Ìtumọ̀ Sura الشعراء ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية
Verse 1
ﭑ
ﭒ
Tọ̄ sīn mīm.
Verse 2
ﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà t’ó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
Verse 3
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
ﭞ
Nítorí kí ni o ṣe máa para rẹ pé wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 4
Tí A bá fẹ́, A máa sọ àmì kan kalẹ̀ fún wọn láti sánmọ̀. Àwọn ọrùn wọn kò sì níí yé tẹríba fún un.
Verse 5
Kò sí ìrántí kan tí ó máa dé bá wọn ní titun láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé àfi kí wọ́n jẹ́ olùgbúnrí kúrò níbẹ̀.
Verse 6
Dájúdájú wọ́n ti pe (āyah Wa) nírọ́. Nítorí náà, àwọn ìró ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.
Verse 7
Ṣé wọn kò rí ilẹ̀ pé mélòó mélòó nínú gbogbo oríṣiríṣi n̄ǹkan alápọ̀n-ọ́nlé tí A mú hù jáde láti inú rẹ̀?
Verse 8
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 9
ﮖﮗﮘﮙﮚ
ﮛ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 10
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ pe (Ànábì) Mūsā pé: "Lọ bá ìjọ alábòsí,
Verse 11
ﮥﮦﮧﮨﮩ
ﮪ
ìjọ Fir‘aon (kí o sì sọ̱ fún wọn) pé 'Ṣé wọn kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni.'"
Verse 12
ﮫﮬﮭﮮﮯﮰ
ﮱ
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pè mí ní òpùrọ́.
Verse 13
Ó sì máa jẹ́ ìnira fún mi (tí wọ́n bá pè mí ní òpùrọ́). Ahọ́n mi kò sì já gaaraga. Nítorí náà, ránṣẹ́ sí Hārūn.
Verse 14
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
ﯢ
Àti pé mo ní ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́rùn lọ́dọ̀ wọn. Nítorí náà, mò ń bẹ̀rù pé wọ́n máa pa mí."
Verse 15
(Allāhu) sọ pé: "Rárá (wọn kò lè pa ọ́). Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Wa lọ (bá wọn). Dájúdájú Àwa ń bẹ pẹ̀lú yín; À ń gbọ́ (ọ̀rọ̀ yín).
Verse 16
Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ bá Fir‘aon. Kí ẹ sọ fún un pé: 'Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 17
ﯵﯶﯷﯸﯹ
ﯺ
(À ń sọ fún ọ) pé kí o jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ.'"
Verse 18
(Fir‘aon) wí pé: “Ṣé kì í ṣe ní ààrin wa ni a ti tọ́ ọ ní kékeré ni, tí o sì gbé ní ọ̀dọ̀ wa fún ọdún púpọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ?
Verse 19
O sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí o ṣe (sí wa). Ìwọ sì wà nínú àwọn aláìmoore.”
Verse 20
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
(Ànábì Mūsā) sọ pé: "Mo ṣe é nígbà náà nígbà tí mo wà nínú àwọn aláìmọ̀kan ni.
Verse 21
Mo sì sá fun yín nígbà tí mo bẹ̀rù yín. Nítorí náà, Allāhu ti ta mí lọ́rẹ ipò Ànábì. Ó sì ṣe mí ní (ọ̀kan) nínú àwọn Òjíṣẹ́.
Verse 22
Àti pé ìyẹn ni ìdẹ̀ra tí ò ń ṣe ìrègún rẹ̀ lé mi lórí. Pé ó sọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl di ẹrú (ńkọ́?).
____________________
Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń fọ èsì fún Fir ‘aon pé, tí o bá sọ pé o ṣoore alágbàtọ́ fún mi, ṣebí o tún sọ àwọn ènìyàn mi di ẹrú rẹ?! Ìyẹn ni pé, tí Fir ‘aon bá mọ ìrègún oore síṣe alágbàtọ́ òun í ṣe, kó rántí aburú ńlá t’ó wà nínú bí ó ṣe sọ àwọn ènìyàn t’òun náà di ẹrú rẹ̀. Nítorí náà, kí Fir ‘aon má ṣe lérò pé gbígba ẹnì kan wò tẹ̀wọ̀n ju sísọ àwọn yòókù rẹ̀ di ẹrú. Fir‘aon sì mẹ́nu kúrò níbẹ̀. Ó bọ́ sórí ọ̀rọ̀ mìíràn.
____________________
Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ń fọ èsì fún Fir ‘aon pé, tí o bá sọ pé o ṣoore alágbàtọ́ fún mi, ṣebí o tún sọ àwọn ènìyàn mi di ẹrú rẹ?! Ìyẹn ni pé, tí Fir ‘aon bá mọ ìrègún oore síṣe alágbàtọ́ òun í ṣe, kó rántí aburú ńlá t’ó wà nínú bí ó ṣe sọ àwọn ènìyàn t’òun náà di ẹrú rẹ̀. Nítorí náà, kí Fir ‘aon má ṣe lérò pé gbígba ẹnì kan wò tẹ̀wọ̀n ju sísọ àwọn yòókù rẹ̀ di ẹrú. Fir‘aon sì mẹ́nu kúrò níbẹ̀. Ó bọ́ sórí ọ̀rọ̀ mìíràn.
Verse 23
ﭭﭮﭯﭰﭱ
ﭲ
Fir‘aon wí pé: “Kí ni Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”
Verse 24
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni)
Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”
Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú.”
Verse 25
ﭾﭿﮀﮁﮂ
ﮃ
(Fir‘aon) wí fún àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ (t’ó ń sọ ni)?”
Verse 26
ﮄﮅﮆﮇﮈ
ﮉ
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Verse 27
(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ yín èyí tí wọ́n rán si yín, wèrè mà ni.”
Verse 28
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Allāhu ni) Olúwa ibùyọ òòrùn, ibùwọ̀ òòrùn àti ohunkóhun t’ó ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ẹ bá máa ń ṣe làákàyè.”
Verse 29
(Fir‘aon) wí pé: “Dájúdájú tí o bá fi lè jọ́sìn fún ọlọ́hun kan yàtọ̀ sí mi, dájúdájú mo máa sọ ọ́ di ara àwọn ẹlẹ́wọ̀n.”
Verse 30
ﮦﮧﮨﮩﮪ
ﮫ
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé mo mú kiní kan t’ó yanjú wá fún ọ ńkọ́?”
Verse 31
(Fir‘aon) wí pé: “Mú un wá nígbà náà tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
Verse 32
ﯕﯖﯗﯘﯙﯚ
ﯛ
Nítorí náà, ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ejò pọ́nńbélé.
Verse 33
ﯜﯝﯞﯟﯠﯡ
ﯢ
Ó tún fa ọwọ́ rẹ̀ yọ síta, ó sì di funfun fún àwọn olùwòran.
Verse 34
(Fir‘aon) wí fún àwọn ìjòyè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ pé: “Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa.
Verse 35
Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni. Kí ni ohun tí ẹ máa mú wá ní ìmọ̀ràn?”
____________________
Nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:109- 110, gbólóhùn "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni.", ó jáde láti ẹnu àwọn ìjòyè Fir‘aon. Àmọ́ nínú sūrah yìí, sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26: 34-35, gbólóhùn yẹn jáde láti ẹnu Fir‘aon. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, Fir‘aon sọ gbólóhùn náà, àwọn ìjòyè rẹ̀ náà gbè é lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà sì di àgbàsọ láààrin wọn.
____________________
Nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:109- 110, gbólóhùn "Dájúdájú èyí ni onímọ̀ nípa idán pípa. Ó fẹ́ ko yín kúrò lórí ilẹ̀ yín ni.", ó jáde láti ẹnu àwọn ìjòyè Fir‘aon. Àmọ́ nínú sūrah yìí, sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26: 34-35, gbólóhùn yẹn jáde láti ẹnu Fir‘aon. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, Fir‘aon sọ gbólóhùn náà, àwọn ìjòyè rẹ̀ náà gbè é lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà sì di àgbàsọ láààrin wọn.
Verse 36
Wọ́n wí pé: "Dá òun àti arákùnrin rẹ̀ dúró ná, kí o sì rán àwọn akónijọ sí àwọn ìlú
Verse 37
ﯼﯽﯾﯿ
ﰀ
(pé) kí gbogbo onímọ̀ nípa idán pípa wá bá ọ."
Verse 38
ﰁﰂﰃﰄﰅ
ﰆ
Wọ́n sì kó àwọn òpìdán jọ ní àsìkò tí wọ́n fi àdéhùn sí ní ọjọ́ tí (gbogbo ìlú) ti mọ̀.
Verse 39
ﰇﰈﰉﰊﰋ
ﰌ
Wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé: "Ṣé ẹ̀yin máa kó jọ (síbẹ̀) bí?
Verse 40
Nítorí kí á lè tẹ̀lé àwọn òpìdán tí ó bá jẹ́ pé àwọn ni olùborí."
Verse 41
Nígbà tí àwọn òpìdán dé, wọ́n wí fún Fir‘aon pé: “Ǹjẹ́ owó-ọ̀yà kan wà fún wa, tí ó bá jẹ́ pé àwa gan-an la jẹ́ olùborí?”
Verse 42
ﭦﭧﭨﭩﭪﭫ
ﭬ
(Fir‘aon) wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú nígbà náà ẹ máa wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (mi).”
Verse 43
(Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”
Verse 44
Wọ́n sì ju àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn sílẹ̀. Wọ́n wí pé: “Pẹ̀lú ògo Fir‘aon, dájúdájú àwa, àwa ni olùborí.”
Verse 45
Nígbà náà, (Ànábì) Mūsā ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì ń gbé ohun tí wọ́n pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.
Verse 46
ﮈﮉﮊ
ﮋ
Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
Verse 47
ﮌﮍﮎﮏ
ﮐ
Wọ́n sọ pé: "A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,
Verse 48
ﮑﮒﮓ
ﮔ
Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn."
Verse 49
Fir‘aon wí pé: “Ẹ gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fun yín! Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Láìpẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ wá mọ̀. Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”
Verse 50
(Àwọn òpìdán) sọ pé: “Kò sí ìnira fún wa! Dájúdájú àwa yó sì fàbọ̀ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wa.
Verse 51
Dájúdájú àwa n retí pé Olúwa wa yóò ṣe àforíjìn àwọn àṣìṣe wa fún wa nítorí pé àwa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo.”
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú ìjọ Fir‘aon. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú àwọn ènìyàn. Ṣebí ìjọ-ìjọ onígbàgbọ́ òdodo ti ré kọjá ṣíwájú wọn.
____________________
Ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú ìjọ Fir‘aon. Kì í ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹni àkọ́kọ t’ó gba Allāhu gbọ́ nínú àwọn ènìyàn. Ṣebí ìjọ-ìjọ onígbàgbọ́ òdodo ti ré kọjá ṣíwájú wọn.
Verse 52
A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru (nítorí pé) dájúdájú wọn yóò lépa yín.”
Verse 53
ﯭﯮﯯﯰﯱ
ﯲ
Fir‘aon sì rán àwọn akónijọ sínú àwọn ìlú (láti sọ pé):
Verse 54
ﯳﯴﯵﯶ
ﯷ
"Dájúdájú àwọn (ọmọ ’Isrọ̄’īl) wọ̀nyí, ìjọ péréte díẹ̀ ni wọ́n.
Verse 55
ﯸﯹﯺ
ﯻ
Àti pé dájúdájú wọ́n ti ṣe ohun t’ó ń bí wa nínú.
Verse 56
ﯼﯽﯾ
ﯿ
Dájúdájú gbogbo wa ni kí á sì wà tìfura-tìfura."
Verse 57
ﰀﰁﰂﰃ
ﰄ
Nítorí náà, A mú (ìjọ Fir‘aon) jáde kúrò nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi,
Verse 58
ﰅﰆﰇ
ﰈ
àti àwọn àpótí-ọrọ̀ àti ibùjókòó àpọ́nlé.
Verse 59
ﰉﰊﰋﰌﰍ
ﰎ
Báyẹn (lọ̀rọ̀ rí). A sì jogún rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
Verse 60
ﰏﰐ
ﰑ
Wọ́n sì lépa wọn ní àsìkò tí òòrùn yọ.
Verse 61
Nígbà tí ìjọ méjèèjì ríra wọn, àwọn ìjọ (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú wọn yóò lé wa bá.”
Verse 62
(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Rárá, dájúdájú Olúwa mi ń bẹ pẹ̀lú mi. Ó sì máa fi ọ̀nà mọ̀ mí.”
Verse 63
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Fi ọ̀pá rẹ na agbami òkun.” (Ó fi nà á). Ó sì pín (sí ọ̀nà méjìlá). Ìpín kọ̀ọ̀kan sì dà bí àpáta ńlá.
Verse 64
ﭱﭲﭳ
ﭴ
A sì mú ìjọ kejì (ìyẹn, ìjọ Fir‘aon) súnmọ́ ibẹ̀ yẹn.
Verse 65
ﭵﭶﭷﭸﭹ
ﭺ
A gba (Ànábì) Mūsā àti gbogbo àwọn t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ là pátápátá.
Verse 66
ﭻﭼﭽ
ﭾ
Lẹ́yìn náà, A tẹ ìjọ kejì rì (sínú agbami).
Verse 67
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 68
ﮉﮊﮋﮌﮍ
ﮎ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 69
ﮏﮐﮑﮒ
ﮓ
Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.
Verse 70
ﮔﮕﮖﮗﮘﮙ
ﮚ
Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
Verse 71
ﮛﮜﮝﮞﮟﮠ
ﮡ
Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
Verse 72
ﮢﮣﮤﮥﮦ
ﮧ
(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Ǹjẹ́ wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ bá ń pè wọ́n?
Verse 73
ﮨﮩﮪﮫ
ﮬ
Tàbí (ṣé) wọ́n lè ṣe yín ní oore tàbí wọ́n lè fi ìnira kàn yín?”
Verse 74
ﮭﮮﮯﮰﮱﯓ
ﯔ
Wọ́n wí pé: “Rárá o! A bá àwọn bàbá wa, tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni”
Verse 75
ﯕﯖﯗﯘﯙ
ﯚ
(Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: " Ẹ sọ fún mi, kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún,
Verse 76
ﯛﯜﯝ
ﯞ
ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ìṣaájú?
Verse 77
ﯟﯠﯡﯢﯣﯤ
ﯥ
Dájúdájú àwọn ni ọ̀tá fún mi àyàfi Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 78
ﯦﯧﯨﯩ
ﯪ
(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Nítorí náà, Ó máa fi ọ̀nà mọ̀ mí;
Verse 79
ﯫﯬﯭﯮ
ﯯ
Ẹni t’Ó ń fún mi ní jíjẹ, t’Ó ń fún mi ní mímu;
Verse 80
ﯰﯱﯲﯳ
ﯴ
Àti pé nígbà tí ara mi kò bá yá, Òun l’Ó ń wò mí sàn;
Verse 81
ﯵﯶﯷﯸ
ﯹ
Ẹni tí Ó máa pa mí, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ mí di alààyè;
Verse 82
Ẹni tí mo ní ìrètí sí pé Ó máa forí àwọn àṣìṣe mi jìn mí ní Ọjọ́ Ẹ̀san.
Verse 83
ﰃﰄﰅﰆﰇﰈ
ﰉ
Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ ipò Ànábì. Dà mí pọ̀ mọ́ àwọn ẹni rere.
Verse 84
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Jẹ́ kí àwọn t’ó ń bọ̀ lẹ́yìn (mi) máa sọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú dáadáa.
Verse 85
ﭘﭙﭚﭛﭜ
ﭝ
Ṣe mí ní ọ̀kan nínú àwọn olùjogún Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Verse 86
ﭞﭟﭠﭡﭢﭣ
ﭤ
Kí O sì foríjin bàbá mi. Dájúdájú ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣìnà.
Verse 87
ﭥﭦﭧﭨ
ﭩ
Má ṣe dójú tì mí ní ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
Verse 88
ﭪﭫﭬﭭﭮﭯ
ﭰ
Ọjọ́ tí dúkìá kan tàbí àwọn ọmọ kò níí ṣàǹfààní.
Verse 89
ﭱﭲﭳﭴﭵﭶ
ﭷ
Àyàfi ẹni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ọkàn mímọ́."
____________________
Ọkàn mímọ́ ni ọkàn tí ó là kúrò nínú ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn.
____________________
Ọkàn mímọ́ ni ọkàn tí ó là kúrò nínú ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ẹ̀sìn.
Verse 90
ﭸﭹﭺ
ﭻ
A máa mú Ọgbà Ìdẹ̀ra súnmọ́ àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Verse 91
ﭼﭽﭾ
ﭿ
Wọ́n sì máa fi iná Jẹhīm han àwọn olùṣìnà,
Verse 92
ﮀﮁﮂﮃﮄﮅ
ﮆ
wọn yó sì sọ fún wọn pé: “Níbo ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún wà?”
Verse 93
(N̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu, ṣé wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ tàbí ṣé wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́?
Verse 94
ﮏﮐﮑﮒ
ﮓ
Wọ́n sì máa taari gbogbo wọn sínú Iná; àwọn àti èṣù wọn,
Verse 95
ﮔﮕﮖ
ﮗ
àti àwọn ọmọ ogun ’Iblīs pátápátá.
Verse 96
ﮘﮙﮚﮛ
ﮜ
(Àwọn aláìgbàgbọ́), nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn jiyàn nínú Iná, wọ́n á wí pé:
Verse 97
ﮝﮞﮟﮠﮡﮢ
ﮣ
"A fi Allāhu búra, dájúdájú àwa kúkú ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
Verse 98
ﮤﮥﮦﮧ
ﮨ
nígbà tí a fi yín ṣe akẹgbẹ́ fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 99
ﮩﮪﮫﮬ
ﮭ
Kò sí ohun tí ó ṣì wá lọ́nà bí kò ṣe àwọn (èṣù) ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 100
ﮮﮯﮰﮱ
ﯓ
Kò sì sí àwọn olùṣìpẹ̀ kan fún wa.
Verse 101
ﯔﯕﯖ
ﯗ
Kò tún sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan (fún wa.)
Verse 102
Tí ó bá jẹ́ pé ìpadà sí ilé ayé wà fún wa ni, nígbà náà àwa ìbá wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo."
Verse 103
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 104
ﯪﯫﯬﯭﯮ
ﯯ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 105
ﯰﯱﯲﯳ
ﯴ
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
Verse 106
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Nūh, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
Verse 107
ﯽﯾﯿﰀ
ﰁ
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
Verse 108
ﰂﰃﰄ
ﰅ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 109
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 110
ﰓﰔﰕ
ﰖ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.”
Verse 111
ﰗﰘﰙﰚﰛﰜ
ﰝ
Wọ́n wí pé: “Ṣé kí á gbà ọ́ gbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ l’ó ń tẹ̀lé ọ!?”
Verse 112
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Ó sọ pé: “Èmi kò nímọ̀ sí ohun tí wọ́n ń ṣe (lẹ́yìn mi).
Verse 113
Kò sí ìṣírò-iṣẹ́ wọn lọ́dọ̀ ẹnì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Olúwa mi, tí ó bá jẹ́ pé ẹ bá fura.
Verse 114
ﭡﭢﭣﭤ
ﭥ
Èmi kò sì níí lé àwọn onígbàgbọ́ òdodo dànù.
Verse 115
ﭦﭧﭨﭩﭪ
ﭫ
Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
Verse 116
Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”
Verse 117
ﭵﭶﭷﭸﭹ
ﭺ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.
Verse 118
Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Verse 119
ﮅﮆﮇﮈﮉﮊ
ﮋ
A la òun àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi t’ó kún kẹ́kẹ́.
Verse 120
ﮌﮍﮎﮏ
ﮐ
Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn t’ó ṣẹ́kù rì sínú omi.
Verse 121
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 122
ﮛﮜﮝﮞﮟ
ﮠ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 123
ﮡﮢﮣ
ﮤ
Àwọn ìran ‘Ād pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
Verse 124
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
Verse 125
ﮭﮮﮯﮰ
ﮱ
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
Verse 126
ﯓﯔﯕ
ﯖ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 127
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 128
ﯤﯥﯦﯧﯨ
ﯩ
Ṣé ẹ óò máa kọ́ ilé ńlá ńlá sí àwọn àyè gíga (kí ẹ lè) máa fi àwọn olùrékọjá ṣẹ̀fẹ̀?
Verse 129
ﯪﯫﯬﯭ
ﯮ
Ẹ sì ń kọ́ àwọn ilé ńlá ńlá bí ẹni pé ẹ máa ṣe gbére (nílé ayé yìí).
Verse 130
ﯯﯰﯱﯲ
ﯳ
Nígbà tí ẹ bá sì gbá (ènìyàn mú láti fìyà jẹ wọ́n), ẹ̀ ń gbá wọn mú ní ìgbámú aláìlójú-àánú.
Verse 131
ﯴﯵﯶ
ﯷ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 132
ﯸﯹﯺﯻﯼ
ﯽ
Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun tí ẹ mọ̀;
Verse 133
ﯾﯿﰀ
ﰁ
Ó ràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sìn àti àwọn ọmọ,
Verse 134
ﰂﰃ
ﰄ
àti àwọn ọgbà oko pẹ̀lú àwọn ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
Verse 135
ﰅﰆﰇﰈﰉﰊ
ﰋ
Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá fun yín.”
Verse 136
Wọ́n wí pé: “Bákan náà ni fún wa; yálà o kìlọ̀ fún wa tàbí o ò sí nínú àwọn olùkìlọ̀.
Verse 137
ﭑﭒﭓﭔﭕ
ﭖ
Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìwà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 138
ﭗﭘﭙ
ﭚ
Wọn kò sì níí jẹ wá níyà.”
Verse 139
Nítorí náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. A sì pa wọ́n run. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 140
ﭨﭩﭪﭫﭬ
ﭭ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 141
ﭮﭯﭰ
ﭱ
Àwọn ìran Thamūd pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
Verse 142
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
Verse 143
ﭺﭻﭼﭽ
ﭾ
Dájúdájú emi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
Verse 144
ﭿﮀﮁ
ﮂ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 145
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 146
ﮐﮑﮒﮓﮔ
ﮕ
Ṣé kí wọ́n fi yín sílẹ̀ síbi n̄ǹkan tí ó wà (nílé ayé) níbí yìí (nínú ìgbádùn ayé, kí ẹ jẹ́) olùfọkànbalẹ̀
Verse 147
ﮖﮗﮘ
ﮙ
nínú àwọn ọgbà oko àti ìṣẹ́lẹ̀rú omi.
Verse 148
ﮚﮛﮜﮝ
ﮞ
àti oko irúgbìn pẹ̀lú igi dàbínù tí ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ tutù?
Verse 149
ﮟﮠﮡﮢﮣ
ﮤ
Ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àwọn àpáta (gẹ́gẹ́ bí) akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́!
Verse 150
ﮥﮦﮧ
ﮨ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 151
ﮩﮪﮫﮬ
ﮭ
Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àṣẹ àwọn aláṣejù,
Verse 152
ﮮﮯﮰﮱﯓﯔ
ﯕ
àwọn t’ó ń ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí wọn kò sì ṣe rere.”
Verse 153
ﯖﯗﯘﯙﯚ
ﯛ
Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
Verse 154
Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Nítorí náà, mú àmì kan wá tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
Verse 155
Ó sọ pé: “Èyí ni abo ràkúnmí kan. Omi wà fún òhun, omi sì wà fún ẹ̀yin náà ní ọjọ́ tí a ti mọ̀.
Verse 156
Ẹ má ṣe fi aburú kan kàn án nítorí kí ìyà ọjọ́ ńlá má baà jẹ yín.”
Verse 157
ﯺﯻﯼ
ﯽ
Wọ́n sì gún un pa. Nítorí náà, wọ́n sì di alábàámọ̀.
Verse 158
Ìyà náà jẹ wọ́n. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 159
ﰋﰌﰍﰎﰏ
ﰐ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 160
ﭑﭒﭓﭔ
ﭕ
Ìjọ Lūt pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
Verse 161
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Lūt, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
Verse 162
ﭞﭟﭠﭡ
ﭢ
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
Verse 163
ﭣﭤﭥ
ﭦ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 164
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 165
ﭴﭵﭶﭷ
ﭸ
Ṣé àwọn ọkùnrin nínú ẹ̀dá ni ẹ̀yin ọkùnrin yóò lọ máa bá (fún adùn ìbálòpọ̀)?
Verse 166
Ẹ sì ń pa ohun tí Olúwa yín dá fun yín tì nínú àwọn ìyàwó yín! Àní sẹ́, ìjọ alákọyọ ni ẹ̀yin.”
Verse 167
Wọ́n wí pé: “Tí ìwọ Lūt kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa lé jáde kúrò nínú ìlú.”
Verse 168
ﮏﮐﮑﮒﮓ
ﮔ
Ó sọ pé: "Dájúdájú èmi wà nínú àwọn olùbínú sí iṣẹ́ (aburú) ọwọ́ yín.
Verse 169
ﮕﮖﮗﮘﮙ
ﮚ
Olúwa mi, la èmi àti àwọn ènìyàn mi níbí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (aburú)."
Verse 170
ﮛﮜﮝ
ﮞ
Nítorí náà, A la òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pátápátá.
Verse 171
ﮟﮠﮡﮢ
ﮣ
Àfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn t’ó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).
____________________
Arúgbóbìnrin yẹn ni ìyàwó Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, nínú sūrah Hūd; 11:81, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo “àyàfi ìyàwó rẹ”.
____________________
Arúgbóbìnrin yẹn ni ìyàwó Ànábì Lūt ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) nítorí pé, nínú sūrah Hūd; 11:81, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lo “àyàfi ìyàwó rẹ”.
Verse 172
ﮤﮥﮦ
ﮧ
Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
Verse 173
A rọ òjò lé wọn lórí tààrà. Òjò àwọn tí A kìlọ̀ fún sì burú.
Verse 174
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 175
ﯛﯜﯝﯞﯟ
ﯠ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 176
ﯡﯢﯣﯤ
ﯥ
Àwọn ará ’Aekah pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́.
Verse 177
ﯦﯧﯨﯩﯪﯫ
ﯬ
Nígbà tí arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb, sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin kò níí bẹ̀rù (Allāhu) ni?
Verse 178
ﯭﯮﯯﯰ
ﯱ
Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fun yín.
Verse 179
ﯲﯳﯴ
ﯵ
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 180
Èmi kò sì bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi lọ́dọ̀ ẹnì kan àfi lọ́dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 181
Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún. Kí ẹ sì má ṣe wà nínú àwọn olùdóṣùwọ̀nkù.
Verse 182
ﰋﰌﰍ
ﰎ
Ẹ fi ìwọ̀n t’ó tọ́ wọn n̄ǹkan.
Verse 183
Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣe hùwà aburú lórí ilẹ̀ ní ti òbìlẹ̀jẹ́.
Verse 184
ﭑﭒﭓﭔﭕ
ﭖ
Kí ẹ sì bẹ̀rù Ẹni tí Ó dá yín àti àwọn ìran àkọ́kọ́.”
Verse 185
ﭗﭘﭙﭚﭛ
ﭜ
Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú wà nínú àwọn eléèdì.
Verse 186
Ìwọ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àti pé a ò rò ọ́ sí kiní kan bí kò ṣe pé ó wà nínú àwọn òpùrọ́.
Verse 187
Nítorí náà, jẹ́ kí apá kan nínú sánmọ̀ ya lù wá mọ́lẹ̀, tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
Verse 188
ﭱﭲﭳﭴﭵ
ﭶ
Ó sọ pé: “Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Verse 189
Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ìyà ọjọ́ ẹ̀ṣújò sì jẹ wọ́n. Dájúdájú ó jẹ́ ìyà ọjọ́ ńlá.
Verse 190
Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 191
ﮍﮎﮏﮐﮑ
ﮒ
Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun mà ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Verse 192
ﮓﮔﮕﮖ
ﮗ
Dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 193
ﮘﮙﮚﮛ
ﮜ
Mọlāika Jibrīl, olùfọkàntán l’ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀
Verse 194
ﮝﮞﮟﮠﮡ
ﮢ
sínú ọkàn rẹ nítorí kí o lè wà nínú àwọn olùkìlọ̀
Verse 195
ﮣﮤﮥ
ﮦ
pẹ̀lú èdè Lárúbáwá pọ́nńbélé.
Verse 196
ﮧﮨﮩﮪ
ﮫ
Dájúdájú (ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀) ti wà nínú ìpín-ìpín Tírà àwọn ẹni àkọ́kọ́.
Verse 197
Ṣé kò jẹ́ àmì kan fún wọn pé àwọn onímọ̀ (nínú) àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nímọ̀ (sí àsọọ́lẹ̀ nípa) rẹ̀ (nínú tírà ọwọ́ wọn)?
Verse 198
ﯗﯘﯙﯚﯛ
ﯜ
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún apá kan àwọn elédè mìíràn ni,
Verse 199
ﯝﯞﯟﯠﯡﯢ
ﯣ
199. tí ó sì ké e fún wọn, wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo.
Verse 200
ﯤﯥﯦﯧﯨ
ﯩ
Báyẹn ni A ṣe mú (àtakò) wọ inú ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 201
Wọn kò níí gbà á gbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Verse 202
ﯲﯳﯴﯵﯶ
ﯷ
(Ìyà náà) yóò dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura.
Verse 203
ﯸﯹﯺﯻ
ﯼ
Nígbà náà ni wọn yóò wí pé: "Ǹjẹ́ wọ́n lè lọ́ wa lára bí?"
Verse 204
ﯽﯾ
ﯿ
Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
Verse 205
ﰀﰁﰂﰃ
ﰄ
Sọ fún Mi tí A bá fún wọn ní ìgbádùn ayé fún ọdún gbọọrọ!
Verse 206
ﰅﰆﰇﰈﰉ
ﰊ
Lẹ́yìn náà, kí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn dé bá wọn.
Verse 207
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Ohun tí A ṣe ní ìgbádùn fún wọn kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
Verse 208
A ò sì pa ìlú kan run àfi kí wọ́n ti ní àwọn olùkìlọ̀.
Verse 209
ﭠﭡﭢﭣ
ﭤ
Ìrántí (dé fún wọn sẹ́). Àti pé Àwa kì í ṣe alábòsí.
Verse 210
ﭥﭦﭧﭨ
ﭩ
Kì í ṣe àwọn èṣù ni wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀.
Verse 211
ﭪﭫﭬﭭﭮ
ﭯ
Kò yẹ fún wọn. Wọn kò sì lágbára rẹ̀.
Verse 212
ﭰﭱﭲﭳ
ﭴ
Dájúdájú A ti mú wọn takété sí gbígbọ́ rẹ̀ (láti ojú sánmọ̀).
Verse 213
Nítorí náà, má ṣe pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu, nítorí kí ìwọ má baà wà nínú àwọn tí A máa jẹ níyà.
Verse 214
ﭿﮀﮁ
ﮂ
Kí o sì kìlọ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, t’ó súnmọ́ jùlọ.
Verse 215
ﮃﮄﮅﮆﮇﮈ
ﮉ
Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn t’ó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Verse 216
Tí wọ́n bá sì yapa (àṣẹ) rẹ, sọ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe (níṣẹ́ aburú).”
Verse 217
ﮒﮓﮔﮕ
ﮖ
Kí o sì gbáralé Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run;
Verse 218
ﮗﮘﮙﮚ
ﮛ
Ẹni t’Ó ń rí ọ nígbà tí ò ń dìde nàró (fún ìrun kíkí)
Verse 219
ﮜﮝﮞ
ﮟ
àti ìyírapadà rẹ (fún rukuu àti ìforíkanlẹ̀) láààrin àwọn olùforíkanlẹ̀.
Verse 220
ﮠﮡﮢﮣ
ﮤ
Dájúdájú Òun mà ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Verse 221
ﮥﮦﮧﮨﮩﮪ
ﮫ
Ṣé kí n̄g sọ ẹni tí àwọn èṣù ń sọ̀kalẹ̀ wá bá?
Verse 222
ﮬﮭﮮﮯﮰ
ﮱ
Wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ wá bá gbogbo àwọn òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 223
ﯓﯔﯕﯖ
ﯗ
(Àwọn èṣù) ń dẹtí (sí ìró sánmọ̀). Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òpùrọ́.
Verse 224
ﯘﯙﯚ
ﯛ
Àwọn eléwì, àwọn olùṣìnà l’ó ń tẹ̀lé wọn.
Verse 225
Ṣé o ò rí i pé gbogbo ọ̀gbun ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń tẹnu bọ̀ ni?
Verse 226
ﯤﯥﯦﯧﯨ
ﯩ
Àti pé dájúdájú wọ́n ń sọ ohun tí wọn kò níí ṣe.
Verse 227
Àfi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere, tí wọ́n rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀, tí wọ́n sì jàjà gbara lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàbòsí sí wọn. Àwọn t’ó ṣàbòsí sì máa mọ irú ìkángun tí wọ́n máa gúnlẹ̀ sí.
تقدم القراءة