Ìtumọ̀ Sura نوح ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية
Verse 1
Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: "Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn."
Verse 2
ﮇﮈﮉﮊﮋﮌ
ﮍ
Ó sọ pé: "Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fun yín
Verse 3
ﮎﮏﮐﮑﮒ
ﮓ
pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Verse 4
(Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fun yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀."
Verse 5
Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán.
Verse 6
ﮱﯓﯔﯕﯖ
ﯗ
Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo).
Verse 7
Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an.
Verse 8
ﯧﯨﯩﯪ
ﯫ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè.
Verse 9
Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmi kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́.
Verse 10
ﯴﯵﯶﯷﯸﯹ
ﯺ
Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn.
Verse 11
ﭑﭒﭓﭔ
ﭕ
Ó máa rọ̀jò fun yín ní òjò púpọ̀,
Verse 12
Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fun yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fun yín.
Verse 13
ﭠﭡﭢﭣﭤﭥ
ﭦ
Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu?
Verse 14
ﭧﭨﭩ
ﭪ
Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).
____________________
Ìyẹn ni pé, láti ìrísí àtọ̀ sí ìrísí ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà sí bááṣí ẹran.
____________________
Ìyẹn ni pé, láti ìrísí àtọ̀ sí ìrísí ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà sí bááṣí ẹran.
Verse 15
Ṣé ẹ ò rí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni?
Verse 16
Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà.
Verse 17
ﭼﭽﭾﭿﮀ
ﮁ
Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀.
Verse 18
ﮂﮃﮄﮅﮆ
ﮇ
Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà.
Verse 19
ﮈﮉﮊﮋﮌ
ﮍ
Allāhu ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́
Verse 20
ﮎﮏﮐﮑ
ﮒ
nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀."
Verse 21
(Ànábì) Nūh sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò.
Verse 22
ﮡﮢﮣ
ﮤ
Wọ́n sì déte ní ète t’ó tóbi."
Verse 23
Wọ́n sì wí pé: "Ẹ má ṣe fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ má ṣe fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀."
Verse 24
Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà.
Verse 25
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe fún wọn lẹ́yìn Allāhu.
Verse 26
(Ànábì) Nūh tún sọ pé: "Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀.
Verse 27
Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́.
Verse 28
Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni t’ó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun."
تقدم القراءة