ترجمة سورة الأحزاب

الترجمة اليورباوية
ترجمة معاني سورة الأحزاب باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.
Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà.
Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ ò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fun yín nípa ohun tí ẹ bá ṣàṣìṣe rẹ̀, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Àṣẹ pípe ẹrú pẹ̀lú orúkọ bàbá rẹ̀, tí fífi orúkọ olówó-ẹrú pe ẹrú kò sì dára, èyí ti fi hàn kedere pé, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún obìnrin láti fi orúkọ ọkọ rẹ̀ pààrọ̀ orúkọ bàbá rẹ̀. Àṣà àwọn aláìgbàgbọ́ ni àṣà fífi orúkọ ọkọ pààrọ̀ orúkọ bàbá. Yàtọ̀ sí pé, àṣà náà jẹ́ àṣà àwọn aláìgbàgbọ́, ó tún jẹ́ àbòsí láti ọ̀dọ̀ ọmọ sí bàbá rẹ̀ nítorí pé, òfin t’ó ní kí ọkùnrin máa jẹ́ orúkọ bàbá rẹ lọ, ìbáà di ọkọ ìyàwó, òfin yìí náà l’ó ní kí ọmọbìnrin máa jẹ́ orúkọ bàbá rẹ̀ lọ, ìbáà di ìyàwó. Nítorí náà, yálà kí obìnrin dárúkọ ara rẹ̀ báyìí “lágbájá ọmọ lámọrín” tàbí kí ó sọ pé “lágbájá aya tàmẹ̀dò”. Àgbékalẹ̀ orúkọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ìbátan t’ó wà láààrin orúkọ rẹ̀ àti orúkọ ọkùnrin t’ó pè mọ́ra rẹ̀. Wọn kò sì gbọ́dọ̀ dárúkọ ọkọ nìkan láti fi pe ìyàwó, gẹ́gẹ́ bí wọ́n kò ṣe gbọ́dọ̀ dárúkọ bàbá nìkan láti fi pe ọmọ. Ẹ pe ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀.
Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀). Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn t’ó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀). Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀.
____________________
Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), mùsùlùmí gbọ́dọ̀ fẹ́ràn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ju ẹ̀mí ara rẹ̀. Bákan náà, nípa ìdájọ́, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ tẹ ìfẹ́-inú rẹ̀ ba fún ìdájọ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
(Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn t’ó nípọn
nítorí kí (Allāhu) lè bèèrè (òdodo) àwọn olódodo nípa òdodo wọn. Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ ò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
____________________
Ọmọ ogun oníjọ ni àwọn ọmọ ogun ìjọ mẹ́ta kan tó para pọ̀ lórí ìjọ ọmọ ogun Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam): ìjọ ọmọ ogun Ƙuraeṣi, ìjọ ọmọ ogun Gatfān àti ìjọ ọmọ ogun Yẹhudi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Nadīr. Gbogbo àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ní àpapọ̀ ni à ń pè ní ’ahzāb “ọmọ ogun oníjọ”.
(Ẹ rántí) nígbà tí wọ́n dé ba yín láti òkè yín àti ìsàlẹ̀ yín, àti nígbà tí àwọn ojú yẹ̀ (sọ́tùn-ún sósì), tí àwọn ọkàn sí dé ọ̀nà-ọ̀fun (ní ti ìpáyà). Ẹ sì ń ro àwọn èrò kan nípa Allāhu.
Níbẹ̀ yẹn ni wọ́n ti fi àdánwò kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n sì milẹ̀ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ní ìmìtìtì líle.
(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àìsàn wà nínú ọkàn wọn ń wí pé: “Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kò ṣe àdéhùn kan fún wa bí kò ṣe ẹ̀tàn.”
(Ẹ rántí) nígbà tí igun kan nínú wọn wí pé: “Ẹ̀yin ará Yẹthrib, kò sí àyè (ìṣẹ́gun) fun yín, nítorí náà, ẹ ṣẹ́rí padà (lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́).” Apá kan nínú wọn sì ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ Ànábì, wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú ilé wa dá páropáro ni.” (Ilé wọn) kò sì dá páropáro. Wọn kò sì gbèrò ohun kan tayọ síságun.
____________________
Yẹthrib ni orúkọ ìlú Mọdīnah ṣíwájú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tó ṣe hijrah wá sí ibẹ̀.
Àti pé tí ó bá jẹ́ pé (ọmọ ogun oníjọ) wọlé tọ̀ wọ́n wá láti àwọn ìloro ìlú (Mọdīnah), lẹ́yìn náà, kí wọ́n pe (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) sínú ẹbọ ṣíṣe, wọn ìbá ṣẹbọ. Wọn kò sì níí gbé nínú ìlú mọ́ tayọ ìgbà díẹ̀ (tí wọn yóò fi parẹ́).
Dájúdájú wọ́n ti bá Allāhu ṣe àdéhùn ṣíwájú pé àwọn kò níí pẹ̀yìndà (láti ságun). Àdéhùn Allāhu sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa bèèrè (lọ́wọ́ wọn).
Sọ pé: “Síságun yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí ẹ bá sá fún ikú tàbí pípa (sí ojú ogun ẹ̀sìn. Tí ẹ bá sì ságun) nígbà náà, A ò níí fun yín ní ìgbádùn ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.
Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó lè dá ààbò bò yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá fẹ́ fi aburú kàn yín tàbí tí Ó bá fẹ́ kẹ yín?” Wọn kò sì lè rí aláàbò tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.
Dájúdájú Allāhu ti mọ àwọn t’ó ń fa ènìyàn sẹ́yìn nínú yín àti àwọn t’ó ń wí fún àwọn arakùnrin wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Wọn kò sì níí lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn àfi (ogun) díẹ̀.
Wọ́n ní ahun si yín (láti ṣe ìrànlọ́wọ́). Nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá dé, o máa rí wọn tí wọn yóò máa wò ọ́. Ojú wọn yó sì máa yí kiri ràkọ̀ràkọ̀ (ní ti ìbẹ̀rù) bí ẹni tí ó fẹ́ dákú, ṣùgbọ́n nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá lọ, (tí ìkógun bá dé), wọn yóò máa fi àwọn ahọ́n kan t’ó mú bérébéré ba yín sọ̀rọ̀ ní ti ṣíṣe ọ̀kánjúà sí oore náà. Àwọn wọ̀nyẹn kò gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.
Wọ́n ń lérò pé àwọn ọmọ ogun oníjọ kò tí ì lọ, (wọ́n sì ti túká). Tí àwọn ọmọ ogun oníjọ bá (sì padà) dé, dájúdájú (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò fẹ́ kí àwọn ti wà ní oko láààrin àwọn Lárúbáwá oko, kí wọ́n máa bèèrè nípa àwọn ìró yín (pé ṣé ẹ ti kú tán tàbí ẹ sì wà láyé). Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n wà láààrin yín, wọn kò níí jagun bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fun yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà).
Nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu).
____________________
Àdéhùn náà wà nínú àwọn sūrah bí sūrah al-Baƙọrah; 2:214 àti sūrah al-‘Ankabūt; 29:1-3.
Ó wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ olódodo nípa àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe; ó wà nínú wọn ẹni tí ó pé àdéhùn rẹ̀ (t’ó sì kú sójú ogun ẹ̀sìn), ó sì wà nínú wọn ẹni t’ó ń retí (ikú tirẹ̀). Wọn kò sì yí (àdéhùn) padà rárá.
(Ìwọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi (òdodo) àwọn olódodo san wọ́n ní ẹ̀san òdodo wọn, àti nítorí kí Ó lè jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìyà tí Ó bá fẹ́ tàbí nítorí kí Ó lè gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Allāhu sì dá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ padà tòhun ti ìbínú wọn; ọwọ́ wọn kò sì tẹ oore kan. Allāhu sì tó àwọn onígbàgbọ́ òdodo níbi ogun náà. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Olùborí.
(Allāhu) sì mú àwọn t’ó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn ahlul-kitāb sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú.
____________________
Àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn ni àwọn yẹhudi tí wọ́n ń jẹ́ banū Ƙuraeṭḥọh, tí wọ́n ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àwọn wọ̀nyí mọ odi ńlá ńlá yípo àwọn ilé wọn fún ààbò ogun. Àwọn wọ̀nyí l’ó ṣe agbódegbà fún àwọn ọmọ ogun oníjọ. Lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì dójú ti àwọn ọmọ ogun oníjọ tán, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fàbọ̀ sórí wọn.
(Allāhu) sì jogún ilẹ̀ wọn, ilé wọn, dúkìá wọn àti ilẹ̀ tí ẹ ò tẹ̀ rí fun yín. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn ìyàwó rẹ pé: “Tí ẹ bá fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ẹ wá níbí kí n̄g fun yín ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀, kí n̄g sì fi yín sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà.
____________________
Ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀ ni ohunkóhun ní owó tàbí n̄ǹkan mìíràn tí ọkọ yóò fún ìyàwó tí ó fẹ́ kọ̀ sílẹ̀. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:236.
Tí ẹ bá sì fẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ilé Ìkẹ́yìn, dájúdájú Allāhu ti pèsè ẹ̀san ńlá sílẹ̀ de àwọn olùṣe-rere lóbìnrin nínú yín.”
Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ìbàjẹ́ t’ó fojú hàn, A máa di àdìpèlé ìyà ìlọ́po méjì fún un. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú yín, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, A máa fún un ní ẹ̀san ìlọ́po méjì. A sì ti pèsè ìjẹ-ìmu alápọ̀n-ọ́nlé sílẹ̀ dè é.”
Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹ ò dà bí ẹnì kan kan nínú àwọn obìnrin, tí ẹ bá ti bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ má ṣe dínhùn (sí àwọn ọkùnrin létí) nítorí kí ẹni tí àrùn wà nínú ọkàn rẹ̀ má baá jẹ̀rankàn. Kí ẹ sì máa sọ ọ̀rọ̀ t’ó dára.
Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ t’ó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni.
Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀.
____________________
Àwọn àkíyèsí méjì kan ń bẹ lára gbogbo gbólóhùn àṣẹ tí ó wà nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34. Àkíyèsí kìíní ni pé, àwọn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) dojú àwọn àṣẹ náà kọ ni àwọn ìyàwó Ànábì (kí Allāhu yọ́nú sí wọn), ṣùgbọ́n kò sí àṣẹ kan nínú rẹ̀ tí ó yọ àwọn mùsùlùmí lóbìnrin yòókù sílẹ̀. Ìdí ni pé, àgbékalẹ̀ àwọn àṣẹ náà dúró fún gbígbèrò gbogbogbò pẹ̀lú dídojú-ọ̀rọ̀ kọ aṣíwájú. Nítorí náà, ẹ wo ìṣerẹ́gí láààrin gbólóhùn yìí “Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ tó di mùsùlùmí)....” àti gbólóhùn yìí “Kí wọ́n má ṣe ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀…” èyí tí ó wà nínú sūrah an-Nūr; 24:31.
Àkíyèsí kejì ni pé, èdè Lárúbáwá jẹ́ èdè jẹ́ńdà. Èdè jẹ́ńdà ni èdè t’ó ni ìhun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún akọ àti abo. Ìyẹn ni pé, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin tàbí n̄ǹkan akọ, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun akọ fún akọ. Bákan náà, tí Lárúbáwá bá ń d’ojú ọ̀rọ̀ kọ obìnrin tàbí n̄ǹkan abo tàbí ó ń sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tàbí n̄ǹkan abo, èdè Lárúbáwá ti ní ìhun abo fún abo. Irúfẹ́ àbùdá yìí kò sí fún èdè Yorùbá. Ìhun akọ kò yàtọ̀ sí ìhun abo. Nítorí náà, gbogbo àwọn gbólóhùn àṣẹ tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) mú wá nínú sūrah yìí láti āyah 28 sí 34 jẹ́ gbólóhùn àṣẹ fún ìhun abo nítorí pé, àwọn obìnrin ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa wọn. Àwọn sì ni Ó ń dojú gbólóhùn àṣẹ náà kọ. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a fẹ́ rí kọ́ nínú èyí ni pé, bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe pàṣẹ ìjọ́sìn fún àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ náà ni Ó ṣe pàṣẹ rẹ̀ fún àwọn obìnrin. Àti pé èèwọ̀ ni ohunkóhun tí ó bá lè sọ mùsùlùmí lóbìnrin di aláìgbàgbọ́ nípasẹ̀ níní ọkọ nítorí pé, obìnrin ní ẹ̀sìn. ’Islām sì ni ẹ̀sìn rẹ̀, ẹ̀sìn Allāhu. Ẹ̀rí apayànjẹ (= ẹ̀rí t’ó ń pa iyàn jíjà jẹ) ni bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ń sọ nípa ẹ̀san àwọn olújọ́sìn; Ó ń sọ ọ́ pẹ̀lú ìhun akọ àti ìhun abo láì fi àwọn obìnrin ṣe olùjọ́sìn afarahẹ. Ẹ wo āyah 35 nínú sūrah yìí àti sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:195, sūrah an-Nisā’; 4:124, sūrah an-Nahl; 16:97, sūrah Gọ̄fir; 40:40 àti sūrah al-Hujurāt; 49:13.
Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùpáyà Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùpáyà Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn t’ó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n.
Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé.
(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún1 pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ.2
____________________
1. Ẹni yìí ni Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu). Ìdẹ̀ra Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lórí rẹ̀ ni pé, Allāhu ṣe é ní mùsùlùmí. Ìdẹ̀ra Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lórí rẹ̀ ni pé, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mú un kúrò lóko ẹrú. Ó sọ ọ́ di olómìnira. 2. Ohun tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀ ni gbólóhùn yìí: "Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …". Àmọ́ kàkà kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kéde gbólóhùn yìí fún àwọn mùsùlùmí, kí ó sì jíṣẹ́ fún Zaed, ńṣe ni Ànábì ń sọ fún un pé: "Mú ìyàwó rẹ dání..." Ohun tí ó sì fa èyí fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni pé, kí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn aláìgbàgbọ́ má baà wí pé: "Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) l’ó fi Zaenab fún Zaed, ọmọ rẹ̀. Ó tún fi ìyàwó tí ọmọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ṣaya…". Zaed kì í sì ṣe ọmọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Hārithah ni bàbá t’ó bí Zaed lọ́mọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìdí tí àwọn aṣíwájú rere (r.ahm) fi sọ pé, nínú gbogbo āyah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé kò sí èyí tí ó lágbára lára Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti fi jíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn t’ó tó āyah: "Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …". Nítorí náà, ẹ jìnnà sí àwọn ìtànkítàn tí àwọn kristiẹni bá ń sọ kiri nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kò sí èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú rẹ̀ àfi èyí tí A sọ sókè yìí. Kíyè sí i, bóyá ni Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (a.s.w.) wà tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām kì í sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀. Ìṣe àti àṣà wọn nìyẹn. Ẹni tí a sì lérò pé àwọn kristiẹni máa pọ́nlé, ohun tí wọ́n tún sọ nípa rẹ̀ ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti fífẹ́ tí ó fẹ́ Zaenab tí Zaed kọ̀ sílẹ̀. Pípè tí àwọn kristiẹni ń pe Ànábì ‘Īsā ni ọmọ Allāhu, pípè tí wọ́n ń pè é ní ọlọ́hun ọmọ, pípè tí wọ́n ń pè é ní olúwa àti olùgbàlà, ó burú yéye ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), gẹ́gẹ́ bí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti ṣe pe àkíyèsí wa sí aburú rẹ̀ nínú sūrah Mọryam; 19:88-95. Àmọ́ àwọn kristiẹni kò fura!
Kò sí láìfí fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nípa ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un. (Ó jẹ́) ìlànà Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. Àti pé àṣẹ Allāhu jẹ́ àkọọ́lẹ̀ kan t’ó gbọ́dọ̀ ṣẹ.
(Kọ́ṣe àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́) àwọn t’ó ń jẹ́ iṣẹ́ Allāhu, tí wọ́n ń páyà Rẹ̀, tí wọn kò sì páyà ẹnì kan àyàfi Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.
(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Ìtúmọ̀ “Ànábì” ni olùgba-wáhàyí, arímìsíígbà tàbí onímìísí. Ìmísí yìí náà sì ni ó máa fi jíṣẹ́ fún àwọn ìjọ rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, kò sí ẹni tí ó lè di Òjíṣẹ́ Allāhu (afìmísíjíṣẹ́) àfi kí ó kọ́kọ́ jẹ́ Ànábì (arímìsíígbà). Ìmísí mímọ́ náà ni ó máa jẹ́ òfin ẹ̀sìn fún onímìísí náà àti ìjọ rẹ̀. Fún wí pé Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni “kātamu-nnabiyyīn” òpin àwọn arímìsíígbà, kò lè sí afìmísíjíṣẹ́ kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” nìyí nínú ẹ̀gbàwá Jubaer ọmọ Mut‘im, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hi, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim). Kíyè sí i, àwọn kan bíi ijọ Ahmadiyyah kò gbàgbọ́ pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n kọ́kọ́ fún “kātamu-nnabiyyīn” ní ìtúmọ̀ t’ó yàtọ̀ sí èròǹgbà Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nínú āyah náà. Wọ́n ní “òrùka àwọn Ànábì” ni ìtúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn”. Lẹ́yìn náà, ìjọ Ahmadiyyah sọ pé, “Ànábì àti Òjíṣẹ́ Allāhu tí ó dìde nínú ìlú Ƙọ̄diyan, nílẹ̀ India tún ni olùdásílẹ́ ìjọ Ahmadiyyah, mirza ghulam Ahmad.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Imam Mahdi tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún ni Mọsīh, ‘Īsā ọmọ Mọryam tí à ń retí lópin ayé.” Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ pé, “Mirza ghulam Ahmad tún sọ àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú ìjọ rẹ̀ di ànábì.”
Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, fúnra Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) àti àwọn Sọhābah (r.ahm) l’ó túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Ìṣìnà pọ́nńbélé ni fún ẹnikẹ́ni láti túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí n̄ǹkan mìíràn. “Òpin àwọn Ànábì” sì ni gbogbo tírà Tafsīr túmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí. Kò sì sí ìyapa-ẹnu láààrin gbogbo àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām lórí títúmọ̀ “kātamu-nnabiyyīn” sí “òpin àwọn Ànábì”. Dandan sì ni kí á gbógun ti ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa ìpanupọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām.
Lẹ́yìn náà, ní ti arákùnrin tí wọ́n ń pè ní mirza ghulam Ahmad, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn wulẹ̀ ni òun. Irọ́ ẹnu rẹ̀ ti pọ̀ jù. Alágbárí pọ́nńbélé sì ni pẹ̀lú. Irú iṣẹ́ aburú tí ṣeeu Ahmada Tijāni ṣe fún ’Islām gẹ́lẹ́ náà ni mirza ghulam Ahmad ṣe. Àwọn méjèèjì ni Pọ́ọ̀lù láààrin àwa mùsùlùmí. Ẹ wo díẹ̀ nínú irọ́ ńlá rẹ̀. Mirza ghulam Ahmad sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, bí ọmọ Mi ló ṣe wà sí Mi." (Tadhkirah, 362) Ṣé Allāhu bímọ ni? Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó ń parọ́ mọ Ọlọ́hun pé Ó bímọ, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) kò bímọ, kò sì sọ ẹnì kan kan di ọmọ Rẹ̀. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Allāhu sọ fún mi ní èdè Lárúbáwá pé, ìwọ wá láti ara Mi; Èmi náà wá láti ara rẹ." (Tadhkirah, ojú ewé 295) Ṣebí àwọn kristiẹni l’ó máa ń sọ pé ọlọ́hun t’ó wá láwòrán ọmọ ni Jésù Kristi! Ṣé ẹ̀ ń rí ìjọra láààrin ìjọ Ahmadiyyah àti àwọn kristiẹni báyìí. Irọ́ mìíràn nìyí láti ẹnu mirza ghulām Ahmad, ó sọ pé: "Nínú ìríran ẹ̀mí, mo rí ara mi pé èmi gan-an ni Allāhu. Mo sì ní ìgbàgbọ́ pé èmi gan-an nìyẹn." (Tadhkirah, 118) Ẹ wo bí ó ṣe sọra rẹ̀ di ọlọ́hun! Lẹ́yìn náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:158 kí ẹ rí bí ó ṣe sọra rẹ̀ di Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún òun àti ìjọ rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Àti òun àti ṣeeu Ahmada Tijāniy, wọ́n wáyé láti wá tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ní ọ̀nà ẹkọrọ lórúkọ ’Islām.
Síwájú sí i, àwọn kan tún sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, kò yẹ fún Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) láti padà wá sáyé mọ́ lópin ayé.” Wọ́n tún sọ pé, “Ìgbàgbọ́ àwọn kristiẹni lásán ni ìgbàgbọ́ nínú ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Kì í ṣe ìgbàgbọ́ ’Islām rárá.”
Èsì: Ní ti àwọn wọ̀nyí, wọ́n gbà pé, Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ni òpin àwọn Ànábì Ọlọ́hun, àmọ́ ìṣòro tiwọn ni pé, wọn kò gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) wà nípò ẹni tí kò ì kú, wọn kò sì gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń padà bọ̀ lópin ayé. Ọ̀gá ìṣòro àwọn wọ̀nyí ni pé, wọ́n wọ́gi lé gbogbo hadīth t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú Bukọ̄riy àti Muslim lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) lópin ayé. Àwọn hadith náà sì pọ̀ púpọ̀, wọ́n fẹsẹ̀ rinlẹ̀, wọn kò sì ní pọ́n-na rárá. Àmọ́ èrò-ọkàn àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn ni pé, àwọn hadīth náà tako āyah tí àwọn ń túmọ̀ sí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń tinú wàhálà kan bọ́ sínú wàhálà mìíràn lórí ọ̀rọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām). Àdánwò kúkú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí Allāhu kó wa yọ. Àmọ́ sá, ẹ lọ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:55 àti sūrah an-Nisā’; 4:157 kí ẹ lè rí àlàyé apayànjẹ lórí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kò ì kú, ó wà ní àyè, ó sì ń padà bọ̀ lópin ayé.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí Allāhu ní ìrántí púpọ̀.
Ẹ ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
(Allāhu) Òun ni Ẹni t’Ó ń kẹ yín, àwọn mọlāika Rẹ̀ (sì ń tọrọ àforíjìn fun yín), nítorí kí Allāhu lè mu yín kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àti pé Ó ń jẹ́ Àṣàkẹ́-ọ̀run fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ìkíni wọn ní ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Rẹ̀ ni "àlàáfíà." Ó sì ti pèsè ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlẹ́ sílẹ̀ dè wọ́n.
Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú, olùkìlọ̀,
olùpèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ àti àtùpà ìmọ́lẹ̀.
Fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú oore àjùlọ ńlá wà fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.
Má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Fi bí wọ́n ṣe ń kó ìnira bá ọ sílẹ̀. Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì ń tó ní Alámòjúútó.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fun yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ t’ó rẹwà.
____________________
Ìjọra wà láààrin āyah yìí àti sūrah al-Baƙọrah; 2:221 àti sūrah an-Nūr; 24:26.
Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún ọ àwọn ìyàwó rẹ̀, tí o fún ní owó-orí wọn, àti àwọn ẹrú nínú àwọn tí Allāhu fí ṣe ìkógun fún ọ àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin bàbá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin ìyá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin ìyá rẹ, àwọn t’ó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ìlú Mọdīnah pẹ̀lú rẹ, àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ó bá fi ara rẹ̀ tọrẹ fún Ànábì, tí Ànábì náà sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Ìwọ nìkan ni (èyí) wà fún, kò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin. A ti mọ ohun tí A ṣe ní ọ̀ran-anyàn fún wọn nípa àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ẹrú wọn. (Èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ó má baà sí láìfí fún ọ. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ohun tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe ní ọ̀ran-anyàn lé àwa lórí nípa ìgbéyàwó àwa ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìwọ̀nyí; ìkíní: Fífẹ́ onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pẹ̀lú àṣẹ àti ìyọ̀ǹda aláṣẹ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:25. Ìkejì: Fífẹ́ obìnrin pẹ̀lú sọ̀daàkí. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:4. Ìkẹta: Òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:3.
Lọ́ra láti súnmọ́ ẹni tí o bá fẹ́ nínú wọn. Fa ẹni tí o bá fẹ́ mọ́ra. Àti pé ẹni kẹ́ni tí o bá tún wá (láti súnmọ́) nínú àwọn tí o ò pín oorun fún, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ (láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ojú wọn tutù ìdùnnú. Wọn kò sì níí banújẹ́. Gbogbo wọn yó sì yọ́nú sí ohunkóhun tí o bá fún wọn. Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Aláfaradà.
____________________
Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nìkan ni èyí wà fún. Mùsùlùmí tí ó ní ìyàwó méjì sí mẹ́rin gbọ́dọ̀ máa pín oorun fún ìkọ̀ọ̀kan àwọn ìyàwó rẹ̀. Kò sí gbọdọ̀ ṣàì pín oorun fún ọ̀kan nínú wọn. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:129.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún ọ, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ (nìkan l’o lè kọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn ìyàwó rẹ). Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Āyah yìí kò ní kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) má ṣe fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní àsìkò tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀, ṣùgbọ́n āyah yìí kọ̀ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) láti yọ èyíkéyìí ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ipò ìyá àwọn onígbàgbọ́ òdodo nípasẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ àfi ìyàwó tí ó bá jẹ́ ẹrú ogun ní ìpìlẹ̀. Ìyá wa ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā) sọ pé: “Òjíṣẹ́ Allāhu kò tí ì kú títí Allāhu fi ṣe àwọn obìnrin ayé ní ẹ̀tọ́ fún un láti fẹ́.” Ìyẹn ni pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fẹ́ ìyàwó lọ́ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Kíyè sí i, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kọ ìyá wa Hafsọh ọmọ ‘Umar sílẹ̀, lẹ́yìn náà ó fẹ́ ẹ padà. Bákan náà, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbèrò láti kọ ìyá wa Saodah sílẹ̀. Èyí sì ni ó ṣokùnfà tí Saodah (rọdiyallāhu 'anhā) fi yọ̀ǹda ọjọ́ tirẹ̀ fún ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā). Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí. (at-Tọbariy). Nítorí náà, kí Ànábì fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ láì ní ẹnu àlà, láì sì gbọdọ̀ tìtorí èyí kọ ọ̀kan sílẹ̀, àfi ẹrú ogun, èyí tún jẹ́ n̄ǹkan ẹ̀ṣà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi ṣà á lẹ́ṣà. Ìdí ni pé, òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Tí òǹkà ìyàwó Mùsùlùmí bá sì pé mẹ́rin, mùsùlùmí lè kọ ọ̀kan sílẹ̀ láti lè fi òmíràn jìrọ̀ rẹ̀, ìyẹn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:3 àti 20-21.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe wọ àwọn inú ilé Ànábì àfi tí wọ́n bá yọ̀ǹda fun yín láti wọlé jẹun láì níí jẹ́ ẹni tí yóò máa retí kí oúnjẹ jinná, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pè yín (fún oúnjẹ) ẹ wọ inú ilé nígbà náà. Nígbà tí ẹ bá sì jẹun tán, ẹ túká, ẹ má ṣe jókòó kalẹ̀ tira yin fún ọ̀rọ̀ kan mọ́ (nínú ilé rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn ń kó ìnira bá Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì ń tijú yín. Allāhu kò sì níí tijú níbi òdodo. Nígbà tí ẹ bá sì fẹ́ bèèrè n̄ǹkan ní ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó rẹ̀, ẹ bèèrè rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wọn ní ẹ̀yìn gàgá. Ìyẹn jẹ́ àfọ̀mọ́ jùlọ fún ọkàn yín àti ọkàn wọn. Kò tọ́ fun yín láti kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu. (Kò sì tọ́ fun yín) láti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ láéláé. Dájúdájú ìyẹn jẹ́ n̄ǹkan ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.
Tí ẹ bá ṣàfi hàn kiní kan tàbí ẹ fi pamọ́, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ìyàwó Ànábì nípa àwọn bàbá wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn àti àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn àti àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn àti àwọn ẹrúkùnrin wọn (láti wọlé tì wọ́n.) Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú Allāhu àti àwọn mọlāika Rẹ̀ ń kẹ́ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tọrọ ìkẹ́ fún un, kí ẹ sì kí i ní kíkí àlàáfíà.
____________________
Níkété tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ āyah yìí kalẹ̀ ni àwọn Sọhābah (r.ahm) bèèrè ohun tí àwọn náà yóò fi máa tọrọ ìkẹ́ fún Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì kọ́ wọn ní sọlātu ’Ibrọ̄hīmiyyah. Ẹ̀gbàwá kan nìyí:
اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ اللَّهُمَّ بَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ.
Allahummọ sọlli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ sọllaeta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd. Allahummọ bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin kamọ̄ bārọkta ‘alā āli ’Ibrọ̄hīmọ ’innaka Hamīdun Mọjīd. (Bukọ̄riy àti Muslim)
Gbólóhùn wọ̀nyí tún tọ súnà; “sọlla-llāhu ‘aleehi wa sallam” tàbí “‘aleehi sọlātun wa salām.” Kíyè sí i, kò sí aburú níbi kí mùsùlùmí máa sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ kí ó sì fi gbólóhùn kan ní ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ tọrọ ìkẹ́ àti ọlà fún Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tí ì dáràn nítorí pé, àwọn Sọhābah náa (r.ahm) máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn àáfà sunnah ṣe ń ṣe asọlātu fún Ànábì nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣaájú nínú àwọn tírà wọn. Kò sí aburú nínú èyí rárá. Ṣùgbọ́n mùsùlùmí yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìhun asọlātu dáràn tí ó bá fi lè kó sínú ọ̀kan nínú àwọn n̄ǹkan mẹ́fà kan. Ìkíní: Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí òfin àti àdìsọ́kàn ’Islām nínú àwọn gbólóhùn asọlātu náà. Ìkejì: Sísọ gbólóhùn asọlātu yẹn gan-angan di ìlànà tí wọn yóò máa pèpè sí, tí irúfẹ́ gbólóhùn náà yóò fi wá dà bí ẹni pé hadīth kan l’ó gbà á wá, tí kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ìkẹta: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ òǹkà kan tàbí àsìkò kan tàbí ọjọ́ kan ní pàtó fún ṣíṣe irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà. Ìkẹrin: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ ìlànà kan ní pàtó fún ṣíṣe irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà, bí kí wọ́n wí pé ẹnì kan kò gbọdọ̀ kà á àfi pẹ̀lú àlùwàlá. Ìkarùn-ún: Ṣíṣe àgbékalẹ̀ láádá fún irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà, tí èyí yó sì bí níní àdìsọ́kàn nípa àwọn láádá àgbélẹ̀rọ náà. Ìkẹfà: Kíka irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà kún ìmísí mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) tàbí ṣíṣe àfitì irúfẹ́ asọlātu àdáhun náà sí ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ti irọ́. Àwọn n̄ǹkan mẹ́fẹ̀ẹ̀fà wọ̀nyí l’ó ṣe àkóbá ńlá fún àwọn asọlātu àdáhun kan bíi sọlātul-fātih, sọlātu tunjīnā, sọlātul-gaebiyyah, sọlātu rọf‘il-’a‘mọ̄l, sọlātul-kamsah, jaoharatul-kamọ̄l, dalā’ilul-kaerāt, sọlawātul-kibrītu al-’ahmọr àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn onisūfi ni wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ àwọn asọlātu aburú wọ̀nyẹn sínú ẹ̀sìn. Ìṣìnà àti òfò pọ́nńbélé sì ni gbogbo wọn.
Dájúdájú àwọn t’ó ń fi ìnira kan Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn nílé ayé àti ní ọ̀run. Ó sì ti pèsè ìyà t’ó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ dè wọ́n.
____________________
Ọ̀nà tí ẹ̀dá ń gbà fi ìnira kan Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìwọ̀nyí; àìgbàgbọ́ nínú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), ìṣẹbọ sí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn Rẹ̀, ṣíṣe àfitì ìyàwó àti ọmọ bíbí tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, pípa irọ́ mọ́ Ọn àti bíbú ìgbà, yíya àwòrán n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kíyè sí i, fífi ìnira kan Allāhu, Ọbá tí kò sí ìnira fún, kò ní ìtúmọ̀ kan tayọ pé ẹ̀dá ń wá ìnira ọ̀run fún ẹ̀mí ara rẹ̀.
Àwọn t’ó ń fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin nípa n̄ǹkan tí wọn kò ṣe, dájúdájú wọ́n ti ru ẹrù (ọ̀ràn) ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Ìwọ Ànábì sọ fún àwọn ìyàwó rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ òdodo pé kí wọ́n máa gbé àwọn aṣọ jilbāb wọn wọ̀ sí ara wọn bámúbámú. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti fi mọ̀ wọ́n (ní olùbẹ̀rù Allāhu). Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò níí fi ìnira kàn wọ́n. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí, àti àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn túlétúlé nínú ìlú Mọdīnah kò bá jáwọ́ (níbi aburú), dájúdájú A máa dẹ ọ́ sí wọn, (o sì máa borí wọn). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí bá ọ gbé àdúgbò pọ̀ mọ́ àfi fún ìgbà díẹ̀.
Wọ́n di ẹni-ìṣẹ́bilé níbikíbi tí ọwọ́ bá ti bà wọ́n; wọ́n máa mú wọn, wọ́n sì máa pa wọ́n tààrà.
(Ó jẹ́) ìṣe Allāhu lórí àwọn t’ó ti lọ ṣíwájú. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Allāhu.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hijr; 15:13
Àwọn ènìyàn ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo ni ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà. Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!”
Dájúdájú Allāhu ṣẹ́bi le àwọn aláìgbàgbọ́. Ó sì pèsè Iná t’ó ń jò fòfò sílẹ̀ dè wọ́n.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé; wọn kò níí rí olùṣọ́ tàbí alárànṣe kan.
Ní ọjọ́ tí A óò yí ojú wọn padà nínú Iná, wọn yó sì wí pé: “Yéè! Àwa ìbá tẹ̀lé ti Allāhu, àwa ìbá sì tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́.”
Wọ́n wí pé: “Olúwa wa! Dájúdájú àwa tẹ̀lé àwọn aṣíwájú wa àti àwọn àgbààgbà wa. Wọ́n sì ṣì wá lọ́nà.
Olúwa wa! Fún wọn ní ìlọ́po méjì nínú ìyà. Kí O sì ṣẹ́bi lé wọn ní ìṣẹ́bi t’ó tóbi.”
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe dà bí àwọn t’ó fi ìnira kan (Ànábì) Mūsā. Allāhu sì ṣàfọ̀mọ́ rẹ̀ nínú ohun tí wọ́n wí. Ó sì jẹ́ ẹni abiyì lọ́dọ̀ Allāhu.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì sọ ọ̀rọ̀ òdodo.
(Allāhu) máa ṣàtúnṣe àwọn iṣẹ́ yín fun yín, Ó sì máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Àti pé ẹni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ó kúkú ti jèrè ní èrèǹjẹ ńlá.
Dájúdájú Àwa fi iṣẹ́ láádá lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan.
____________________
Àgbàfipamọ́ ni ìtúmọ̀ “ ’amọ̄nah”. Èyí sì túmọ̀ sí ohun tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́ fún ṣíṣọ́ àti àmójútó. Ohun tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) gbé lé wa lọ́wọ́ tí a óò máa ṣọ́, tí a óò máa ṣe àmójútó rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀sìn Rẹ̀, ’Islām. Allāhu sì gbé ẹ̀sìn náà kalẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀san. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá rí i ṣe gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe gbé e kalẹ̀, ó máa gba láádá lórí rẹ̀. Àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àpáta gbà láti máa ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu, àmọ́ wọ́n ní àwọn kò bùkátà sí láádá. Ènìyàn tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá tán, ó di wàhálà sí wọn lọ́rùn nítorí pé, wọn kò mọ̀ pé tí ṣíṣe n̄ǹkan bá la láádá lọ, àìṣe rẹ̀ máa la ìyà lọ. Ìbá ṣuwọ̀n fún ènìyàn àti àlùjànnú láti ṣe ẹ̀sìn láì retí láádà kan tayọ ìtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo.
(Ènìyàn tẹ́rí gba ẹ̀sìn àṣegbaláádá) nítorí kí Allāhu lè fi ìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn ọ̀sẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin àti nítorí kí Allāhu lè gba ìronúpìwàdà fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.