Ìtumọ̀ Sura الحاقة ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية
Verse 1
ﮯ
ﮰ
Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo
Verse 2
ﮱﯓ
ﯔ
Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo.
Verse 3
ﯕﯖﯗﯘ
ﯙ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo?
Verse 4
ﯚﯛﯜﯝ
ﯞ
Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Ìpáyà nírọ́.
____________________
Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo àti Ìpáyà.
____________________
Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo àti Ìpáyà.
Verse 5
ﯟﯠﯡﯢ
ﯣ
Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́.
Verse 6
ﯤﯥﯦﯧﯨﯩ
ﯪ
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle t’ó tayọ ẹnu-àlà pa wọ́n rẹ́.
Verse 7
Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù t’ó ti luhò nínú ni wọ́n.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Fussilat; 41:16.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah Fussilat; 41:16.
Verse 8
ﯼﯽﯾﯿﰀ
ﰁ
Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn t’ó ṣẹ́ kù bí?
Verse 9
ﭑﭒﭓﭔﭕﭖ
ﭗ
Fir‘aon àti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
Verse 10
ﭘﭙﭚﭛﭜﭝ
ﭞ
Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú àlékún.
Verse 11
Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-àlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
Verse 12
ﭧﭨﭩﭪﭫﭬ
ﭭ
Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fun yín àti nítorí kí etí t’ó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
Verse 13
ﭮﭯﭰﭱﭲﭳ
ﭴ
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
Verse 14
ﭵﭶﭷﭸﭹﭺ
ﭻ
tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
Verse 15
ﭼﭽﭾ
ﭿ
ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
Verse 16
ﮀﮁﮂﮃﮄ
ﮅ
Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
Verse 17
Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
Verse 18
ﮑﮒﮓﮔﮕﮖ
ﮗ
Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan t’ó máa pamọ́ (fún Wa).
Verse 19
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: "Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi.
Verse 20
ﮢﮣﮤﮥﮦ
ﮧ
Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé."
Verse 21
ﮨﮩﮪﮫ
ﮬ
Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí t’ó máa yọ́nú sí
Verse 22
ﮭﮮﮯ
ﮰ
nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
Verse 23
ﮱﯓ
ﯔ
Àwọn èso rẹ̀ (sì) wà ní àrọ́wọ́tó.
Verse 24
Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
Verse 25
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: "Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí ń sọ pé ọwọ́ òsì ni àwọn aláìgbàgbọ́ máa fi gba ìwé iṣẹ́ wọn, àmọ́ sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:10 ń sọ pé láti ẹ̀yìn ni wọ́n máa ti gbà á.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn!”
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé rẹ̀ nìyí, méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé, ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀.

Verse 26
ﯩﯪﯫﯬ
ﯭ
Àti pé èmi kò mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
Verse 27
ﯮﯯﯰ
ﯱ
Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
Verse 28
ﯲﯳﯴﯵﯶ
ﯷ
Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
Verse 29
ﯸﯹﯺ
ﯻ
Agbára mi sì ti parun."
Verse 30
ﯼﯽ
ﯾ
Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
Verse 31
ﯿﰀﰁ
ﰂ
Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
Verse 32
Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u ni kí ẹ kì í sí.
____________________
Gígùn “Thar‘u” kan ni gígùn láti ìlú Mọkkah sí ibi tí ó jìnnà jùlọ sí ìlú Mọkkah.
____________________
Gígùn “Thar‘u” kan ni gígùn láti ìlú Mọkkah sí ibi tí ó jìnnà jùlọ sí ìlú Mọkkah.
Verse 33
ﰋﰌﰍﰎﰏﰐ
ﰑ
Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
Verse 34
ﰒﰓﰔﰕﰖ
ﰗ
Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
Verse 35
ﰘﰙﰚﰛﰜ
ﰝ
Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
Verse 36
ﭑﭒﭓﭔﭕ
ﭖ
Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọyúnwẹ̀jẹ̀.
Verse 37
ﭗﭘﭙﭚ
ﭛ
Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Verse 38
ﭜﭝﭞﭟ
ﭠ
Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ ń fojú rí
Verse 39
ﭡﭢﭣ
ﭤ
àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
Verse 40
ﭥﭦﭧﭨ
ﭩ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.
____________________
“Ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́” ni ìtúmọ̀ “ƙọolu rọsūl, àmọ́ al-Ƙur’ān kì í ṣe ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ bí kò ṣe “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. Àgbékalẹ̀ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ṣíṣe àfitì ọ̀rọ̀ sí ọ̀dọ̀ alágbàsọ. Bákan náà, āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Tẹkwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam), Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Tẹkwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀.

Verse 41
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
Verse 42
Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
Verse 43
ﭻﭼﭽﭾ
ﭿ
Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Verse 44
ﮀﮁﮂﮃﮄ
ﮅ
Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
Verse 45
ﮆﮇﮈ
ﮉ
Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
Verse 46
ﮊﮋﮌﮍ
ﮎ
Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
Verse 47
ﮏﮐﮑﮒﮓﮔ
ﮕ
Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
Verse 48
ﮖﮗﮘ
ﮙ
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Verse 49
ﮚﮛﮜﮝﮞ
ﮟ
Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn t’ó ń pe al-Ƙur’ān nírọ́ wà nínú yín.
Verse 50
ﮠﮡﮢﮣ
ﮤ
Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Verse 51
ﮥﮦﮧ
ﮨ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo t’ó dájú.
Verse 52
ﮩﮪﮫﮬ
ﮭ
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.
تقدم القراءة