ترجمة معاني سورة لقمان
باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà ọgbọ́n.
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún àwọn olùṣe-rere;
àwọn t’ó ń kírun, tí wọ́n ń yọ zakāh. Àwọn sì ni wọ́n ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn olùjèrè.
Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni t’ó ń ra ìranù-ọ̀rọ̀ láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún.
____________________
Ìranù-ọ̀rọ̀ ni gbogbo ọ̀rọ̀ t’ó jẹ́ odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà). Ríra ìranù-ọ̀rọ̀ túmọ̀ sí n̄ǹkan méjì. Ìkíní: Ríra ìranù-ọ̀rọ̀ túmọ̀ sí nínáwó lórí ìranù-ọ̀rọ̀ bíi pípe olórin, ríra àwo orin, ríra irin-iṣẹ́ fún orin, kíkún onítíátà lọ́wọ́. Ìkéjì: Ríra ìranù-ọ̀rọ̀ túmọ̀ sí níní ìfẹ́ sí ìranù-ọ̀rọ̀. Lílo ìranù-ọ̀rọ̀ láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà Allāhu túmọ̀ sí lílo ìranù-ọ̀rọ̀ àti gbígbọ́lá fún un nínú ìṣẹ̀mí ayé dípò lílo ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lára rẹ̀ ni lílo àsìkò fún ìranù-ọ̀rọ̀ dípò kíké al-Ƙur’ān (tilāwah), gbígbọ́ wáàsí àti ṣíṣe ìrántí Allāhu (ath-thikr).
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa pẹ̀yìndà ní ti ìgbéraga, àfi bí ẹni pé kò gbọ́ ọ, àfi bí ẹni pé èdídí wà nínú etí rẹ̀ méjèèjì. Nítorí náà, fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) àdéhùn tí Allāhu ṣe ní ti òdodo. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ó dá àwọn sánmọ̀ láì ní òpó tí ẹ lè rí. Ó sì ju àwọn àpáta t’ó dúró gbagidi sínú ilẹ̀ kí ó má fi lè mì mọ yín lẹ́sẹ̀. Ó fọ́n gbogbo n̄ǹkan abẹ̀mí ká sórí ilẹ̀. A tún sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, A sì fi mú gbogbo oríṣiríṣi èso dáadáa hù jáde láti inú ilẹ̀.
Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni.
Dájúdájú A ti fún Luƙmọ̄n ní ọgbọ́n, pé: “Dúpẹ́ fún Allāhu.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúpẹ́, ó ń dúpẹ́ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́ (tí ọpẹ́ tọ́ sí).
(Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: “Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá.
Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì – (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.1 Fi dáadáa bá àwọn méjèèjì lò pọ̀ ní ilé ayé.2 Kí o sì tẹ̀lé ojú ọ̀nà ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Mi (ní ti ìronúpìwàdà). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
____________________
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-‘Ankabūt; 29:8.
2. N̄ǹkan mẹ́ta ni dáadáa. Ìkíní: ohunkóhun tí āyah al-Ƙur’ān bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni. Ìkejì: ohunkóhun tí sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni. Ìkẹta: ohunkóhun tí àṣà àti ìṣe ẹ̀yà ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan bá pè ní dáadáa, n̄ǹkan dáadáa ni ní òdiwọ̀n ìgbà tí āyah kan tàbí hadīth kan kò bá ti lòdì sí irúfẹ́ n̄ǹkan náà. Bí àpẹẹrẹ, nínú àṣà àti ìṣe ọmọ Yorùbá ni àṣà ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí òbí ẹni àti àwọn aṣíwájú. Àmọ́ hadīth lòdì sí i. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:34 lórí ìyẹn. Bákan náà, nínú àṣà àti ìṣe ọmọ Yorùbá ni fífi ọtí “ìbílẹ̀” ṣàdúà. Àmọ́ āyah àti hadīth lòdì sí ọtí. Kíyè sí i, kò sí āyah tàbí hadīth tí ó lòdì sí kí ọmọ gbé òbí rẹ̀ jáde lọ sí ibì kan. Èyí náà sì wà nínú àṣà àti ìṣe ọmọ Yorùbá. Àmọ́ āyah àti hadīth lòdì sí kí ọmọ gbé òbí rẹ̀ lọ sí ojúbọ òrìṣà àti ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ibikíbi tí n̄ǹkan t’ó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ lè jẹ́ okùnfa ìbínú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bíi àyè ayẹyẹ òkú tàbí maolid-nnabiyi nítorí pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìbàjẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Mọ̄’idah; 5:2 (lọ́wọ́ ìparí āyah náà).
Ọmọ mi, dájúdájú tí ó bá jẹ́ pé òdiwọ̀n èso kardal kan ló wà nínú àpáta, tàbí nínú àwọn sánmọ̀, tàbí nínú ilẹ̀, Allāhu yóò mú un wá. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
____________________
Ìyẹn dúró fún òdíwọ̀n t’ó kéré gan-an bíi ọmọ-iná igún.
Ọmọ mi, kírun, p’àṣẹ rere, kọ aburú, kí o sì ṣe sùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ. Dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀ t’ó pọn dandan.
Má ṣe kọ párìkẹ́ rẹ sí ènìyàn. Má sì ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú fáàrí. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn gbogbo onígbèéraga, onífáàrí.
Jẹ́ kí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì, kí o sì rẹ ohùn rẹ nílẹ̀. Dájúdájú ohùn t’ó burú jùlọ mà ni ohùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Ṣé ẹ ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ fun yín, Ó sì pé àwọn ìkẹ́ Rẹ̀ fun yín ní gban̄gba àti ní kọ̀rọ̀? Ó sì wà nínú àwọn ènìyàn ẹni t’ó ń jiyàn nípa Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (nínú sunnah Ànábì s.a.w.) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) t’ó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí a bá lọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” (Ṣé wọn yóò tẹ̀lé àwọn bàbá wọn) t’òhun ti bí Èṣù ṣe ń pè wọ́n síbi ìyà Iná t’ó ń jò fòfò?
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, tí ó jẹ́ olùṣe-rere, dájúdájú onítọ̀un ti dìrọ̀ mọ́ okùn t’ó fọkàn balẹ̀ jùlọ. Àti pé ọ̀dọ̀ Allāhu ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, má ṣe jẹ́ kí àìgbàgbọ́ rẹ̀ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Nígbà náà, A máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
A máa fún wọn ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, A máa taari wọn sínú ìyà t’ó nípọn.
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ̀.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ọlọ́pẹ́.
Tí ó bá jẹ́ pé kìkìdá ohun t’ó ń bẹ lórí ilẹ̀ ní igi ni gègé ìkọ̀wé, kí agbami odò jẹ́ tàdáà rẹ̀, agbami odò méje (tún wà) lẹ́yìn rẹ̀ (t’ó máa kún un), àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu kò níí tán (lẹ́yìn tí àwọn n̄ǹkan ìkọ̀wé wọ̀nyí bá tán nílẹ̀). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ìṣẹ̀dá yín àti àjíǹde yín kò tayọ bí (ìṣẹ̀dá àti àjíǹde) ẹ̀mí ẹyọ kan. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán, Ó ń ti ọ̀sán bọ inú òru, Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá? Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ń rìn títí di gbèdéke àkókò kan. Àti pé (ṣé o ò rí i pé) dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú ọkọ̀ ojú-omi ń rìn ní ojú omi pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀, (ṣebí) nítorí kí (Allāhu) lè fi hàn yín nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí àwọn àpáta àti ẹ̀ṣújò, wọ́n á pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni t’ó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Kí ẹ sì páyà ọjọ́ kan tí òbí kan kò níí ṣàǹfààní fún ọmọ rẹ̀; àti pé ọmọ kan, òun náà kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún òbí rẹ̀. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Nítorí náà, ìṣẹ̀mí ayé yìí kò gbọdọ̀ tàn yín jẹ. (Èṣù) ẹlẹ́tàn kò sì gbọdọ̀ tàn yín jẹ nípa Allāhu.
Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun t’ó wà nínú àpòlùkẹ́. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.
____________________
Ohun t’ó wà nínú àpòlùkẹ́ lè di mímọ̀ fún ẹ̀dá nípasẹ̀ yíya àwòrán ọlẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ ìyàwòrán-ọlẹ̀. Èyí kò sì lòdì sí àgbọ́yé āyah náà. Àmọ́ bí ọ̀rọ̀ tayé àti tọ̀run ọlẹ̀ ṣe máa rí kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Èyí sì ni àgbọ́yé āyah náà.