سورة المدثر

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura المدّثر ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 3
Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
Verse 4
Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
Verse 5
Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.
Verse 6
Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
Verse 7
Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
Verse 8
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
Verse 10
tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 13
àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
Verse 14
Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an.
Verse 15
Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
Verse 17
Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná).
____________________
Orúkọ àpáta ńlá kan nínú Iná ni Sọ‘ūd. Kèfèrí yóò máa pọ́n òkè náà láààrin àádọ́rin ọdún ní àpọ́njábọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pe ìyà náà ní ìyà pọ́nkèpọ́nkè.
Verse 18
Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
Verse 19
Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
Verse 20
Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
Verse 21
Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.
Verse 22
Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
Verse 23
Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga.
Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
Verse 26
Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
Verse 27
Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr?
Verse 28
(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.
____________________
Ìyẹn ni pé, Iná náà yóò máa jó o lọ, kò sì níí gba ẹ̀mí rẹ̀.
Verse 29
Ó máa jó awọ ara di dúdú.
Verse 30
(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
Verse 32
Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá.
Verse 33
Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.
Verse 34
Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́.
Verse 35
Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi.
Verse 36
(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn.
Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
Verse 39
Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Verse 40
Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
Verse 41
nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
Verse 44
Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
Verse 45
Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
Verse 46
Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́
Verse 48
Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
Verse 50
bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ,
Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
Verse 54
Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
Verse 55
Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀.
Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn.
تقدم القراءة