Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”
____________________
Ìyẹn ni pé, tí ẹ̀yin bá jẹ́ mọlāika ni, mọlāika ni ìbá jẹ́ Òjíṣẹ́ yín. Àmọ́ ènìyàn ni yín, Òjíṣẹ́ yín náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ènìyàn. Kíyè sí i, nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò níí sọ mọlāika di Òjíṣẹ́ láààrin àwọn ènìyàn, báwo wá ni Allāhu yó ṣe wá sọ ara Rẹ̀ di Òjíṣẹ́ láààrin àwọn ènìyàn? Ìyẹn ni pé, irọ́ ńlá ni láti ẹnu àwọn kristiẹni láti sọ pé Ọlọ́hun fúnra Rẹ̀ l’ó wá jíṣẹ́ ara Rẹ̀ ní àwòrán Jésù Kristi láààrin àwọn ọmọ Isrọ̄’īl! Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀ ní irọ́.

الترجمة اليورباوية