèwọ̀ fún wa ni."
Ẹni t’ó dúró déédé jùlọ nínú wọn sọ pé: "Ṣé èmi kò sọ fun yín pé ẹ̀yin kò ṣe ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu (pé "a máa kórè oko wa, ’in ṣā ’Allāhu.)"?
Wọ́n wí pé: "Mímọ́ ni fún Olúwa wa, dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí."
Apá kan wọn kọjú sí apá kan; wọ́n sì ń dára wọn lẹ́bi.
Wọ́n wí pé: "Ègbé wa ò! Dájúdájú àwa jẹ́ olùtayọ-ẹnu àlà.
Ó ṣeé ṣe kí Olúwa wa fi èyí t’ó dára ju èyí lọ pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa ń rokàn oore sí."
Báyẹn ni ìyà náà ṣe rí (fún wọn). Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
Dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún àwọn olùbẹ̀rù lọ́dọ̀ Olúwa wọn.
Ṣé A máa ṣe àwọn mùsùlùmí bí (A ṣe máa ṣe) àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?
Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí ná?
____________________
Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá lérò pé ìkẹ́ máa wà fún òun ní ọ̀run láì jẹ́ pé ó kú sínú ẹ̀sìn ’Islām, ó ti gbé ìdájọ́ gbági.
Tàbí tírà kan wà fun yín tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀
pé dájúdájú ẹ̀yin lẹ ni ohun tí ẹ bá ń ṣà lẹ́ṣà nínú ìdájọ́?
Ǹjẹ́ ẹ ni àwọn àdéhùn kan lọ́dọ̀ wa tí ó máa wà títí di Ọjọ́ Àjíǹde pé: "Dájúdájú tiyín ni ìdájọ́ tí ẹ bá ti mú wá."?
Bi wọ́n léèrè wò pé èwo nínú wọn l’ó lè fọwọ́ ìyẹn sọ̀yà!
Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan? Kí wọ́n mú àwọn òrìṣà wọn wá nígbà náà tí wọ́n bá jẹ́ olódodo.
Ní ọjọ́ tí A máa ṣí ojúgun sílẹ̀, A sì máa pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀, wọn kò sì níí lè ṣe é.
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n kúkú ti pè wọ́n síbi ìforíkanlẹ̀ nígbà tí wọ́n ní àlàáfíà (wọn kò sì kírun).
Nítorí náà, fi Èmi àti ẹni t’ó ń pe ọ̀rọ̀ yìí nírọ́ sílẹ̀. A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò mọ̀.
Mò ń lọ́ra fún wọn ni. Dájúdájú ète Mi lágbára.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Tàbí ò ń bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́dọ̀ wọn, ni gbèsè fi wọ̀ wọ́n lọ́rùn?
Tàbí lọ́dọ̀ wọn ni (wàláà) ìkọ̀kọ̀ wà ni wọ́n bá ń kọ ọ́ (síta)?
Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Kí ìwọ má sì ṣe dà bí ẹlẹ́ja (ìyẹn, Ànábì Yūnus) nígbà tí ó pe (Allāhu) pẹ̀lú ìbànújẹ́.
Tí kò bá jẹ́ pé ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ lé e bá, wọn ìbá jù ú sórí ilẹ̀ gban̄sasa (láti inú ẹja) ní ẹni-èébú.
Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà. Ó sì ṣe é ní ara àwọn ẹni rere.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ẹ̀ fi ojú wọn gbé ọ ṣubú nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrántí náà. Wọ́n sì ń wí pé: "Dájúdájú wèrè mà ni."
Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.