ﰍ
surah.translation
.
من تأليف:
أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني
.
ﰡ
Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.
Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.
Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.
Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.
Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-àlà
nítorí pé ó ríra rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ń kọ̀
fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!
Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!
Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo nírọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?
Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)
Bẹ́ẹ̀ ni (Allāhu ń rí i.) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí i lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
ﭧﭨ
ﰐ
Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.
ﭪﭫ
ﰑ
Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.
Rárá o, má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o súnmọ́ (Allāhu).