سورة النبأ

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura النبأ ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 1
Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná?
Verse 4
Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
Verse 5
Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀.
Verse 7
àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)?
Verse 8
A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo).
Verse 11
A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu.
Verse 12
A tún mọ sánmọ̀ méje t’ó lágbára sókè yín.
Verse 13
A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ t’ó ń tàn gbòlà.
Àti pé A sọ omi t’ó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò
Verse 15
nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde
Verse 16
pẹ̀lú àwọn ọgbà t’ó kún digbí fún n̄ǹkan oko.
Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan.
(Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ.
Verse 19
Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn.
Verse 20
Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná.
Verse 21
Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà.
Verse 22
(Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ.
Verse 23
Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ.
Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀,
Verse 25
àyàfi omi gbígbóná àti àwọyúnwẹ̀jẹ̀.
Verse 26
(Ó jẹ́) ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn).
Verse 28
Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa nírọ́ gan-an.
Verse 29
Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan.
Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fun yín bí kò ṣe ìyà.
Verse 31
Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Verse 32
Àwọn ọgbà àti èso àjàrà,
Verse 33
àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí,
Verse 34
àti ife ọtí t’ó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn).
Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀.
(Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn).
(Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun t’ó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀.
Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ t’ó ṣe wẹ́kú.
Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà).
Dájúdájú A fi ìyà t’ó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fun yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: "Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà)."
تقدم القراءة