A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.
____________________
Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni oníròó-ìdùnnú fún èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òun náà sì ni olùkìlọ̀ fún èrò inú Iná. Jíjẹ́ tí Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ oníròó-ìdùnnú túmọ̀ sí pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìró nípa ìjọ́sìn, ìwà dáradára àti ọ̀nà ìṣẹ̀mí tí a óò fi rí Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ̀. Àti pé lára ìró ìdùnnú tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n ẹ̀san tí a lè rí gbà lórí àwọn iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ tí Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ olùkìlọ̀ túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìkìlọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan tí ó lè múni wọ inú Iná. Àti pé lára ìkìlọ̀ tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n àti irú ìyà tí ẹ̀dá lè rí lórí àwọn iṣẹ́ Iná. Al-Ƙur’ān àti Hadīth Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni orísun fún ìmọ̀ nípa ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀. Nítorí náà, ọ̀kan nínú àwọn bẹ̀sìnjẹ́ (ohun t’ó ń ba ẹ̀sìn jẹ́) mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́ ni kí ẹlòmíìràn nínú ìjọ rẹ̀ sọra rẹ̀ di oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí pé, onítọ̀ún ti sọra rẹ̀ di arímìísígbà. Ìmísí sánmọ̀ sì ti dòpin.

الترجمة اليورباوية