Ìtumọ̀ Sura الجمعة ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية
Verse 1
Ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu, Ọba ẹ̀dá, Ẹni-Mímọ́ jùlọ, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 2
Òun ni Ẹni tí Ó gbé dìde láààrin àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (aláìnítírà) Òjíṣẹ́ kan lára wọn. Ó ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
Verse 3
(Iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ tún wà fún) àwọn mìíràn tí wọ́n máa wà nínú àwọn (ọmọlẹ́yìn rẹ̀), àmọ́ tí wọn kò tí ì rìn kàn wọ́n. (Allāhu) Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Verse 4
Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore-àjùlọ ńlá.
Verse 5
Àpèjúwe ìjọ tí A fún ní Taorāh, lẹ́yìn náà tí wọn kò tẹ̀lé e, ó dà bí àpèjúwe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ru ẹrù àwọn tírà. Aburú ni àpèjúwe àwọn t’ó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Verse 6
Sọ pé: "Ẹ̀yin yẹhudi, tí ẹ bá lérò pé dájúdájú ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ Allāhu dípò àwọn ènìyàn (yòókù), ẹ tọrọ ikú nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo."
Verse 7
Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn ti tì ṣíwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Verse 8
Sọ pé: "Dájúdájú ikú tí ẹ̀ ń sá fún, dájúdájú ó máa pàdé yín. Lẹ́yìn náà, wọn yóò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Ó sì máa fun yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́."
Verse 9
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.
Verse 10
Nígbà tí wọ́n bá sì parí ìrun, ẹ túká sí orí ilẹ̀, kí ẹ sì máa wa nínú oore Allāhu. Ẹ rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.
Verse 11
Nígbà tí wọ́n bá rí ọjà kan tàbí ìranù kan, wọn yóò dà lọ síbẹ̀. Wọn yó sì fi ọ́ sílẹ̀ lórí ìdúró. Sọ pé: "N̄ǹkan tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore ju ìranù àti ọjà lọ. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.
تقدم القراءة