ﰡ
Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò!
A kúkú ti dán àwọn t’ó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn t’ó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.
Àbí àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
Àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí t’ó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe.
A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
Fífi ohun tí ẹ̀dá kò nímọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) túmọ̀ sí pé, sísọ n̄ǹkan kan di ọlọ́hun, olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), n̄ǹkan tí Allāhu kò fi ìmọ̀ nípa n̄ǹkan náà mọ àwa ẹ̀dá Rẹ̀ nínú àwọn Tírà Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “akẹgbẹ́ Rẹ̀”. Ìyẹn bíi sísọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di akẹgbẹ́ Allāhu, ẹni tí Allāhu kò fi ìmọ̀ nípa rẹ̀ mọ̀ wá pé “akẹgbẹ́ Òun” ni. Tàbí bíi sísọ òrìṣà kan di akẹgbẹ́ Allāhu, ẹni tí Allāhu kò fi ìmọ̀ nípa rẹ̀ mọ̀ wá pé “akẹgbẹ́ Òun” ni.
Àwọn t’ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọ́n sínú àwọn ẹni rere.
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń wí pé: “A gba Allāhu gbọ́.” Nígbà tí wọ́n bá sì fi ìnira kàn wọ́n nínú ẹ̀sìn Allāhu, ó máa sọ ìnira ènìyàn dà bí ìyà ti Allāhu. Tí àrànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ bá sì dé, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Dájúdájú àwa wà pẹ̀lú yín.” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà gbogbo ẹ̀dá ni?
Dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ tẹ̀lé ojú ọ̀nà tiwa nítorí kí á lè ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọn kò sì lè ru kiní kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
Dájúdájú wọn yóò ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn àti àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kan mọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. Àti pé dájúdájú A óò bi wọ́n léèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nahl; 16:25
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó gbé láààrin wọn fún ẹgbẹ̀rún ọdún àfi àádọ́ta ọdún. Ẹ̀kún-omi sì gbá wọn mú nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí.
A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.
____________________
Ǹjẹ́ ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ Ànábì Nūh ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di olúwa àti olùgbàlà nítorí pé Allāhu sọ nípa rẹ̀ pé “A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá”? Rárá. Kí ló wá rọ́lu àwọn kan tí wọ́n fi sọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam di olúwa àti olùgbàlà nítorí pé Allāhu sọ nípa rẹ̀ pé “A sì ṣe òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá” (sūrah al-’Anbiyā’ 21:91)? Ìṣìnà pọ́nńbélé nìyẹn.
(Rántí Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.”
Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fun yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
Tí ẹ bá sì pe (òdodo) nírọ́, àwọn ìjọ kan t’ó ṣíwájú yín kúkú ti pe (òdodo) nírọ́. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́-jíjẹ́ pọ́nńbélé.
Tàbí wọn kò rí bí Allāhu ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá ni? Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí Ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá (ní ìpìlẹ̀). Lẹ́yìn náà, Allāhu l’Ó máa mú ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn wá (fún àjíǹde). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”
Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
____________________
“Mọṣī’tu-llāh” Fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu: Èyí lè jẹyọ nínú àwọn awẹ́ gbólóhùn wọ̀nyí; “ ’in ṣā-Allāh” – “tí Allāhu bá fẹ́”, tàbí “mọ̄ ṣā-Allāh” – “ohun tí Allāhu bá fẹ́” tàbí “mọn ṣā-Allāh” – “ẹni tí Allāhu bá fẹ́”. Àpapọ̀ rẹ̀ ní àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ ni “mọṣī’tu-llāh” – fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan pàtàkì lára ìròyìn Allāhu ni “mọṣī’ah” fífẹ́bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá gan-an fúnra rẹ̀ gbàròyìn pẹ̀lú fífẹ́bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé, ẹ̀dá náà ń ṣe n̄ǹkan tí ó bá fẹ́ ṣe, fífẹ́bẹ́ẹ̀ ti Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’ó wà lókè fífẹ́bẹ́ẹ̀ ti ẹ̀dá. Èyí túmọ̀ sí pé, ohun tí Allāhu = = bá fẹ́ l’ó máa ṣẹlẹ̀, kódà kí ẹ̀dá má fẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀. Ohun tí ẹ̀dá bá sì fẹ́, tí Allāhu kò bá fẹ́, kò níí ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìwọ̀nyí ni àpẹẹrẹ fún fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā):
Ìkíní: Fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu nínú kádàrá. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, ohunkóhun tí ẹ̀dá bá rí ṣe nílé ayé nínú iṣẹ́ rere tàbí iṣẹ́ aburú, ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá náà nínú kádàrá rẹ̀ nítorí pé tibi-tire ni kádàrá ẹ̀dá. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní "mọṣī’atu-llāhi al-kaoniyyah" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tayé”. Bí àpẹẹrẹ, lágbájá fẹ́ di olówó lọ́nà ẹ̀tọ́, ó sì di olówó, Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá rẹ̀. Ó sì máa tún gba ẹ̀san rere lọ́dọ̀ Allāhu lórí wíwá owó lọ́nà ẹ̀tọ́. Ní ìdà kejì, tàmẹ̀dò fẹ́ di olówó lọ́nà àìtọ́, ó sì di olówó, Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá rẹ̀. Àmọ́ ó máa gba ẹ̀san aburú lọ́dọ̀ Allāhu lórí wíwá owó lọ́nà àìtọ́.
Ìkejì: Fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu nínú òfin. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, ohunkóhun tí Allāhu bá pa láṣẹ fún ẹ̀dá láti ṣe àti ohunkóhun tí Allāhu bá kọ̀ fún ẹ̀dá láti ṣe nínú àwọn tírà sánmọ̀ tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún àwọn Ànábì Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (a.s.w), ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá nínú òfin àti ìlànà Rẹ̀. Allāhu kò sì níí fẹ́ òfin àti ìlànà kan bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Rẹ̀ t’ó sọ̀kalẹ̀ fún wa àfi kí ó jẹ́ rere pọ́nńbélé tàbí kí rere rẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju aburú rẹ̀ lọ. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní "mọṣī’atu-llāhi aṣ-ṣẹr‘iyyah" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tòfin”. Bí àpẹẹrẹ, lágbájá fẹ́ di mùsùlùmí, ó sì di mùsùlùmí, Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú òfin àti ìlànà Rẹ̀ nínú Tírà Rẹ̀. Ní ìdà kejì, tàmẹ̀dò fẹ́ di kèfèrí, ó sì di kèfèrí. Allāhu kò fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un nínú òfin àti ìlànà Rẹ̀, àmọ́ Ó fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un nínú kádàrá rẹ̀. Pẹ̀lú àlàyé òkè yìí, gbogbo fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú òfin Rẹ̀ ni okùnfà ìyọ́nú Rẹ̀.
Fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu, yálà fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ nínú kádàrá tàbí fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ nínú òfin Rẹ̀, méjèèjì l’ó dúró sórí “ ‘adl” àti “ fọdl” – déédé àti ọlá. Àlàyé èyí ni pé, tí ìyà bá jẹ́ lágbájá nílé ayé tàbí ní ọ̀run, Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nínú kádàrá tí Ó kọ lé lágbájá lórí. Èyí sì jẹ́ déédé láti ọ̀dọ̀ Allāhu nítorí pé Allāhu kì í ṣe àbòsí sí ẹ̀dá Rẹ̀. Bákan náà, tí ìkẹ́ bá tẹ lágbájá lọ́wọ́ nílé ayé tàbí ní ọ̀run, Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nínú kádàrá tí Ó kọ lé lágbájá lórí. Èyí sì jẹ́ ọlá láti ọ̀dọ̀ Allāhu nítorí pé Allāhu l’Ó ni gbogbo ọlá.
Kíyè sí i, fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí ẹ̀dá ní ọ̀run kò túmọ̀ sí pé Allāhu máa fi kó àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọ inú Iná tàbí pé ó máa fi kó àwọn aláìgbàgbọ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí pé fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu kò níí sọ Allāhu di olùyapa àdéhùn Rẹ̀. Ó ti ṣe àdéhùn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì ti ṣe àdéhùn Iná fún àwọn aláìgbàgbọ́. Òdodo sì ni àdéhùn Rẹ̀. Tí Allāhu bá wá yọ ẹnì kan kúrò nínú Iná, láì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, ẹnu ẹni kẹ́ni kò gbà á láti fi ẹ̀sùn kan Allāhu lórí fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ lórí ẹ̀dá rẹ̀. Ṣebí nílé ayé yìí gan-an, láti inú ìdílé ẹrú tí Allāhu bá sọ ẹrú di ọba lábẹ́ fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀, ta ni ó máa mú Allāhu sí i? Kò sí. Bákan náà, láti inú ìdílé ọba, tí Allāhu bá sọ ọba di ẹrú lábẹ́ fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀, ta ni ó máa mú Allāhu sí i? Kò sí. Nítorí náà, ọpẹ́ púpọ̀ ni kí a máa dú fún Allāhu lórí bí fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ lórí wa ṣe ń ṣe wẹ́kú ohun rere tí à ń fẹ́.
Àti pé ẹ̀yin kò níí mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fun yín lẹ́yìn Allāhu.
Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu àti ìpàdé Rẹ̀ (lọ́run), àwọn wọ̀nyẹn ti sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Mi. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún.
Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ pa á tàbí kí ẹ sun ún níná.” Allāhu sì là á nínú iná. Dájúdájú àwọn àmì kúkú wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́ lódodo.
Ó sì sọ pé: “Ẹ kàn mú àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu, ní ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí (láti jọ́sìn fún) láààrin ara yín nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde apá kan yin yóò tako apá kan. Apá kan yín yó sì ṣẹ́bi lé apá kan. Iná sì ni ibùgbé yín. Kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan fun yín.”
(Ànábì) Lūt sì gbà á gbọ́. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Dájúdájú èmi yóò fi ìlú yìí sílẹ̀ nítorí ti Olúwa mi. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
A fi ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀) ta á lọ́rẹ. A sì ṣe jíjẹ́ Ànábì àti fífúnni ní tírà sínú àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀. A fún un ní ẹ̀san rẹ̀ ní ayé yìí. Dájúdájú ní ọ̀run, ó tún wà nínú àwọn ẹni rere.
(Rántí Ànábì) Lūt. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ń ṣe ìbàjẹ́ tí kò sí ẹnì kan nínú ẹ̀dá tí ó ṣe é rí ṣíwájú yín.
Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa tọ àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) lọ (fún adùn ìbálòpọ̀), ẹ tún ń dánà, ẹ tún ń ṣe ohun burúkú nínú àkójọ yín? Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan àfi kí wọ́n wí pé :“Mú ìyà Allāhu wá fún wa tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
____________________
Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé, ìjọ rẹ̀ kì í sọ ọ̀rọ̀ mìíràn láti fi takò ó. Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu wọ́n máa ń dá lérí “múyà wá”.
Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mí lórí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì mú ìró ìdùnnú dé bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa máa pa àwọn ará ìlú yìí run. Dájúdájú àwọn ará ìlú náà jẹ́ alábòsí.”
Ó sọ pé: “Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà níbẹ̀! Wọ́n sọ pé: “Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó wà níbẹ̀. Dájúdájú àwa yóò la òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó máa wà nínú àwọn t’ó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Wọ́n sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú a máa la ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ àfi ìyàwó rẹ tí ó máa wà nínú àwọn olùṣẹ́kù-lẹ́yìn sínú ìparun.”
Dájúdájú a máa sọ ìyà kan kalẹ̀ lé àwọn ará ìlú yìí lórí láti inú sánmọ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
Dájúdájú A ti fi àmì kan t’ó fojú hàn lélẹ̀ nínú rẹ̀ fún ìjọ t’ó ní làákàyè.
A tún ránṣẹ́ sí ará ìlú Mọdyan. (A rán) arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb (níṣẹ́ sí wọn). Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ retí Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.”
Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle t’ó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni t’ó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) ará ‘Ād àti ará Thamūd. (Ìparun wọn) sì kúkú ti fojú hàn kedere si yín nínú àwọn ibùgbé wọn. Èṣù ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì ṣẹ́rí wọn kúrò nínú ẹ̀sìn (Allāhu). Wọ́n sì jẹ́ olùríran (nípa ọ̀rọ̀ ayé).
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) Ƙọ̄rūn, Fir‘aon àti Hāmọ̄n. Dájúdájú (Ànábì) Mūsā mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn. Wọ́n sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Wọn kò sì lè mórí bọ́ nínú ìyà.
A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ gbémì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Àpèjúwe àwọn t’ó mú àwọn (òrìṣà) ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu, ó dà bí àpèjúwe aláǹtàakùn tí ó kọ́ ilé kan. Dájúdájú ilé tí ó yẹpẹrẹ jùlọ ni ilé aláǹtàakùn, tí wọ́n bá mọ̀.
Dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Àwọn àkàwé wọ̀nyí, tí À ń fún àwọn ènìyàn, kò sì sí ẹni tí ó máa ṣe làákàyè nípa rẹ̀ àfi àwọn onímọ̀.
Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
____________________
Gbólóhùn yìí “ولذكر الله أكبر” (wala thikru-llāh ’akbar) jẹ́ gbólóhùn tí àwọn onímọ̀ fún ní ìtúmọ̀ bíi márùn-ún. Ìtúmọ̀ kìíní: Ẹ̀san tí Allāhu máa fun yín lórí ìjọ́sìn tóbi ju bí ẹ ṣe jọ́sìn fún Un. Ìtúmọ̀ kejì: Mímú àwọn gbólóhùn ìrántí Allāhu wá, àwọn gbólóhùn bíi subhān-Allāh, al-hamdulillāh, Allāhu ’akbar, kíké al-Ƙur’ān àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ó tóbi ní ẹ̀san ju dídúró nìkan, dídáwọ́ tẹ orúnkún nìkan, fíforí kanlẹ̀ nìkan, kíkó ẹnuró nìkan (ìyẹn, ààwẹ̀ gbígbà), lílọ sí ojú ogun ẹ̀sìn nìkan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn nígbà tí ṣíṣe àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí kò bá kó ṣíṣe ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn gbólóhùn ìrántí Allāhu t’ó tọ sunnah sínú. Ìyẹn ni pé, ohun tí ó lóòrìn jùlọ nínú ìjọ́sìn ẹlẹ́kajẹ̀ka ní àwọn gbólóhùn ìrántí Allāhu, tí ẹ̀dá rí mú wá nínú ẹka ìjọ́sìn náà. Ìtúmọ̀ kẹta: Ó kó ìtúmọ̀ kìíní àti ìkejì sínú papọ̀. Ìyẹn ni pé, bí ẹ̀san ìjọ́sìn ṣe tóbi ju ìjọ́sìn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni pé ohun tí ó lóòrìn jùlọ nínú ìjọ́sìn ni àwọn gbólóhùn ìrántí Allāhu, èyí tí a rí mú wá nínú ìjọ́sìn náà. Ìtúmọ̀ kẹrin: Ẹ̀san tí Allāhu máa fún ẹrúsìn lórí ìrun kíkí tóbi ju ìrun tí ó kí lọ. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ni ó wà nínú ìtúmọ̀ kìíní àti ìkẹrin yìí. Ìkíní ń sọ nípa ẹ̀san ìjọ́sìn ní àpapọ̀, ṣùgbọ́n ìtúmọ̀ kẹ́rin ń sọ nípa ẹ̀san ìrun kíkí nìkan.
Ìtúmọ̀ karùn-ún: Ẹ̀san ìrun kíkí àti ẹ̀san mímú gbólóhùn ìrántí Allāhu wá lórí ìrun, ó tóbi jú bí ìrun kíkí ṣe ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú fún ẹ̀dá. Ìyẹn ni pé, bí ìrun kíkí ṣe ní ẹ̀san, bẹ́ẹ̀ náà ló tún jẹ́ ohun t’ó ń mú olùkírun jìnnà sí ìwà aburú, ṣùgbọ́n abala ẹ̀san kò ṣe é fojú rénà fún ẹni tí kò yé hùwà aburú. Bí ẹ̀san ìrun kíkí rẹ̀ yó ṣe mọ l’ó máa mọ, kódà kí aburú rẹ̀ kó gbogbo ẹ̀san ìjọ́sìn rẹ̀ tán nílẹ̀, olùkírun t’ó ń hùwà ìbàjẹ́ kò lè di èrò inú Iná gbére, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá padà já sí Iná. Ó sì máa padà wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo tí ìjọ́sìn tọ́ sí kò bá ti ròpọ̀ mọ́ sísọ ẹ̀dá kan di akẹgbẹ́ fún Un, èyí tí a mọ̀ sí ẹbọ ńlá "aṣ-ṣirku al-’akbar", tàbí ṣíṣe àìgbàgbọ́ nínú Allāhu "al-kufru al-mukriju minal-millah" àti ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú àdìsọ́kàn "an-nifāƙ al-’i‘tiƙọ̄di".
Wàyí, nínú àwọn ìtúmọ̀ márààrùn-ún òkè wọ̀nyí, ìtúmọ́ kìíní l’ó gbòòrò jùlọ. Òhun sì ni ìtúmọ̀ tí tafsīr Tọbariy fara mọ́ jùlọ.
Kíyè sí i, kò sí ọ̀kan nínú àwọn ìtúmọ̀ márààrùn-ún òkè wọ̀nyí t’ó ní kí mùsùlùmí fi gbólóhùn ìrántí Allāhu rọ́pò ìrun kíkí, ààwẹ̀ gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ìrun kíkí àti ààwẹ̀ gbígbà tì nípasẹ̀ fífún gbólóhùn yìí ní ìtúmọ̀ òdì, ó ti kó ìparun bá ẹ̀mí ara rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-Muddaththir; 74: 42-43. Kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) là wá nínú èyí.
Ẹ má ṣe bá ahlul-kitāb ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà t’ó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn t’ó bá ṣàbòsí nínú wọn. Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
____________________
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòsí wulẹ̀ ni gbogbo àwọn ahlul-kitāb, àbòsí mìíràn ni Allāhu ń tọ́ka sí lára wọn nínú āyah yìí. Òhun sì ni bí àwọn ahlul-kitāb ṣe ń gbógun ti àwa mùsùlùmí àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀ láti san ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām.
Báyẹn ni A ṣe sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ. Nítorí náà, àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n gbà á gbọ́. Ó sì wà nínú àwọn wọ̀nyí (ìyẹn, àwọn ará Mọkkah), ẹni t’ó gbà á gbọ́. Kò sì sí ẹni t’ó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn aláìgbàgbọ́.
____________________
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa wọn nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:52-55. Àpẹẹrẹ wọn ni ‘Abdullāh bun Salām àti Ọba Najāṣi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ ’Ashamah (r.ahmọ.).
Ìwọ kò ké tírà kan rí ṣíwájú al-Ƙur’ān, ìwọ kò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ kọ n̄ǹkan rí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, kí àwọn òpùrọ́ ṣeyèméjì (sí al-Ƙur’ān).
Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó. al-Ƙur’ān), òhun ni àwọn āyah t’ó yanjú nínú igbá-àyà àwọn tí A fún ní ìmọ̀-ẹ̀sìn. Kò sì sí ẹni t’ó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn alábòsí.
Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi.”
Ṣé kò tó fún wọn (ní àmì ìyanu) pé A sọ tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ, tí wọ́n ń ké e fún wọn? Dájúdájú ìkẹ́ àti ìṣítí wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó gbàgbọ́.
Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn t’ó gba irọ́ gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
Wọ́n sì ń kán ọ lójú nípa ìyà! Tí kò bá jẹ́ pé ó ti ní gbèdéke àkókò kan ni, ìyà náà ìbá kúkú dé bá wọn. (Ìyà) ìbá dé bá wọn ní òjijì sẹ́, wọn kò sì níí fura.
Wọ́n ń kán ọ lójú nípa ìyà! Dájúdájú iná Jahanamọ kúkú máa yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
(Rántí) ọjọ́ tí ìyà yóò bò wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn àti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, (Allāhu) sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ (ìyà) ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”
Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò. Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún.
Gbogbo ẹ̀mí l’ó máa tọ́ ikú wò. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni wọn yóò da yín padà sí.
Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọn sínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gígá kan nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere sì dára.
(Àwọn ni) àwọn t’ó ṣe sùúrù. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
Mélòó mélòó nínú àwọn ẹranko tí kò lè dá bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀ gbé, tí Allāhu sì ń ṣe ìjẹ-ìmu fún àwọn àti ẹ̀yin. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.”
Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n yóò pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Àmọ́ nígbà tí Ó bá kó wọn yọ sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu?
Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí t’ó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
Àwọn t’ó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere.