ترجمة سورة القارعة

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة القارعة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Àkókò ìjáyà.
Kí ni Àkókò ìjáyà?
Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
àwọn àpáta yó sì dà bí òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀ wọ̀n,
ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó yọ́nú sí.
Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
Kí sì ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
(Òhun ni) Iná gbígbóná gan-an.
Icon