سورة الإنفطار

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura الإنفطار ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 1
Nígbà tí sánmọ̀ bá fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
Verse 2
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
Verse 3
àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
Verse 4
àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
Verse 7
Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
Verse 9
Ní ti òdodo, ńṣe l’ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́.
Verse 10
Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
Verse 11
(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
Verse 12
Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 13
Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
Verse 14
Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
Verse 15
Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.
تقدم القراءة