سورة الواقعة

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura الواقعة ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 1
Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,
Verse 2
- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-E4983
Verse 3
ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).
Verse 4
Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,
Verse 5
àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,
Verse 6
- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù - E4987
Verse 7
ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.
____________________
Àwọn kristiẹni lérò pé āyah t’ó pín ẹ̀dá sí mẹ́ta ní ọjọ́ Àjíǹde tako āyah t’ó pín wọn sí ìjọ méjì.
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin wọn. Nínú sūrah yìí, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ pé oríṣi ìjọ mẹ́ta ni àwọn ẹ̀dá máa pín sí ní ọjọ́ Àjíǹde. Ìjọ ọ̀tún, ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18-19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6-8, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run, ìjọ ọ̀tún àti ìjọ òsì nítorí pé, Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ nípa ìgbádùn ìjọ aṣíwájú láti āyah 10 sí āyah 26. Ó sọ nípa ìgbádùn ìjọ ọ̀tún láti āyah 27 sí āyah 40. Ó sì sọ nípa oníran-ànran ìyà ìjọ òsì láti āyah 41 sí āyah 56.
Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
Verse 10
Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.
Verse 11
Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)
Verse 13
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 14
Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
Verse 15
(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.
Verse 16
Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.
Verse 17
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn
pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn.
Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.
Verse 20
Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).
Verse 21
Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).
Verse 22
Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).
Verse 23
Wọ́n dà bí òkúta olówó-iyebíye tí wọ́n fi pamọ́.
Verse 24
(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 26
Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.
Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?
Verse 28
(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,
Verse 29
àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ t’ó so jìgbìnnì,
Verse 30
àti ibòji t’ó gbòòrò,
Verse 31
àti omi t’ó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,
Verse 32
àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,
Verse 33
tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).
Verse 34
(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.
Verse 35
Dájúdájú Àwa tún (àwọn obìnrin wọn) dá ní ẹ̀dá ọ̀tun.
Verse 36
A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,
Verse 37
olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.
Verse 38
(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Verse 39
Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 40
Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.
____________________
Àwọn ẹni àkọ́kọ́ dúró fún àwọn ènìyàn láti àsìkò Ànábì Ādam títí di àsìkò Ànábì ‘Īsā (aleehim sọlātu wa salām). Àwọn ẹni Ìkẹ́yìn sì dúró fún ìjọ Ànábì wa nìkan (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?
Verse 42
(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná àti omi gbígbóná,
Verse 43
àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,
Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.
Wọ́n sì máa ń wí pé: "Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
Verse 48
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?"
Verse 49
Sọ pé: "Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,
dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀."
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,
dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).
Verse 53
Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.
Verse 54
Ẹ̀yin yó sì máa mu omi gbígbóná lé e lórí.
Verse 55
Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.
Verse 56
Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.
Verse 57
Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ lódodo!
Verse 58
Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),
ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?
Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara
Verse 63
Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,
ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde ni tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).
Verse 66
(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) "Dájúdájú àwa ti di onígbèsè."
Verse 67
(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) "Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni."
ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?
Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi t’ó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?
ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?
Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.
Verse 74
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
Verse 77
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé,
Verse 78
(t’ó wà) nínú Tírà ààbò (nínú Laohul-Mahfūṭḥ).
Verse 79
Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).
Verse 80
Wọ́n sọ̀ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 81
Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè nírọ́?
Verse 82
Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo nírọ́.
____________________
Ìyẹn ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dúpẹ́ fún ìràwọ̀ nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́ pé òhun l’ó ń rọ̀jò lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Irọ́ ni èyí àti àìgbàgbọ́ nínú Allāhu (subhānahu wa ta'ālā), Ẹni t’Ó ń rọ̀jò fún ẹ̀dá Rẹ̀.
Verse 83
Kí ni ó máa ti rí (fun yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,
Verse 84
tí ẹ̀yin yó sì máa wòran nígbà yẹn?
Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Mujādilah; 58:7.
Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,
Verse 87
kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),
Verse 89
ìsinmi, èsè t’ó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).
àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,
Verse 93
n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi gbígbóná
Verse 94
àti wíwọ inú iná Jẹhīm.
Verse 96
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.
تقدم القراءة