سورة الليل

الترجمة اليورباوية

Ìtumọ̀ Sura الليل ní اليورباوية láti الترجمة اليورباوية

الترجمة اليورباوية

Verse 1
(Allāhu) búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú.
Verse 2
Ó tún búra pẹ̀lú ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n.
Verse 3
Ó tún búra pẹ̀lú Ẹni tí Ó dá akọ àti abo.
____________________
Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ni Ẹni tí Ó dá akọ àti abo. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
Verse 4
Dájúdájú iṣẹ́ yín, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni.
Verse 5
Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
Verse 6
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní òdodo,
Verse 7
A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
Verse 8
Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni t’ó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
Verse 9
(tí) ó tún pe ẹ̀san rere ní irọ́,
Verse 10
A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá já bọ́ (sínú Iná).
Verse 12
Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
Verse 14
Nítorí náà, Mo ti fi Iná eléjò fòfò kìlọ̀ fun yín.
Verse 15
Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
Verse 16
ẹni tí ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
Verse 17
Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
Verse 18
ẹni t’ó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
Verse 21
Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rẹ̀).
تقدم القراءة