surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Hā mīm.
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,
Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo nírọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ pé: "Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná."
Àwọn t’ó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn t’ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n gba Allāhu gbọ́. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): "Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn t’ó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni t’ó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá."
Dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): " Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́."
Wọ́n wí pé: "Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Nítorí náà, a sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?"
____________________
Àwọn kan lérò pé, ìtúmọ̀ āyah yìí ni pé, ènìyàn máa wáyé ní ẹ̀ẹ̀ méjì, ó sì máa kú ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, ènìyàn wà ní ipò òkú nígbà tí ó jẹ́ aláìsí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ìyẹn ni ikú àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa wà ní ipò alààyè nígbà tí ó bá délé ayé. Ìyẹn ni ìṣẹ̀mí àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa di aláìsí nígbà tí ó bá parí òǹkà àkókò tí Allāhu pèbùbù fún un láti lò nílé ayé. Ìyẹn sì ni ikú kejì. Lẹ́yìn náà, ó máa di alààyè ní ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí kú mọ́. Ìyẹn sì ni ìṣẹ̀mí kejì. Èyí ni ìtúmọ̀ āyah náà. Irú āyah yìí sì kúkú ti ṣíwájú nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:28.
(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
Òun ni Ẹni t’Ó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àfi ẹni t’ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
Nítorí náà, ẹ pe Allāhu ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.
(Allāhu) Ẹni t’Ó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí (al-Ƙur’ān) ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.
Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): "Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní? Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni."
Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Àti pé ṣèkìlọ̀ ọjọ́ tí ó súnmọ́ fún wọn. Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí.
(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.
____________________
Ojú ìjàǹbá ni ojú t’ó ń yọ́ obìnrin wò. Ìyẹn ni pé, ìjàǹbá ni fún ọkùnrin kan láti máa yọ́ obìnrin olóbìnrin wò. Ohun tí ọkàn sì fi pamọ́ ni èrò-ọkàn ọkùnrin náà nípa obìnrin t’ó ń yọ́ wò àti ohun mìíràn t’ó wà nínú ọkàn rẹ̀.
Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.
Ìyẹn nítorí pé àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí t’ó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́
sí Fir‘aon, Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: "Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā)."
Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: "Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn t’ó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀." Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.
Fir‘aon wí pé: "Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀."
(Ànábì) Mūsā sọ pé: "Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò gba Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́ gbọ́.
Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan t’ó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: "Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, ‘Allāhu ni Olúwa mi.’ Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fun yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, ẹ̀yin sì ni alásẹ lórí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?" Fir‘aon wí pé: "Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà."
Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà t’ó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;
Irú ìṣe (ìparun t’ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn t’ó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fun yín.
____________________
Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde ni Ọjọ́ ìpè. Ìyẹn ni pé, ọjọ́ tí àwọn mọlāika máa pe àwọn ènìyàn àti àlùjànnú láti sọ fún wọn pé, tí ẹ bá lè sá lọ báyìí, ẹ sá lọ wò. Éyí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:33. Bákan náà, ìpè máa wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná. Èyí wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:44. Ìpè tún máa wá láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Èyí tún wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:50.
Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ t’ó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: "Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù.
Àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”
Fir‘aon wí pé: "Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.
Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́." Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.
Ẹni t’ó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí jẹ́ ìgbádùn lásán. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.
Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè àrísìkí fún wọn nínú rẹ̀ láì la ìṣírò lọ.
Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?
Ẹ̀ ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un. Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.
____________________
Sísọ n̄ǹkan tí ẹ̀dá kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) túmọ̀ sí pé sísọ n̄ǹkan tí Allāhu kò fi mọ ẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí akẹgbẹ́ Rẹ̀ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu (subhānahu wa ta'ālā).
Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-àlà, àwọn ni èrò inú Iná.
Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fun yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn."
Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.
Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): "Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná t’ó le jùlọ."
(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”
Àwọn t’ó ṣègbéraga wí pé: "Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀.” Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà."
Àwọn t’ó wà nínú Iná tún wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: "Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan."
Wọ́n yóò sọ pé: "Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá ba yín bí?" Wọ́n wí pé: “Rárá, (wọ́n ń mú un wá).” Wọ́n sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.
____________________
Nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:186, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi kalmọh “rọṣād” parí àdúà àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ìyẹn, “la‘llahum yẹrṣudūn”) àmọ́ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:14 àti sūrah yìí, Ó fi kalmọh “dọlāl” parí àdúà àwọn aláìgbàgbọ́. “Rọṣād” túmọ̀ sí “ìmọ̀nà”, “dọlāl” sì túmọ̀ sí “ìṣìnà”. Àdúà t’ó wà lórí ìmọ̀nà ni àdúà t’ó máa lọ tààrà =
= sọ́dọ̀ Allāhu. Àdúà náà sì máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà. Èyí ni Allāhu fi rinlẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:26. Àmọ́ àdúà t’ó wà lórí ìṣìnà, kò níí lọ sọ́dọ̀ Allāhu. Kò sì sí ẹni tí ó ń gba àdúà lẹ́yìn Allāhu. Ìdí nìyí tí àdúà náà fi máa gúnlẹ̀ sí èbúté-anù àti òfò. Wàyí, ọ̀nà wo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń gbà rí oore láyé? Kò sí oore ayé kan tí ó lè tẹ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ bí kò ṣe ìpín rẹ̀ nínú kádàrá. Àmọ́ ní ti onígbàgbọ́ òdodo, oore inú kádàrá àti oore àdúà l’ó wà fún un níwọ̀n ìgbà tí àdúà rẹ̀ bá ti bá sunnah Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) mu.
Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
____________________
Irú gbólóhùn yìí tún wà nínú sūrah Muhammad; 47:19. Ẹ̀̀ṣẹ̀ wo ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá? Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kì í ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn tàbí olùyapa àṣẹ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā). Àmọ́ nítorí pé kì í ṣe mọlāika, kì í sì ṣe ọlọ́hun, ó ṣeé ṣe kí ó ṣe ìṣe kan tí Allāhu máa pè ní ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Irúfẹ́ àwọn ìṣe náà kò tàbùkù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì yọ ọ́ kúrò nípò àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ẹ̀da.
Allāhu kì í kúkú ṣe Ọba alábòsí, Ó ṣàfi hàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dá.
Àṣìṣe kìíní t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Títú tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú àwọn ẹrú ogun Badr sílẹ̀ dípò pípa wọ́n, ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn nítorí pé, àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé, àwùjọ mùsùlùmí bùkátà sí owó àti ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú kan nínú àwọn ẹrú ogun náà, nígbà tí àwọn ẹrú mìíràn rí ìtúsílẹ̀ gbà nípasẹ̀ kíkọ́ àwọn Sọhābah kan ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní òdodo ni pé, ìgbésẹ̀ yìí dára. Àmọ́ Allāhu kà á kún àṣìṣe. Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé pípa wọn lásìkò náà l’ó lóore ju ìtúsílẹ̀ wọn lọ nítorí pé, àìpa wọ́n l’ó padà bí àwọn ogun mìíràn. Ńṣe ni àwọn ọ̀ṣẹbọ náà lọ túnra mú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ogun mìíràn dìde. Wọn ìbá ti pa wọ́n nígbà àkọ́kọ́, ogun ìbá ti dáwọ́ dúró. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:67-71. Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sì padà yọ̀ǹda ìtúsílẹ̀ ẹrú ogún pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ tàbí ní ọ̀fẹ́ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) nínú sūrah Muhammad; 47:4.
Àṣìṣe kejì t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Àìtètè gbà kí Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kọ Zaenab ọmọ Jahṣ (rọdiyallāhu 'anhā) sílẹ̀ lẹ́yìn tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ (sollalāhu 'alayhi wa sallam) pé Zaed ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí kò bùkátà sí i mọ́. Ohun tí ó sì mú kí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kóra ró ni pé, ó ń páyà pé àwọn aláìsàn-ọkàn yóò máa sọ pé, ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Zaed ọmọ Hārithah (rọdiyallāhu 'anhu) kì í ṣe ọmọbíbí inú Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Àti pé kò sí èèwọ̀ nínú kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fẹ́ Zaenab ọmọ Jahṣ lẹ́yìn tí Allāhu ti pa á láṣẹ fún un láti fi ṣaya. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Ahzāb; 33:37-38. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ṣẹ́rí padà síbi ohun tí Allāhu yàn fún un.
Àṣìṣe kẹta t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Sísọ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ pé òun kò níí fi ẹrúbìnrin rẹ̀ kan ṣaya. Sísọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣìṣe fún un nítorí pé, ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un ni òun fẹ́ ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ láti fi wá ìyọ́nú ìyàwó rẹ̀ kan. Èyí ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Tahrīm; 66:1.
Àṣìṣe kẹ́rin t’ó di ẹ̀ṣẹ̀: Fífajúro tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fajú ro sí afọ́jú kan tí Allāhu ti ṣípayá ọkàn rẹ̀ fún gbígba ’Islām. Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wà pẹ̀lú ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, tí ó ń ṣe wáàsí fún lọ́wọ́ nígbà tí afọ́jú yìí ń sáré bọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì ti kó ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ léyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi fẹ́ kí afọ́jú t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé di òun lọ́wọ́. Ṣíṣẹ bẹ́ẹ̀ l’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi ìdí èyí náà múlẹ̀ nínú sūrah ‘Abas; 80:1-11.
Ìwọ̀nyẹn ni àwọn àṣìṣe t’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lọ́rùn. Kì í ṣe pé Ànábì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn. Tòhun tí bí ó ṣe mọ yìí, Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò yé tọrọ àforíjìn lórí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kódà Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) kò lè má tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí ìwọ̀nyẹn nígbà ọgọ́rùn-ún lójúmọ́. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó yẹ kí èyí kọ́ èmi àti ẹ̀yin ni pé, a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu, Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa, irú èyí tí Allāhu ṣe fún Ànábì wa Muhammad yìí (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí Allāhu sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ayé nínú sūrah al-Fath; 48:1-2.
Ìyẹn ni abala èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) lẹ́yìn tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣẹrh; 94:3 fún abala kejì, èyí t’ó jẹmọ́ àṣìṣe rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun (sollalāhu 'alayhi wa sallam).
Dájúdájú àwọn t’ó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
Olúwa yín sọ pé: "Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ."
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fun yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).
Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn t’ó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ibùgbé. Ó mọ sánmọ̀ (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fun yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Sọ pé: "Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣé o ò rí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
Àwọn t’ó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa nírọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn
sínú omi gbígbóná. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.
Lẹ́yìn náà, Wọ́n máa sọ fún wọn pé: "Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?"
"(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?" Wọ́n á wí pé: "Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.
Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).
Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.
Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A ò sì sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah ar-Ra‘d; 13:38 lórí ìtúmọ̀ “àmì”.
Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fun yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.
Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fun yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn t’ó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ ó sì máa fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.
(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn t’ó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ mú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun t’ó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà t’ó yí wọn po.
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: "A gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un."
Ìgbàgbọ́ wọn kò ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.