surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.
(al-Ƙur’ān) fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nítorí kí (Ànábì) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí (Ànábì) lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn t’ó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);
Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.
Àti nítorí kí (Ànábì) lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn t’ó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”
Kò sí ìmọ̀ fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ t’ó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́.
Nítorí náà, nítorí kí ni o ṣe máa fi ìbànújẹ́ para rẹ lórí ìgbésẹ̀ wọn pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí gbọ́.
Dájúdájú Àwa ṣe ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún ará-ayé nítorí kí Á lè dán wọn wò (pé) èwo nínú wọn l’ó máa dára jùlọ níbi iṣẹ́ ṣíṣe (fún ẹ̀sìn).
Àti pé dájúdájú Àwa máa sọ n̄ǹkan tí ń bẹ lórí (ilẹ̀) di erùpẹ̀ gbígbẹ tí kò níí hu irúgbìn.
Tàbí o lérò pé dájúdájú àwọn ará inú ihò àpáta àti wàláhà orúkọ wọn jẹ́ èèmọ̀ kan nínú àwọn àmì Wa?
Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kóra wọn sínú ihò àpáta, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, kí O ṣe ìmọ̀nà ní ìrọ̀rùn fún wa nínú ọ̀rọ̀ wa.”
A kùn wọ́n l’óorun àsùnpiyè nínú ihò àpáta f’ọ́dún gbọọrọ.
Lẹ́yìn náà, A gbé wọn dìde nítorí kí Á lè ṣàfi hàn èwo nínú ìjọ méjèèjì l’ó mọ gbèdéke òǹkà ọdún t’ó lò (nínú ihò àpáta náà).
Àwa ń sọ ìròyìn wọn fún ọ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n. Wọ́n gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. A sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn.
A sì kì wọ́n lọ́kàn nígbà tí wọ́n dìde, tí wọ́n sọ pé: "Olúwa wa ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. A ò sì níí pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀. (Tí a bá pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀) dájúdájú a ti pa irọ́ nìyẹn.
Àwọn ìjọ wa wọ̀nyí sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀rí t’ó yanjú wá nípa wọn? Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni t’ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?"
(Àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fúnra wọn pé:) nígbà tí ẹ bá yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ sì wá ibùgbé sínú ihò àpáta, Olúwa yín yóò tẹ́ nínú ìkẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ fun yín. Ó sì máa ṣe ọ̀rọ̀ yín ní ìrọ̀rùn fun yín.
O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ihò wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ihò àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un.
O máa lérò pé wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ojú oorun ni wọ́n sì wà. A sì ń yí wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ padà sọ́tùn-ún sósì. Ajá wọn sì na apá rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀ ní gbàgéde àpáta. Tí ó bá jẹ́ pé o yọjú wò wọ́n ni, ìwọ ìbá pẹ̀yìn dà láti họ fún wọn, ìwọ ìbá sì kún fún ìbẹ̀rù-bojo láti ara wọn.
Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìdajì ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú l’ó mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fun yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín.
(Nítorí pé) dájúdájú tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa yín, wọn yóò jù yín lókò tàbí kí wọ́n da yín padà sínú ẹ̀sìn wọn. (Tí ó bá sì fi rí bẹ́ẹ̀) ẹ ò níí jèrè mọ́ láéláé nìyẹn.
Báyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: "Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn nímọ̀ jùlọ nípa wọn." Àwọn t’ó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”
____________________
Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah (r.ah), ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn tí ó kú sórí rẹ̀ pé: “Ibi dandan Allāhu ń bẹ lórí àwọn yẹhudi àti nasara (nítorí pé) wọ́n sọ sàréè àwọn Ànábì di ilé ìjọ́sìn.” ‘Ā’iṣah sọ pé: “Tí kì í bá ṣe nítorí èyí ni, wọn ìbá ṣe àfihàn ojú sàréè rẹ̀ ṣùgbọ́n dájúdájú ẹ̀rù ń bà wọ́n pé kí wọ́n má sọ sàréè rẹ̀ di mọ́sálásí. (Muslim) Kíyè sí i, ní ìpìlẹ̀ wọ́n sin òkú Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sí ibi tí ó kú sí nínú yàrá ìyá wa, ‘Ā’iṣah (r.ah). Ní ọjọ́ náà sì nìyí wọ́n kọ́ ilé Ànábì papọ̀ mọ́ mọ́sálásí rẹ̀ ni. Ilé rẹ̀ sì bọ́ sí ọwọ́ iwájú mọ́sálásí. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín fífẹ̀ tí wọ́n padà fẹ mọ́sálásí rẹ̀ lójú sí ọ̀tún, òsì, ẹ̀yìn àti iwájú, wọn kò sì fẹ́ wú òkú Ànábì àti òkú Abu-Bakr àti òkú ‘Umar jáde kúrò nínú sàréè, èyí l’ó ṣokùnfà tí ilé náà fi bọ́ sínú mọ́sálásí. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mọ́sálásí, ní ìbámu sí hadīth ìya wa ‘Ā’iṣah tí a mú wá ṣíwájú. Èyí tí ó sì ṣẹlẹ̀ sí mọ́sálásì Òjísẹ́ yìí náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) yóò padà ní àtúnṣe lọ́jọ́ iwájú ’in ṣā Allāhu, nítorí pé èèwọ̀ ni kí sàréè bọ́ sínú mọ́sálásí láì la àyàfi lọ!
Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: "Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹfà wọn." Ọ̀rọ̀ t’ó pamọ́ fún wọn (ni wọ́n ń sọ). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹjọ wọn.” Sọ pé: "Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) t’ó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn."
Má ṣe sọ nípa kiní kan pé: “Dájúdájú èmi yóò ṣe ìyẹn ní ọ̀la.”
Àyàfi (kí o fi kún un pé) "tí Allāhu bá fẹ́." Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”
____________________
Okùnfà āyah yìí ni pé, nígbà tí àwọn yẹhudi wá bi Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) léèrè nípa ọ̀rọ̀ àwọn ará inú ihò àpáta pẹ̀lú èròǹgbà wọn pé tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní ti òdodo, ó yẹ kí ó nímọ̀ nípa wọn, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ ìtàn wọn ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú èròǹgbà pé Allāhu á ti fi ìmísí nípa wọn ránṣẹ́ sí òun. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò sì sọ fún àwọn yẹhudi náà pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Àmọ́ àì sọ bẹ́ẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ọjọ́ àdéhùn t’ó ṣe fún wọn yẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ́ Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ní ẹ̀kọ́ pé, ó yẹ kí ó fi kún un fún wọn pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Lẹ́yìn náà, ìmísí nípa àwọn ará inú ihò àpáta dé. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì tún jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé, àwọn ìtàn ìmọ̀nà mìíràn wà tó lè mú kí àwọn yẹhudi wọ̀nyẹn mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ní í ṣe. Tí wọ́n bá ṣetán láti tẹ̀lé ìmọ̀nà tí Ànábì mú wá, Allāhu tún lè sọ àwọn ìtàn t’ó lọ́jọ́ lórí ju ti àwọn ará inú ihò àpáta, t’ó sì tún lágbára jùlọ láti fún àwọn ọkàn ní ìmọ̀nà. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì kúkú ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé, àwọn ọ̀rọ̀ ìgbà-àwá-sẹ̀ bíi ìtàn ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìtàn àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun t’ó ti ré kọjá lọ tí kò sí déètì rẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan kan. Àmọ́ sá, olórí-kunkun ni àwọn yẹhudi; wọ́n gbọ àwọn ìyáláàyá ìtàn òdodo náà, wọ́n sì gbúnrí láti padà sínú ’Islām.
Wọ́n wà nínú ihò àpáta wọn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún. Wọ́n tún lo àlékún ọdún mẹ́sàn-án.
Sọ pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n lò (nínú ihò àpáta). TiRẹ̀ ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kì ni kò rí tán, kì sí ni kò gbọ́ tán! Kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Kò sì fi ẹnì kan ṣe akẹgbẹ́ nínú ìdájọ́ Rẹ̀.”
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ó lè yí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà. Ìwọ kò sì lè rí ibùsásí kan yàtọ̀ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn t’ó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù.
____________________
Àwọn onisūfi lérò pé āyah yìí gbè fún àwọn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al- ’An‘ām; 6:52 fún àgbọ́yé āyah yìí.
Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan t’ó dà bí òjé idẹ gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ó burú ní mímu. Ó sì burú ní ibùkójọ.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ráre.
Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn yóò máa fi góòlù ọrùn ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ó dára ní ẹ̀san. Ó sì dára ní ibùkójọ.
Fi àwọn ọkùnrin méjì kan ṣe àpẹẹrẹ fún wọn; A fún ọ̀kan nínú wọn ní ọgbà èso àjàrà méjì. A sì fi àwọn igi dàbínù yí wọn ká. A tún fi àwọn igi eléso là wọ́n láààrin.
Ìkíní kejì àwọn oko méjèèjì ń so èso wọn. Àwọn èso rẹ̀ kì í pẹ̀ dín. A sì jẹ́ kí odò ṣàn kọjá láààrin oko méjèèjì.
Ó ní èso (sẹ́). Ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń bá a jiyàn (báyìí) pé: “Èmi ní dúkìá lọ́wọ́ jù ọ́ lọ. Mo tún lérò lẹ́yìn jùlọ.”
Ó wọ inú oko rẹ̀ lọ, ó sì ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé.
Èmi kò sì lérò pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí t’ó dára ju èyí lọ.”
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ó ń jà á níyàn (báyìí) pé: “Ṣé o máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà, láti inú àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ́ ní ọkùnrin t’ó pé ní ẹ̀dá.
Ṣùgbọ́n ní tèmi, Olúwa mi, Òun ni Allāhu. Èmi kò sì níí sọ ẹnì kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.
Nígbà tí o wọ inú ọgbà oko rẹ, kí ni kò mú ọ sọ pé: "Ohun tí Allāhu bá fẹ́! Kò sí agbára kan bí kò ṣe pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí o bá sì rí mi pé mo kéré sí ọ ní dúkìá àti ọmọ,
ó súnmọ́ kí Olúwa mi fún èmi náà ní ọgbà oko tí ó máa dára ju ọgbà oko tìrẹ. (Ó sì súnmọ́) kí Ó sọ ìyà kan kalẹ̀ sínú ọgbà oko rẹ láti sánmọ̀; ó sì máa di ilẹ̀ aṣálẹ̀.
Tàbí kí omi rẹ̀ gbẹ. O ò sì níí lè wá omi kàn."
Wọ́n sì pa èso rẹ̀ run pátápátá. Ó sì di ẹni t’ó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́ nípa ohun tí ó ti ná sórí rẹ̀. Ó ti parun tòrùlé-tòrùlé rẹ̀. Ó sì ń wí pé: “Yéè! Èmi ìbá tí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.”
Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
Níbẹ̀ yẹn, ti Allāhu, Ọba Òdodo ni ìjọba. Ó lóore jùlọ ní ẹ̀san, Ó sì lóore jùlọ ní ìkángun (rere).
Ṣe àkàwé ilé ayé fún wọn; ó dà bí omi tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀. Lẹ́yìn náà, ó ròpọ̀ mọ́ irúgbìn ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (irúgbìn) di gbígbẹ, tí atẹ́gùn ń fọ́nká. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé ni dúkìá àti àwọn ọmọ. Àwọn iṣẹ́ rere t’ó máa wà títí láéláé lóore jùlọ ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, ó sì lóore jùlọ ní ìrètí.
(Rántí) ọjọ́ tí A máa mú àwọn àpáta rìn lọ. O sì máa rí ilẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. A máa kó wọn jọ. A ò sì níí fi ẹnì kan sílẹ̀ nínú wọn.
Wọn yó sì kó wọn wá síwájú Olúwa rẹ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹ ti wá bá Wa (báyìí) gẹ́gẹ́ bí A ṣe da yín nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́ ẹ sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé A ò níí mú ọjọ́ àdéhùn ṣẹ fun yín.
A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: “Ègbé wa! Irú ìwé wo ni èyí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?” Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan.
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì ṣàfojúdi sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ t’ó burú ni fún àwọn alábòsí.
N̄g ò pè wọ́n sí dídá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti dídá àwọn gan-an alára. N̄g ò sì mú àwọn aṣinilọ́nà ní olùrànlọ́wọ́.
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ pe àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n).” Wọ́n pè wọ́n. Wọn kò sì dá wọn lóhùn. A sì ti fi kòtò ìparun sáààrin wọn.
Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rí Iná. Wọ́n sì mọ̀ pé àwọn yóò kó sínú rẹ̀. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan nínú rẹ̀.
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ alátakò púpọ̀ ju ohunkóhun lọ.
Kò sí ohun t’ó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun t’ó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú.
Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́.
Ta sì l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n sínú ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé.
Olúwa rẹ, Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́, tí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀.
Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní àdéhùn fún ìparun wọn.
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "N̄g ò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti pàdé tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún."
Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjì ti pàdé, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì bọ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀ (tí ó ti di) poro ọ̀nà nínú odò.
Nígbà tí àwọn méjèèjì ré kọjá (ibi tí odò méjì ti pàdé), ó sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Fún wa ní oúnjẹ ọ̀sán wa. Dájúdájú a ti ko wàhálà nínú ìrìn-àjò wa yìí."
(Ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀) sọ pé: "Sọ (ohun t’ó ṣẹlẹ̀) fún mi, nígbà tí a wà níbi àpáta! Dájúdájú mo ti gbàgbé ẹja náà (síbẹ̀)? Kò sì sí ohun tí ó mú mi gbàgbé rẹ̀ bí kò ṣe Èṣù, tí kò jẹ́ kí n̄g rántí rẹ̀. (Ẹja náà) sì ti mú ọ̀nà rẹ̀ tọ̀ lọ nínú odò pẹ̀lú ìyanu."
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.” Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ṣe tọ̀ ọ́ wá.
Àwọn méjèèjì sì rí ẹrúsìn kan nínú àwọn ẹrúsìn Wa, tí A fún ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. A sì fún un ní ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Wa.
(Ànábì) Mūsā sọ fún un pé: “Ṣé kí n̄g tẹ̀lé ọ nítorí kí o lè kọ́ mi nínú ohun tí Wọ́n fi mọ̀ ọ́ ní ìmọ̀nà.”
____________________
Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lérò pé lílọ tí Ànábì Mūsā lọ sí ọ̀dọ̀ Kidr túmọ̀ sí pé Kidr lóore ju Ànábì Mūsā (a.s.w.) lọ lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Tí Kidr bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Allāhu “waliyyu-llāh”, ipò jíjẹ́ Ànábì jẹ́ oore àjùlọ lórí ipò jíjẹ́ waliyyu. Tí àwọn méjèèjì bá sí dìjọ jẹ́ Ànábì, fífún tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fún Ànábì Mūsā ní Tírà tún jẹ́ oore àjùlọ mìíràn lórí Kidr. Àti pé Ànábì Mūsā (a.s.w.) tún ní oore àjùlọ mìíràn nípa bí ó tún ṣe jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn Òjíṣẹ́ tí a mọ̀ sí àwọn Onípinnú nínú àwọn Òjíṣẹ́ " ’ulul-‘azmi minar-Rusul" (a.s.w.).
Síwájú sí i, gbogbo mùsùlùmí ni waliyyu-llāh, àmọ́ bí mùsùlùmí kọ̀ọ̀kan bá ṣe súnmọ́ Allāhu tó, nínú ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa lílo òfin ẹ̀sìn ’Islām, l’ó máa ṣ’òdíwọ̀n ìsúnmọ́ tí ń bẹ láààrin Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) àti ẹrúsìn Rẹ̀ náà. Ṣíwájú Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Allāhu fún àwọn mùsùlùmí kan ní àǹfààní láti rí ìṣípayá mímọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Lára àwọn tí Allāhu ṣe èyí fún ni ìyá Mūsā, Mọryam ìya ‘Īsā, Thul-Ƙọrneen àti Kidr. Ìṣípayá mímọ́ tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn yìí kò sọ wọ́n di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́. Àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ tí ìṣípayá mímọ́ náà mú wá fún wọn, bí àpẹẹrẹ, ìya Mūsā (r.ah) kò ṣàdédé gbé ọmọ rẹ̀, Ànábì Mūsā jù sínú odò, tí kì í bá ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìṣípayá mímọ́ tí Ó fi ránṣẹ́ sí i. Bákan náà, àwọn n̄ǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí Kidr dánwò lójú Ànábì Mūsā, ìbá tí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí kì í bá ṣe pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àǹfààní wọ̀nyí wà fún àwọn t’ó ṣíwájú Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), ṣùgbọ́n kò sí fún ìjọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Èyí ni pé, lásìkò yìí ẹnì kan kan kò gbọdọ̀ lo òfin kan tí ó yapa sí òfin tí Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mú wá, kí ó wí pé Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) l’Ó fún òun náà ní ìṣípayá mímọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́ọ́rọ́wọ́ ni onítọ̀ún yóò jáde kúrò nínú ipò jíjẹ́ mùsùlùmí. Ọ̀wọ́ ẹnì kan ṣoṣo tí Allāhu ìbá fún ní ìṣípayá mímọ́ nínú ìjọ Ànábì wa (sollalāhu 'alayhi wa sallam), òun ni ’Amīrul-mu’minīn, ‘Umar bun Kattọ̄b (r.a). Èyí wà ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tí ó sọ pé: “Dájúdájú ṣíwájú yín nínú àwọn ọmọ ‘Isrọ̄’īl, ni a ti rí àwọn ènìyàn kan tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (ní ti ìṣípayá mímọ́), wọn kì í sì ṣe Ànábì. Tí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan nínú wọn máa wà nínú ìjọ mi ni, ‘Umar ni ìbá jẹ́." [Al-Bukāriy; bāb mọnāƙib ‘Umọr] Bákan náà, ohun tí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) kọ́ lọ́dọ̀ Kidr kò túmọ̀ sí pé ó kọ́ ọ fún lílò láààrin ìjọ rẹ̀. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti fún Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ní òfin àti ìlànà tirẹ̀ nínú ’Islām, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún un láti lo òfin àti ìlànà tí Allāhu fún Kidr, yálà Kidr jẹ́ waliyyu tàbí Ànábì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Hajj; 22:67. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fẹ́ kọ́ Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nípa ìrìn-àjò rẹ̀ sọ́dọ̀ Kidr ni pé, ìmọ̀ nípa òfin àti ìlànà ’Islām, èyí tí Allāhu fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra wọn díẹ̀díẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Ànábì kan sí òmíràn. Àti pé kò rọrùn fún ẹnì kan nínú wọn láti jẹ́ alámọ̀tán ohun gbogbo. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) nìkan ṣoṣo sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
(Kidr) sọ pé: “Dájúdájú o ò lè ṣe sùúrù pẹ̀lú mi.
Àti pé báwo ni o ṣe lè ṣe sùúrù lórí ohun tí o ò fi ìmọ̀ rọkiri ká rẹ̀?”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí Allāhu bá fẹ́, ó máa bá mi ní onísùúrù. Mi ò sì níí yapa àṣẹ rẹ.”
(Kidr) sọ pé: “Tí o bá tẹ̀lé mi, má ṣe bi mí ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan kan títí mo fi máa kọ́kọ́ mú ìrántí wá fún ọ nípa rẹ̀.”
Nítorí náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi wọ inú ọkọ̀ ojú-omi. (Kidr) sì dá ọkọ̀ náà lu. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe dá a lu, (ṣé) kí àwọn èrò rẹ̀ lè tẹ̀ rì ni? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú kan!”
(Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé dájúdájú o ò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Má ṣe bá mi wí nípa ohun tí mo gbàgbé. Má sì ṣe kó ìnira bá mi nínú ọ̀rọ̀ (ìrìn-àjò) mi (pẹ̀lú rẹ).”
Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi pàdé ọmọdékùnrin kan. (Kidr) sì pa á. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) mímọ́, láì gba ẹ̀mí? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan t’ó burú o.”
(Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé dájúdájú o ò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí mo bá tún bi ọ́ nípa kiní kan lẹ́yìn rẹ̀, má ṣe bá mi rìn mọ́. Dájúdájú o ti mú àwáwí dé òpin lọ́dọ̀ mi.”
Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú kan. Wọ́n tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sì kọ̀ láti ṣe wọ́n ní àlejò. Àwọn méjèèjì sì bá ògiri kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ wó. (Kidr) sì gbé e dìde. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé o bá fẹ́, o ò bá sì gba owó-ọ̀yà lórí rẹ̀.”
(Kidr) sọ pé: “Èyí ni òpínyà láààrin èmi àti ìwọ. Mo sì máa fún ọ ní ìtúmọ̀ ohun tí o ò lè ṣe sùúrù lórí rẹ̀.”
Ní ti ọkọ̀ ojú-omi, ó jẹ́ ti àwọn mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí omi. Mo sì fẹ́ láti fi àlébù kàn án (nítorí pé) ọba kan wà níwájú wọn t’ó ń gba gbogbo ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú ipá.
Ní ti ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. A sì ń bẹ̀rù pé kí ó màa kó ìtayọ ẹnu-àlà àti àìgbàgbọ́ bá àwọn méjèèjì.
____________________
Ìyẹn ni pé, òbí lè tìtorí ìfẹ́ ọmọ ṣẹ Allāhu, ìyẹn nígbà tí òbí bá ń pọ̀n lẹ́yìn ọmọ burúkú.
Nítorí náà, A fẹ́ kí Olúwa àwọn méjèèjì pààrọ̀ rẹ̀ fún wọn pẹ̀lú (èyí) t’ó lóore jù ú lọ ní ti mímọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀) àti (èyí) t’ó súnmọ́ jù ú lọ ní ti ìkẹ́.
Nípa ti ògiri, ó jẹ́ ti àwọn ọmọdékùnrin, ọmọ òrukàn méjì kan nínú ìlú náà. Àpótí-ọrọ̀ kan sì ń bẹ fún àwọn méjèèjì lábẹ́ ògiri náà. Bàbá àwọn méjèèjì sì jẹ́ ẹni rere. Nítorí náà, Olúwa rẹ fẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà (bá dúkìá náà), kí wọ́n sì hú dúkìá wọn jáde (kí ó lè jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Mi ò dá a ṣe láti ọ̀dọ̀ ara mi; (Allāhu l’Ó pa mí láṣẹ rẹ̀). Ìyẹn ni ìtúmọ̀ ohun tí o ò lè ṣe sùúrù fún.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Thul-Ƙọrneen. Sọ pé: “Mo máa mú ọ̀rọ̀ ìrántí wá fun yín nípa rẹ̀.”
Dájúdájú Àwa fún un ní ipò lórí ilẹ̀. A sì fún un ní ọ̀nà t’ó lè gbà ṣe gbogbo n̄ǹkan (tí ó bá fẹ́ ṣe).
Nítorí náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
títí ó fi dé ibùwọ̀ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń wọ̀ sínú ìṣẹ́lẹ̀rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dúdú kan. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níbẹ̀. A sọ fún un pé: “Thul-Ƙọrneen, yálà kí o jẹ wọ́n níyà tàbí kí o mú ohun rere jáde lára wọn.”
(Allāhu) sọ pé: “Ní ti ẹni tí ó bá ṣàbòsí, láìpẹ́ A máa jẹ ẹ́ níyà. Lẹ́yìn náà, wọn máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì máa jẹ ẹ́ níyà t’ó burú.
Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni ẹ̀san rere. A ó sì sọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn fún un nínú àṣẹ Wa.”
Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
títí ó fi dé ibùyọ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń yọ lórí àwọn ènìyàn kan, tí A kò fún ní gàgá (ààbò) kan níbi òòrùn.
Báyẹn ni (Thul-Ƙọrneen ṣe ń tẹ̀ síwájú). Dájúdájú A rọkiriká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀.
Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
títí ó fi dé ààrin àpáta méjì. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níwájú rẹ̀. Wọn kò sì fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan (nínú èdè mìíràn).
Wọ́n sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, dájúdájú (ìran) Ya’jūj àti Ma’jūj ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ṣé kí á fún ọ ní owó-òde nítorí kí o lè bá wa mọ odi kan sáààrin àwa àti àwọn?”
Ó sọ pé: "Ohun tí Olúwa mi fún mi nínú ipò lóore jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi agbára ràn mí lọ́wọ́ ni nítorí kí n̄g lè mọ odi sáààrin ẹ̀yin àti àwọn.
Ẹ máa fún mi ni ègígé irin títí di ìgbà tí ó fi máa bá ẹ̀gbẹ́ àpáta méjèèjì dọ́gba." Ó sọ pé: "Ẹ máa fẹ́ atẹ́gùn ẹwìrì (sí i lára) títí di ìgbà tí ó máa (pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí) iná." Ó sọ pé: "Ẹ mu idẹ wá fún mi kí n̄g yọ́ ọ lé e lórí."
Nítorí náà, wọn kò lè gùn ún, wọn kò sì lè dá a lu.
Ó sọ pé: “Èyí ni ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi. Nígbà tí àdéhùn Olúwa mi bá dé, (Allāhu) yó sì sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àdéhùn Olúwa mi sì jẹ́ òdodo.”
A máa fi àwọn (ènìyàn àti àlùjànnú) sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí apá kan wọn yó sì máa dàpọ̀ mọ́ apá kan. Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A ó sì kó gbogbo wọn jọ papọ̀ pátápátá.
Ní ọjọ́ yẹn, A ó sì fi iná Jahanamọ han àwọn aláìgbàgbọ́ kedere.
(Àwọn ni) àwọn tí ojú wọn wà nínú èbìbò nípa ìrántí Mi. Wọn kò sì lè gbọ́rọ̀.
Ṣé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní olùrànlọ́wọ́ lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Sọ pé: “Ṣé kí Á fun yín ní ìró àwọn ẹni òfò jùlọ nípa iṣẹ́ (ọwọ́ wọn)?
(Àwọn ni) àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé, (àmọ́ tí) wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ń ṣe iṣẹ́ rere.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn àti ìpàdé Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ wọn sì bàjẹ́. Nítorí náà, A ò níí jẹ́ kí wọ́n jámọ́ n̄ǹkan kan lórí ìwọ̀n ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Jahanamọ, ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́, wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi di oníyẹ̀yẹ́.
Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn ọgbà Firdaos ti wà fún wọn ní ibùdésí.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí fẹ́ kúrò nínú rẹ̀.
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ibúdò jẹ́ tàdáà fún àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi, ibúdò kúkú máa tán ṣíwájú kí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi tó tán, kódà kí Á tún mú (ibúdò) irú rẹ̀ wá ní àlékún.”
Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀.”