surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Dájúdájú Àwa fún ọ ní ìṣẹ́gun pọ́nńbélé
nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀), àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām),
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Gọ̄fir; 40:55.
àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe t’ó lágbára.
Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
(Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.
Àti nítorí kí Ó lè fìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin, àwọn eléròkérò nípa Allāhu ní ti èrò aburú. Àpadàsí aburú ń bẹ fún wọn. Allāhu ti bínú sí wọn. Ó ti ṣẹ́bi lé wọn. Ó sì ti pèsè iná Jahnamọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ó sì burú ní ìkángun.
Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀
nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti (nítorí kí) ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún (Òjíṣẹ́ náà) àti nítorí kí ẹ lè pàtàkì rẹ̀, àti nítorí kí ẹ lè ṣàfọ̀mọ́ fún (Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́.
Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣàdéhùn fún ọ (pé àwọn kò níí fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun), dájúdájú Allāhu ni wọ́n ń ṣàdéhùn fún. Ọwọ́ Allāhu wà lókè ọwọ́ wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tú àdéhùn rẹ̀, ó tú u fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú àdéhùn t’ó ṣe fún Allāhu ṣẹ, (Allāhu) yóò fún un ní ẹ̀san ńlá.
____________________
Èyí fi rinlẹ̀ pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ní ọwọ́ ní ti pàápàá àti ní ti bí ó ṣe bá títóbi Rẹ̀ mu. Àmọ́ àgbọ́yé āyah yìí jọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn nínú àwọn Lárúbáwá oko yóò máa wí fún ọ pé: "Àwọn dúkìá wa àti àwọn ará ilé wa l’ó kó àìrójú bá wa. Nítorí náà, tọrọ àforíjìn fún wa." Wọ́n ń fi ahọ́n wọn wí ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Sọ pé: "Ta ni ó ní ìkápá kiní kan fun yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá gbèrò (láti fi) ìnira kàn yín tàbí tí Ó bá gbèrò àǹfààní kan fun yín? Rárá (kò sí). Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Rárá (kì í ṣe iṣẹ́ kan l’ó di yín lọ́wọ́ láti lọ jagun, àmọ́) ẹ ti lérò pé Òjíṣẹ́ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò níí padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn mọ́ láéláé. Wọ́n ṣe ìyẹn ni ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ẹ sì ro èrò aburú. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ìparun.
Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́, dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
“Ẹni tí Allāhu bá fẹ́” fún àforíjìn Rẹ̀, ó máa lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. “Ẹni tí Allāhu bá fẹ́ jẹ níyà” kò níí lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, kò sì níí ronú pìwàdà.
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: "Nígbà tí ẹ lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kaebar) nítorí kí ẹ lè rí n̄ǹkan kó, wọ́n já wa jù sílẹ̀ kí á má lè tẹ̀lé yín lọ." (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì) sọ pé: "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀." Wọn yó sì tún wí pé: "Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni." Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.
Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: "Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fun yín ní ẹ̀san t’ó dára. Tí ẹ̀yin bá sì gbúnrí padà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe gbúnrí ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn (tí wọn kò bá lọ sójú ogun). Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbúnrí, Ó máa jẹ ẹ́ ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn kò níí fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́
àti àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí wọn yóò rí kó. Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Àti pé Allāhu ṣàdéhùn àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí ẹ̀yin yóò rí kó fun yín. Ó sì tètè mú èyí wá fun yín. Ó tún kó àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ró fun yín nítorí kí ó lè jẹ́ àmì kan fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ yín rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Àti òmíràn tí ẹ ò lágbára lórí rẹ̀, (àmọ́ tí) Allāhu ti rọkiriká rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Tí ó bá jẹ́ pé àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ gbógun dìde si yín ni, wọn ìbá pẹ̀yìn dà (láti ságun fun yín). Lẹ́yìn náà, wọn kò níí rí aláàbò tàbí alárànṣe kan.
Ìṣe Allāhu, èyí t’ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀).
Òun sì ni Ẹni tí Ó kó wọn lọ́wọ́ ró fun yín. Ó sì kó ẹ̀yin náà lọ́wọ́ ró fún wọn nínú ìlú Mọkkah lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti fi yín borí wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
(Rántí) nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ kó ìgbónára sínú ọkàn wọn ní ìgbónára ti ìgbà àìmọ̀kan, Allāhu sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù (Rẹ̀) wà pẹ̀lú wọn; Wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí i jùlọ, àwọn ni wọ́n sì ni ín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Dájúdájú Allāhu ti sọ àlá Òjíṣẹ́ Rẹ̀ di òdodo pé - tí Allāhu bá fẹ́ - dájúdájú ẹ̀yin yóò wọ inú Mọ́sálásí Haram ní ẹni ìfàyàbalẹ̀. Ẹ máa fá irun orí yín; ẹ máa gé irun (orí yín mọ́lẹ̀), ẹ ò sì níí páyà. Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ó tún ṣe ìṣẹ́gun t’ó súnmọ́ (fun yín).
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí ẹ̀sìn (mìíràn), gbogbo rẹ̀ pátápátá. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.
Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, gẹ́gẹ́ bí kóró èso igi t’ó yọ ọ̀gọ́mọ̀ rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó nípọn (ó lágbára), ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn t’ó gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn.