surah.translation .
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

(Allāhu búra pẹ̀lú) ìràwọ̀ nígbà tí ó bá jábọ́.
Ẹni yín kò ṣìnà, kò sì sọnù.
Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú.
Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i.
Alágbára (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) l’ó kọ́ ọ ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān).
Ó ní àlàáfíà t’ó péye. Nítorí náà, ó dúró wámúwámú,
nígbà tí ó wà nínú òfurufú lókè pátápátá.
Lẹ́yìn náà, ó sún mọ́ (Ànábì). Ó sì sọ̀kalẹ̀ (tọ̀ ọ́ wá).
(Àlàfo ààrin àwọn méjèèjì) sì tó ìwọ̀n ọrún ọfà méjì, tàbí kí ó kéré (sí ìyẹn).
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
Allāhu sì fún ẹrúsìn Rẹ̀ ní ìmísí t’Ó fún un.
Ọkàn (Ànábì) kò parọ́ ohun t’ó rí.
Ṣé ẹ óò jà á níyàn nípa ohun t’ó rí ni?
Àti pé dájúdájú ó rí i nígbà kejì
____________________
Gbólóhùn “rọ’āhu” jẹyọ nínú āyah yìí. Ó tún jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah at-Tẹkwīr; 81:23. Ìtúmọ̀ rẹ̀ sì ni pé, “Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rí i.” Ta ni ó rí? Ṣé Allāhu ni tàbí mọlāika Jibrīl? Àní sẹ́, ta ni ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kẹta yìí “hu” t’ó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí? Kí á má gbàgbé pé āyah yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìn-àjò òru àti ìgun sánmọ̀ tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) ṣe ni.
Èsì: Àwọn igun kan nínú àwọn àáfà sọ pé, mọlāika Jibrīl ni Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rí. Igun kejì sì sọ pé, Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni ó rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igun yìí fi kún un pé ọkàn l’ó fi rí Allāhu, kì í ṣe ojú. Ṣebí bí ẹ̀dá ṣe ní ojú ìta, ni ó ní ojú inú. Àmọ́ èyí tí ó gbéwọ̀n jùlọ lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn ’Islām ni pé, orúkọ mọlāika Jibrīl ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ni “hu” yẹn ń rọ́pò. Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni hadīth tí ìyá wa ‘Ā’iṣah (rọdiyallāhu 'anhā) gbàwá lórí ọ̀rọ̀ náà pé, “Èmi ni àkọ́kọ́ nínú ìjọ yìí tí ó béèrè nípa ìyẹn lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Ó sì sọ pé. “Jibrīl ni mo rí.” (Muslim). Bákan náà, nínú ẹ̀gbàwá Abū Tharr (rọdiyallāhu 'anhu), ó sọ pé, mo bi Òjíṣẹ́ Allāhu ní ìbéèrè pé, “Ṣé o fojú rí Olúwa rẹ bí?” Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) sì sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ kan (dí mi lọ́wọ́), báwo ni mo ṣe máa rí I nígbà náà!” (Muslim) Irú èyí náà l’ó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Mūsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:143.
Tọ́ọ̀, ó ṣeé ṣe kí á rí ọ̀rọ̀ mìíràn kan láti ọ̀dọ̀ àwọn Sọhābah (r.ahm.), bíi ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās (rọdiyallāhu 'anhu) wá pé, “Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) fi ọkàn rẹ̀ rí Allāhu ni.” Ìyẹn ni pé, ó fojú inú rí I, kì í ṣe ojú ìta. Kíyè sí i, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó lágbára tó èyí tí ó tọ̀dọ̀ Ànábì fúnra rẹ̀ wá tààrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀gbàwá ‘Ā’iṣah àti ẹ̀gbàwá Abū Tharr sì ni ẹ̀gbàwá t’ó ti ọ̀dọ̀ Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) wá lórí ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe fọkàn sí ibò míìràn. Àti pé, sūrah al-’Ani‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrā; 42:51 ti fi rinlẹ̀ pé, ojú kan kò lè fojú rinjú pẹ̀lú Allāhu, yálà fún gbígba iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu tàbí fún n̄ǹkan mìíràn. Àmọ́ sá, rírí Allāhu sójú máa wáyé fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nìkan lọ́jọ́ Àjíǹde. Èyí sì wà ní ìbámu sí sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:22-23.
níbi igi sidirah al-Muntahā,
nítòsí rẹ̀ ni Ọgbà Ibùgbé (gbére) wà.
(Rántí) nígbà tí ohun t’ó bo igi Sidirah bò ó mọ́lẹ̀.
Ojú (Ànábì) kò yẹ̀, kò sì tayọ ẹnu-àlà.
Dájúdájú ó rí nínú àwọn àmì Olúwa rẹ̀, t’ó tóbi jùlọ.
Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā,
àti Mọnāh, òrìṣà kẹta mìíràn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hajj 22:52.
Ṣé ọmọkùnrin ni tiyín, ọmọbìnrin sì ni tiRẹ̀?
Ìpín àbòsí nìyẹn nígbà náà.
(Àwọn orúkọ òrìṣà wọ̀nyẹn) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín fi sọ (àwọn òrìṣà yín fúnra yín). Allāhu kò sì sọ ẹ̀rí ọ̀rọ̀ kan kalẹ̀ nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ àti ohun tí ẹ̀mí (wọn) ń fẹ́. Ìmọ̀nà kúkú ti dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
Tàbí ti ènìyàn ni n̄ǹkan t’ó bá ń fẹ́!
Ti Allāhu sì ni ọ̀run àti ayé.
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn mọlāika t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀, tí ìṣìpẹ̀ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan àyàfi lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu bá yọ̀ǹda fún ẹni tí Ó bá fẹ́, tí Ó sì yọ́nú sí.
Dájúdájú àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn ni wọ́n ń fún àwọn mọlāika ní orúkọ obìnrin.
Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀. Wọn kò sì tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àròsọ kò sì níí rọrọ̀ kiní kan lára òdodo.
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ ẹni t’ó kẹ̀yìn sí ìrántí Wa, tí kò sì gbèrò kiní kan àfi ìṣẹ̀mí ayé.
Ìyẹn ni òdíwọ̀n (àti òpin) ìmọ̀ wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀. Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó mọ̀nà.
Ti Allāhu ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ aburú ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti nítorí kí Ó lè san àwọn t’ó ṣe iṣẹ́ rere ni ẹ̀san rere.
Àwọn t’ó ń jìnnà sí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti ìwà ìbàjẹ́ àyàfi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, dájúdájú Olúwa rẹ gbòòrò ní àforíjìn. Ó nímọ̀ jùlọ nípa yín nígbà tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú ilẹ̀ àti nígbà tí ẹ wà ní ọlẹ̀ nínú àwọn ikùn ìyá yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe fọra yín mọ́. Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀).
Sọ fún mi nípa ẹni t’ó gbúnrí (kúrò níbi òdodo),
tí ó fi díẹ̀ tọrẹ, tí ó sì di ìyókù mọ́wọ́!
Ṣé ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ, tí ó sì ń rí i (pé ẹlòmíìràn l’ó ma bá òun jìyà lọ́run)?
Tàbí wọn kò fún un ní ìró ohun t’ó wà nínú tírà (Ànábì) Mūsā ni,
àti (tírà Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ẹni t’ó mú (òfin Allāhu) ṣẹ,
pé dájúdájú ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹrù-ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah an-Nahl; 16:25.
Àti pé kò sí kiní kan fún ènìyàn àfi ohun t’ó ṣe níṣẹ́.
Àti pé dájúdájú iṣẹ́ rẹ̀, láìpẹ́ wọ́n máa fi hàn án.
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san án ní ẹ̀san rẹ̀, ní ẹ̀san t’ó kún jùlọ.
Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin (ìrìn-àjò ẹ̀dá).
Dájúdájú Òun l’Ó ń pa (ẹ̀dá) ní ẹ̀rín. Ó sì ń pa (ẹ̀dá) ní ẹkún.
Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ (ẹ̀dá) di òkú. Ó sì ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè.
Dájúdájú Òun l’Ó dá ẹ̀dá ní oríṣi méjì, ọkùnrin àti obìnrin,
____________________
Ẹ̀dá ènìyàn ni èròǹgbà nínú āyah yìí, kì í ṣe ẹ̀dá mìíràn. Āyah 46 l’ó fi èyí rinlẹ̀.
láti ara àtọ̀ nígbà tí wọ́n bá dà á sínú àpòlùkẹ́.
Dájúdájú Òun l’Ó máa ṣe ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn fún àjíǹde,
Dájúdájú Òun l’Ó ń ṣe púpọ̀, Ó sì ń ṣe kékeré (oore fún ẹ̀dá).
Dájúdájú Òun sì ni Olúwa ìràwọ̀ Ṣi‘rọ̄ (tí wọ́n sọ di òrìṣà).
Dájúdájú Òun l’Ó pa ìran ‘Ād rẹ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́;
àti ìran Thamūd, kò sì ṣẹ́ wọn kù;
àti ìjọ Nūh t’ó ṣíwájú (wọn), dájúdájú wọ́n jẹ́ alábòsí jùlọ, wọ́n sì tayọ ẹnu-àlà jùlọ;
àti ìlú tí wọ́n dàwó (ìlú Ànábì Lūt) t’Ó yẹ̀ lulẹ̀ (láti òkè).
Ohun t’ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Nítorí náà, èwo nínú ìdẹ̀ra Olúwa rẹ ni ìwọ (ènìyàn) ń jà níyàn?
Èyí ni ìkìlọ̀ kan nínú àwọn ìkìlọ̀ àkọ́kọ́.
Ohun t’ó súnmọ́ súnmọ́.
____________________
“Ohun t’ó súnmọ́” jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde.
Lẹ́yìn Allāhu, kò sí ẹni t’ó lè ṣàfi hàn (Àkókò náà).
Ṣé ọ̀rọ̀ yìí l’ó ń ṣe yín ní kàyéfì?
Ẹ̀ ń rẹ́rìn-ín, ẹ ò sì sunkún!
Afọ́nú-fọ́ra ni yín.
Nítorí náà, ẹ forí kanlẹ̀ fún Allāhu, kí ẹ jọ́sìn (fún Un).