سورة التكوير

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura التكوير ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 1
Nígbà tí Wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
Verse 2
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
Verse 3
àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
Verse 4
àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
Verse 5
àti nígbà tí Wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
Verse 6
àti nígbà tí Wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
Verse 7
àti nígbà tí Wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
Verse 8
àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
Verse 10
àti nígbà tí Wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
Verse 11
àti nígbà tí Wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
Verse 12
àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
Verse 13
àti nígbà tí Wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
Verse 14
(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
Verse 15
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń búra pẹ̀lú àwọn ìràwọ̀ t’ó ń yọ ní alẹ́, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán,
Verse 16
(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ t’ó ń rìn lọ rìn bọ̀, t’ó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
Verse 17
Mo tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.
Verse 18
Mo tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀.
Verse 19
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,
____________________
Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hāƙƙọh; 69:40.
alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
Verse 21
ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
Verse 22
Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad s.a.w.) kì í ṣe wèrè.
Verse 23
Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Najm; 53:13.
Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
Verse 26
Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
تقدم القراءة